Fún olóòtítọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní olóòtítọ́,
sí aláìlẹ́bi, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìlẹ́bi,
Sí ọlọ́kàn mímọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní ọlọ́kàn mímọ́,
ṣùgbọ́n sí ọlọ́kàn-wíwọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní òǹrorò.
O pa onírẹ̀lẹ̀ mọ́,
ṣùgbọ́n ó rẹ àwọn ti ń gbéraga sílẹ̀.
Ìwọ, OLúWA, jẹ́ kí fìtílà mi
kí ó máa tàn; Ọlọ́run mi, yí òkùnkùn mi padà sí ìmọ́lẹ̀.
Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, èmi sáré tọ ogun lọ;
pẹ̀lú Ọlọ́run mi mo lè fo odi kan.
Bí ó ṣe ti Ọlọ́run mi, ọ̀nà rẹ̀ pé,
a ti rídìí ọ̀rọ̀ OLúWA
òun ni àpáta ààbò fún gbogbo àwọn tí ó fi ṣe ààbò.
Nítorí ta ni ṣe Ọlọ́run bí kò ṣe OLúWA?
Ta ní àpáta bí kò ṣe OLúWA wa?
Ọlọ́run ni ẹni tí ó fi agbára dì mí ní àmùrè
ó sì mú ọ̀nà mi pé.
Ó ṣe ẹsẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bi ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín;
ó jẹ́ ki n lè dúró lórí ibi gíga.
Ó kọ́ ọwọ́ mi ni ogun jíjà;
apá mi lè tẹ ọrùn idẹ
Ìwọ fi asà ìṣẹ́gun rẹ̀ fún mi,
ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé mí dúró;
àti ìwà pẹ̀lẹ́ rẹ̀ sọ mí di ńlá.
Ìwọ sọ ìrìn ẹsẹ̀ mi di ńlá ní ìsàlẹ̀ mi,
kí kókó-ẹsẹ̀ mi má ṣe yẹ̀.
Èmi lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì bá wọn
èmi kò sì padà lẹ́yìn wọn títí a fi run wọ́n.
Èmi sá wọn ní ọgbẹ́ tí wọn ko fi le è dìde;
Wọ́n ṣubú ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi.
Nítorí ìwọ fi agbára dì mí ní àmùrè fún ogun náà;
ìwọ ti mú àwọn tí ó dìde si mí tẹríba ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi
Ìwọ yí ẹ̀yìn àwọn ọ̀tá mí padà sí mi
èmi sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run.
Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbà wọ́n,
àní sí OLúWA, ṣùgbọ́n kò dá wọn lóhùn.
Mo lù wọ́n gẹ́gẹ́ bí eruku níwájú afẹ́fẹ́;
mo dà wọ́n síta gẹ́gẹ́ bí ẹrọ̀fọ̀.
Ìwọ ti gbà mí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ènìyàn;
Ìwọ ti fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè.
Àwọn ènìyàn ti èmi kò mọ, yóò sì máa sìn mí,
ni wéré ti wọ́n gbọ́ ohùn mi, wọ́n pa àṣẹ mi mọ́;
àwọn ọmọ àjèjì yóò tẹríba fún mi.
Àyà yóò pá àlejò;
wọn yóò sì fi ìbẹ̀rù jáde láti ibi kọ́lọ́fín wọn.
OLúWA wà láààyè! Olùbùkún ni àpáta mi!
Gbígbéga ní Ọlọ́run Olùgbàlà mi.
Òun ni Ọlọ́run tí ó ń gbẹ̀san mi,
tí ó sì ń ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní abẹ́ mi,
tí ó pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mí.
Ìwọ gbé mi ga ju àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí mi lọ;
lọ́wọ́ àwọn ènìyàn alágbára ni ìwọ ti gbà mí.
Títí láéláé, èmi yóò máa yìn ọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ OLúWA;
Èmi yóò sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.
Ó fún ọba rẹ̀ ni ìṣẹ́gun ńlá;
ó fi ìkáàánú àìṣẹ̀tàn fún ẹni ààmì òróró rẹ̀,
fún Dafidi àti ìran rẹ̀ títí láé.