O. Daf 17:1-9
O. Daf 17:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
GBỌ́ otiọ́, Oluwa, fiyesi igbe mi, fi eti si adura mi, ti kò ti ète ẹ̀tan jade. Jẹ ki idajọ mi ki o ma ti iwaju rẹ jade wá: jẹ ki oju rẹ ki o ma wò ohun ti o ṣe dẽde. Iwọ ti dan aiya mi wò; iwọ ti bẹ̀ ẹ wò li oru; iwọ ti wadi mi, iwọ kò ri nkan; emi ti pinnu rẹ̀ pe, ẹnu mi kì yio ṣẹ̀. Niti iṣẹ enia, nipa ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ emi ti pa ara mi mọ́ kuro ni ipa alaparun. Fi ìrin mi le ilẹ ni ipa rẹ, ki atẹlẹ ẹsẹ mi ki o máṣe yẹ̀. Emi ti nkepè ọ, nitori pe iwọ o gbohùn mi, Ọlọrun: dẹ eti rẹ si mi, ki o si gbọ́ ọ̀rọ mi: Fi iṣeun ifẹ iyanu rẹ hàn, iwọ ti o fi ọwọ ọtún rẹ gbà awọn ti o gbẹkẹle ọ là, lọwọ awọn ti o dide si wọn. Pa mi mọ́ bi ọmọ-oju, pa mi mọ́ labẹ ojiji iyẹ-apá rẹ, Lọwọ awọn enia buburu ti nfõró mi, lọwọ awọn ọta-iyọta mi, ti o yi mi kakiri.
O. Daf 17:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Gbọ́ tèmi OLUWA, àre ni ẹjọ́ mi; fi ìtara gbọ́ igbe mi. Fetí sí adura mi nítorí kò sí ẹ̀tàn ní ẹnu mi. Jẹ́ kí ìdáláre mi ti ọ̀dọ̀ rẹ wá; kí o sì rí i pé ẹjọ́ mi tọ́. Yẹ ọkàn mi wò; bẹ̀ mí wò lóru. Dán mi wò, o kò ní rí ohun burúkú kan; n kò ní fi ẹnu mi dẹ́ṣẹ̀. Nítorí ohun tí o wí nípa èrè iṣẹ́ ọwọ́ eniyan, mo ti yàgò fún àwọn oníwà ipá. Mò ń tọ ọ̀nà rẹ tààrà; ẹsẹ̀ mi kò sì yọ̀. Mo ké pè ọ́, dájúdájú ìwọ Ọlọrun yóo dá mi lóhùn, dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn lọ́nà ìyanu, fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ó gbógun tì wọ́n. Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú, dáàbò bò mí lábẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ; lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú tí ó gbé ìjà kò mí, àní lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká.
O. Daf 17:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbọ́, OLúWA, ẹ̀bẹ̀ òtítọ́ mi; fi etí sí igbe mi. Tẹ́tí sí àdúrà mi tí kò ti ètè ẹ̀tàn jáde. Kí ìdáláre mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ; kí ojú rẹ kí ó rí ohun tí ó tọ́. Ìwọ ti dán àyà mi wò, ìwọ sì bẹ̀ mí wò ní òru, o sì ti wádìí mi, ìwọ kì yóò rí ohunkóhun èmi ti pinnu pé, ẹnu mi kì yóò ṣẹ̀. Bí ó ṣe ti iṣẹ́ ènìyàn nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ, èmi ti pa ara mi mọ́ kúrò ní ọ̀nà àwọn ìkà. Ìrìn mí ti jẹ mọ́ ọ̀nà rẹ; ẹsẹ̀ mi kì yóò yọ̀. Èmi ké pè ọ́, Ọlọ́run, nítorí tí ìwọ yóò dá mi lóhùn dẹ etí rẹ sí mi kí o sì gbọ́ àdúrà mi. Fi ìṣeun ìyanu ìfẹ́ ńlá rẹ hàn ìwọ tí ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn. Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú rẹ; fi mí pamọ́ sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ, lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú tí ń fóròó mi, kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká.