O. Daf 16:5-9
O. Daf 16:5-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa ni ipin ini mi, ati ti ago mi: iwọ li o mu ìla mi duro. Okùn tita bọ́ sọdọ mi ni ibi daradara; lõtọ, emi ni ogún rere. Emi o fi ibukún fun Oluwa, ẹniti o ti nfun mi ni ìmọ; ọkàn mi pẹlu nkọ́ mi ni wakati oru. Emi ti gbé Oluwa kà iwaju mi nigbagbogbo; nitori o wà li ọwọ ọtún mi, a kì yio ṣi mi ni ipò. Nitorina ni inu mi ṣe dùn, ti ogo mi si nyọ̀; ara mi pẹlu yio simi ni ireti.
O. Daf 16:5-9 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, ìwọ ni ìpín mi, ìwọ ni mo yàn; ìwọ ni ò ń jẹ́ kí ọ̀ràn mi fìdí múlẹ̀. Ìpín tí ó bọ́ sí mi lọ́wọ́ dára pupọ; ogún rere ni ogún ti mo jẹ. Èmi óo máa yin OLUWA, ẹni tí ó ń fún mi ní òye; ọkàn mi ó sì máa tọ́ mi sọ́nà ní òròòru. Mò ń wo OLUWA ní iwájú mi nígbà gbogbo, nítorí pé Ọlọrun dúró tì mí, ẹsẹ̀ mi kò ní yẹ̀. Nítorí náà ni ọkàn mi ṣe ń yọ̀, tí inú mi dùn; ara sì rọ̀ mí.
O. Daf 16:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA, ni ìpín ìní mi tí mo yàn àti ago mi, ó ti pa ohun tí í ṣe tèmi mọ́. Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára; nítòótọ́ mo ti ní ogún rere. Èmi yóò yin OLúWA, ẹni tí ó gbà mí ní ìyànjú; ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀. Mo ti gbé Ọlọ́run síwájú mi ní ìgbà gbogbo. Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí. Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀; ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò