O. Daf 16:1-8
O. Daf 16:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌLỌRUN, pa mi mọ́: nitori iwọ ni mo gbẹkẹ mi le. Ọkàn mi, iwọ ti wi fun Oluwa pe, Iwọ li Oluwa mi: emi kò ni ire kan lẹhin rẹ. Si awọn enia mimọ́ ti o wà li aiye, ani si awọn ọlọla, lara ẹniti didùn inu mi gbogbo gbe wà. Ibinujẹ awọn ti nsare tọ̀ ọlọrun miran lẹhin yio pọ̀: ẹbọ ohun mimu ẹ̀jẹ wọn li emi kì yio ta silẹ, bẹ̃li emi kì yio da orukọ wọn li ẹnu mi. Oluwa ni ipin ini mi, ati ti ago mi: iwọ li o mu ìla mi duro. Okùn tita bọ́ sọdọ mi ni ibi daradara; lõtọ, emi ni ogún rere. Emi o fi ibukún fun Oluwa, ẹniti o ti nfun mi ni ìmọ; ọkàn mi pẹlu nkọ́ mi ni wakati oru. Emi ti gbé Oluwa kà iwaju mi nigbagbogbo; nitori o wà li ọwọ ọtún mi, a kì yio ṣi mi ni ipò.
O. Daf 16:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Pa mí mọ́ Ọlọrun, nítorí ìwọ ni mo sá di. Mo wí fún ọ, OLUWA, pé, “Ìwọ ni Oluwa mi; ìwọ nìkan ni orísun ire mi.” Nípa àwọn eniyan mímọ́ tí ó wà nílẹ̀ yìí, wọ́n jẹ́ ọlọ́lá tí àwọn eniyan fẹ́ràn. “Ìbànújẹ́ àwọn tí ń sá tọ ọlọrun mìíràn lẹ́yìn yóo pọ̀: Èmi kò ní bá wọn ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ fún ìrúbọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò ní gbọ́ orúkọ wọn lẹ́nu mi.” OLUWA, ìwọ ni ìpín mi, ìwọ ni mo yàn; ìwọ ni ò ń jẹ́ kí ọ̀ràn mi fìdí múlẹ̀. Ìpín tí ó bọ́ sí mi lọ́wọ́ dára pupọ; ogún rere ni ogún ti mo jẹ. Èmi óo máa yin OLUWA, ẹni tí ó ń fún mi ní òye; ọkàn mi ó sì máa tọ́ mi sọ́nà ní òròòru. Mò ń wo OLUWA ní iwájú mi nígbà gbogbo, nítorí pé Ọlọrun dúró tì mí, ẹsẹ̀ mi kò ní yẹ̀.
O. Daf 16:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Pa mí mọ́, Ọlọ́run, nítorí nínú rẹ ni ààbò mi wà. Mo sọ fún OLúWA, “ìwọ ni Olúwa mi, lẹ́yìn rẹ èmi kò ní ìre kan.” Sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ayé, àwọn ni ológo nínú èyí tí ayọ̀ mí wà. Ìṣòro àwọn wọ̀n-ọn-nì yóò pọ̀ sí i, àní àwọn tí ń tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn. Ẹbọ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi kì yóò ta sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá orúkọ wọn lẹ́nu mi. OLúWA, ni ìpín ìní mi tí mo yàn àti ago mi, ó ti pa ohun tí í ṣe tèmi mọ́. Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára; nítòótọ́ mo ti ní ogún rere. Èmi yóò yin OLúWA, ẹni tí ó gbà mí ní ìyànjú; ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀. Mo ti gbé Ọlọ́run síwájú mi ní ìgbà gbogbo. Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.