O. Daf 145:17-19
O. Daf 145:17-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Olododo li Oluwa li ọ̀na rẹ̀ gbogbo, ati alãnu ni iṣẹ rẹ̀ gbogbo. Oluwa wà leti ọdọ gbogbo awọn ti nkepè e, leti ọdọ gbogbo ẹniti nkepè e li otitọ. Yio mu ifẹ awọn ti mbẹ̀ru rẹ̀ ṣẹ: yio gbọ́ igbe wọn pẹlu, yio si gbà wọn.
O. Daf 145:17-19 Yoruba Bible (YCE)
Olódodo ni OLUWA ninu gbogbo ọ̀nà rẹ̀, aláàánú sì ni ninu gbogbo ìṣe rẹ̀. OLUWA súnmọ́ gbogbo àwọn tí ń pè é, àní, àwọn tí ń pè é tọkàntọkàn. Ó ń tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ lọ́rùn; ó ń gbọ́ igbe wọn, ó sì ń gbà wọ́n.