O. Daf 145:1-7
O. Daf 145:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
EMI o gbé ọ ga, Ọlọrun mi, ọba mi; emi o si ma fi ibukún fun orukọ rẹ lai ati lailai. Li ojojumọ li emi o ma fi ibukún fun ọ; emi o si ma yìn orukọ rẹ lai ati lailai. Titobi li Oluwa, o si ni iyìn pupọ̀-pupọ̀; awamaridi si ni titobi rẹ̀. Iran kan yio ma yìn iṣẹ rẹ de ekeji, yio si ma sọ̀rọ iṣẹ agbara rẹ. Emi o sọ̀rọ iyìn ọla-nla rẹ ti o logo, ati ti iṣẹ iyanu rẹ. Enia o si ma sọ̀rọ agbara iṣẹ rẹ ti o li ẹ̀ru; emi o si ma ròhin titobi rẹ. Nwọn o ma sọ̀rọ iranti ore rẹ pupọ̀-pupọ̀, nwọn o si ma kọrin ododo rẹ.
O. Daf 145:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Èmi óo gbé ọ ga, Ọlọrun mi, Ọba mi, n óo máa yin orúkọ rẹ lae ati laelae. Lojoojumọ ni n óo máa yìn ọ́, tí n óo máa yin orúkọ rẹ lae ati laelae. OLUWA tóbi, ìyìn sì yẹ ẹ́ lọpọlọpọ; àwámárìídìí ni títóbi rẹ̀. Láti ìran dé ìran ni a óo máa yin iṣẹ́ rẹ, tí a óo sì máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ agbára ńlá rẹ. Èmi óo máa ṣe àṣàrò lórí ẹwà ògo ọlá ńlá rẹ, ati iṣẹ́ ìyanu rẹ. Eniyan óo máa kéde iṣẹ́ agbára rẹ tí ó yani lẹ́nu, èmi óo sì máa polongo títóbi rẹ. Wọn óo máa pòkìkí bí oore rẹ ti pọ̀ tó, wọn óo sì máa kọrin sókè nípa òdodo rẹ.
O. Daf 145:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò gbé ọ ga, Ọlọ́run ọba mi; Èmi yóò yin orúkọ rẹ̀ láé àti láéláé Ní ojoojúmọ́ èmi yóò yìn ọ́ èmi yóò sì pòkìkí orúkọ rẹ láé àti láéláé. Títóbi ni OLúWA. Òun sì ni ó yẹ láti fi ìyìn fún púpọ̀púpọ̀: kò sí ẹni tí ó lè wọn títóbi rẹ̀. Ìran kan yóò máa yin iṣẹ́ rẹ dé ìran mìíràn; wọn yóò máa sọ iṣẹ́ agbára rẹ Wọn yóò máa sọ ìyìn ọláńlá rẹ tí ó lógo, èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú iṣẹ́ ìyanu rẹ. Wọn yóò sọ iṣẹ́ agbára rẹ tí ó ní ẹ̀rù èmi yóò kéde iṣẹ́ ńlá rẹ̀. Wọn yóò ṣe ìrántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà rere rẹ àti orin ayọ̀ òdodo rẹ.