O. Daf 145:1-21

O. Daf 145:1-21 Bibeli Mimọ (YBCV)

EMI o gbé ọ ga, Ọlọrun mi, ọba mi; emi o si ma fi ibukún fun orukọ rẹ lai ati lailai. Li ojojumọ li emi o ma fi ibukún fun ọ; emi o si ma yìn orukọ rẹ lai ati lailai. Titobi li Oluwa, o si ni iyìn pupọ̀-pupọ̀; awamaridi si ni titobi rẹ̀. Iran kan yio ma yìn iṣẹ rẹ de ekeji, yio si ma sọ̀rọ iṣẹ agbara rẹ. Emi o sọ̀rọ iyìn ọla-nla rẹ ti o logo, ati ti iṣẹ iyanu rẹ. Enia o si ma sọ̀rọ agbara iṣẹ rẹ ti o li ẹ̀ru; emi o si ma ròhin titobi rẹ. Nwọn o ma sọ̀rọ iranti ore rẹ pupọ̀-pupọ̀, nwọn o si ma kọrin ododo rẹ. Olore-ọfẹ li Oluwa, o kún fun ãnu; o lọra lati binu, o si li ãnu pupọ̀. Oluwa ṣeun fun ẹni gbogbo; iyọ́nu rẹ̀ si mbẹ lori iṣẹ rẹ̀ gbogbo. Oluwa, gbogbo iṣẹ rẹ ni yio ma yìn ọ; awọn enia mimọ́ rẹ yio si ma fi ibukún fun ọ. Nwọn o ma sọ̀rọ ogo ijọba rẹ, nwọn o si ma sọ̀rọ agbara rẹ: Lati mu iṣẹ agbara rẹ̀ di mimọ̀ fun awọn ọmọ enia, ati ọla-nla ijọba rẹ̀ ti o logo, Ijọba rẹ ijọba aiye-raiye ni, ati ijọba rẹ lati iran-diran gbogbo. Oluwa mu gbogbo awọn ti o ṣubu ró; o si gbé gbogbo awọn ti o tẹriba dide. Oju gbogbo enia nwò ọ; iwọ si fun wọn li onjẹ wọn li akokò rẹ̀. Iwọ ṣi ọwọ rẹ, iwọ si tẹ́ ifẹ gbogbo ohun alãye lọrùn. Olododo li Oluwa li ọ̀na rẹ̀ gbogbo, ati alãnu ni iṣẹ rẹ̀ gbogbo. Oluwa wà leti ọdọ gbogbo awọn ti nkepè e, leti ọdọ gbogbo ẹniti nkepè e li otitọ. Yio mu ifẹ awọn ti mbẹ̀ru rẹ̀ ṣẹ: yio gbọ́ igbe wọn pẹlu, yio si gbà wọn. Oluwa da gbogbo awọn ti o fẹ ẹ si: ṣugbọn gbogbo enia buburu ni yio parun. Ẹnu mi yio ma sọ̀rọ iyìn Oluwa: ki gbogbo enia ki o si ma fi ibukún fun orukọ rẹ̀ mimọ́ lai ati lailai.

O. Daf 145:1-21 Yoruba Bible (YCE)

Èmi óo gbé ọ ga, Ọlọrun mi, Ọba mi, n óo máa yin orúkọ rẹ lae ati laelae. Lojoojumọ ni n óo máa yìn ọ́, tí n óo máa yin orúkọ rẹ lae ati laelae. OLUWA tóbi, ìyìn sì yẹ ẹ́ lọpọlọpọ; àwámárìídìí ni títóbi rẹ̀. Láti ìran dé ìran ni a óo máa yin iṣẹ́ rẹ, tí a óo sì máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ agbára ńlá rẹ. Èmi óo máa ṣe àṣàrò lórí ẹwà ògo ọlá ńlá rẹ, ati iṣẹ́ ìyanu rẹ. Eniyan óo máa kéde iṣẹ́ agbára rẹ tí ó yani lẹ́nu, èmi óo sì máa polongo títóbi rẹ. Wọn óo máa pòkìkí bí oore rẹ ti pọ̀ tó, wọn óo sì máa kọrin sókè nípa òdodo rẹ. Aláàánú ni OLUWA, olóore sì ni; kì í yára bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀. OLUWA ṣeun fún gbogbo eniyan, àánú rẹ̀ sì ń bẹ lórí gbogbo ohun tí ó dá. OLUWA, gbogbo ohun tí o dá ni yóo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, àwọn eniyan mímọ́ rẹ yóo sì máa yìn ọ́. Wọn óo máa ròyìn ògo ìjọba rẹ, wọn óo sì máa sọ nípa agbára rẹ, láti mú àwọn eniyan mọ agbára rẹ, ati ẹwà ògo ìjọba rẹ. Ìjọba ayérayé ni ìjọba rẹ, yóo sì máa wà láti ìran dé ìran. Olóòótọ́ ni OLUWA ninu gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀, olóore ọ̀fẹ́ sì ni ninu gbogbo ìṣe rẹ̀. OLUWA gbé gbogbo àwọn tí ń ṣubú lọ dìde, ó sì gbé gbogbo àwọn tí a tẹrí wọn ba nàró. Ojú gbogbo eniyan ń wò ọ́, o sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àsìkò. Ìwọ la ọwọ́ rẹ, o sì tẹ́ gbogbo ẹ̀dá alààyè lọ́rùn. Olódodo ni OLUWA ninu gbogbo ọ̀nà rẹ̀, aláàánú sì ni ninu gbogbo ìṣe rẹ̀. OLUWA súnmọ́ gbogbo àwọn tí ń pè é, àní, àwọn tí ń pè é tọkàntọkàn. Ó ń tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ lọ́rùn; ó ń gbọ́ igbe wọn, ó sì ń gbà wọ́n. OLUWA dá gbogbo àwọn tí ó fẹ́ ẹ sí, ṣugbọn yóo pa gbogbo àwọn eniyan burúkú run. Ẹnu mi yóo máa sọ̀rọ̀ ìyìn OLUWA; kí gbogbo ẹ̀dá máa yin orúkọ rẹ̀ lae ati laelae.

O. Daf 145:1-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èmi yóò gbé ọ ga, Ọlọ́run ọba mi; Èmi yóò yin orúkọ rẹ̀ láé àti láéláé Ní ojoojúmọ́ èmi yóò yìn ọ́ èmi yóò sì pòkìkí orúkọ rẹ láé àti láéláé. Títóbi ni OLúWA. Òun sì ni ó yẹ láti fi ìyìn fún púpọ̀púpọ̀: kò sí ẹni tí ó lè wọn títóbi rẹ̀. Ìran kan yóò máa yin iṣẹ́ rẹ dé ìran mìíràn; wọn yóò máa sọ iṣẹ́ agbára rẹ Wọn yóò máa sọ ìyìn ọláńlá rẹ tí ó lógo, èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú iṣẹ́ ìyanu rẹ. Wọn yóò sọ iṣẹ́ agbára rẹ tí ó ní ẹ̀rù èmi yóò kéde iṣẹ́ ńlá rẹ̀. Wọn yóò ṣe ìrántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà rere rẹ àti orin ayọ̀ òdodo rẹ. Olóore-ọ̀fẹ́ ni OLúWA àti aláàánú ó lọ́ra láti bínú ó sì ní ìfẹ́ púpọ̀. OLúWA dára sí ẹni gbogbo; ó ní àánú lórí ohun gbogbo tí ó dá. Gbogbo ohun tí ìwọ ti dá ni yóò máa yìn ọ́ OLúWA; àwọn ẹni mímọ́ yóò máa pòkìkí rẹ. Wọn yóò sọ ògo ìjọba rẹ wọn yóò sì sọ̀rọ̀ agbára rẹ, Kí gbogbo ènìyàn le mọ iṣẹ́ agbára rẹ̀ àti ọláńlá ìjọba rẹ tí ó lógo. Ìjọba rẹ ìjọba ayérayé ni, àti ìjọba rẹ wà ní gbogbo ìrandíran. OLúWA mú gbogbo àwọn tí ó ṣubú ró ó sì gbé gbogbo àwọn tí ó tẹríba dìde. Ojú gbogbo ènìyàn ń wò ọ́, ó sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó yẹ Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ ìwọ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn. OLúWA jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀ sí gbogbo ohun tí o dá. OLúWA wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́. Ó mú ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ṣẹ; ó gbọ́ igbe wọn, ó sì gbà wọ́n. OLúWA dá gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́ sẹ sí ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹni búburú ní yóò parun. Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ìyìn OLúWA. Jẹ́ kí gbogbo ẹ̀dá yín orúkọ rẹ̀ mímọ́ láé àti láéláé.