O. Daf 135:15-18
O. Daf 135:15-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Fadaka on wura li ere awọn keferi, iṣẹ ọwọ enia. Nwọn li ẹnu, ṣugbọn nwọn kò sọ̀rọ; nwọn li oju, ṣugbọn nwọn kò fi riran. Nwọn li eti, ṣugbọn nwọn kò fi gbọran; bẹ̃ni kò si ẽmi kan li ẹnu wọn. Awọn ti o ṣe wọn dabi wọn: bẹ̃ si li olukuluku ẹniti o gbẹkẹle wọn.
O. Daf 135:15-18 Yoruba Bible (YCE)
Wúrà ati fadaka ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù fi ṣe oriṣa wọn, iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n. Wọ́n lẹ́nu, ṣugbọn wọn kò lè sọ̀rọ̀, wọ́n lójú, ṣugbọn wọn kò lè ríran. Wọ́n létí, ṣugbọn wọn kò lè gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí èémí kan ní ẹnu wọn. Àwọn tí ń ṣe wọ́n yóo dàbí wọn, ati gbogbo àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé wọn.
O. Daf 135:15-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà, iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni. Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀; wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran. Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀; bẹ́ẹ̀ ni kò si èémí kan ní ẹnu wọn Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn.