O. Daf 135:1-21

O. Daf 135:1-21 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹ yìn Oluwa, Ẹ yìn orukọ Oluwa; ẹ yìn i, ẹnyin iranṣẹ Oluwa. Ẹnyin ti nduro ni ile Oluwa, ninu agbalá ile Ọlọrun wa. Ẹ yìn Oluwa: nitori ti Oluwa ṣeun; ẹ kọrin iyìn si orukọ rẹ̀; ni orin ti o dùn. Nitori ti Oluwa ti yàn Jakobu fun ara rẹ̀; ani Israeli fun iṣura ãyo rẹ̀. Nitori ti emi mọ̀ pe Oluwa tobi, ati pe Oluwa jù gbogbo oriṣa lọ. Ohunkohun ti o wù Oluwa, on ni iṣe li ọrun, ati li aiye, li okun, ati ni ọgbun gbogbo. O mu ikũku gòke lati opin ilẹ wá: o da manamana fun òjo: o nmu afẹfẹ ti inu ile iṣura rẹ̀ wá. Ẹniti o kọlù awọn akọbi Egipti, ati ti enia ati ti ẹranko. Ẹniti o rán àmi ati iṣẹ iyanu si ãrin rẹ, iwọ Egipti, si ara Farao, ati si ara awọn iranṣẹ rẹ̀ gbogbo. Ẹniti o kọlu awọn orilẹ-ède pupọ̀, ti o si pa awọn alagbara ọba. Sihoni, ọba awọn ara Amori, ati Ogu, ọba Baṣani, ati gbogbo ijọba Kenaani: O si fi ilẹ wọn funni ni ini, ini fun Israeli, enia rẹ̀. Oluwa, orukọ rẹ duro lailai; iranti rẹ Oluwa, lati iran-diran. Nitori ti Oluwa yio ṣe idajọ awọn enia rẹ̀, yio si ṣe iyọ́nu si awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, Fadaka on wura li ere awọn keferi, iṣẹ ọwọ enia. Nwọn li ẹnu, ṣugbọn nwọn kò sọ̀rọ; nwọn li oju, ṣugbọn nwọn kò fi riran. Nwọn li eti, ṣugbọn nwọn kò fi gbọran; bẹ̃ni kò si ẽmi kan li ẹnu wọn. Awọn ti o ṣe wọn dabi wọn: bẹ̃ si li olukuluku ẹniti o gbẹkẹle wọn. Ẹnyin arale Israeli, ẹ fi ibukún fun Oluwa, ẹnyin arale Aaroni, ẹ fi ibukún fun Oluwa. Ẹnyin arale Lefi, ẹ fi ibukún fun Oluwa; ẹnyin ti o bẹ̀ru Oluwa, ẹ fi ibukún fun Oluwa. Olubukún li Oluwa, lati Sioni wá, ti ngbe Jerusalemu. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

O. Daf 135:1-21 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ yin OLUWA. Ẹ yin orúkọ OLUWA; ẹ yìn ín, ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń jọ́sìn ninu ilé OLUWA, tí ẹ wà ní àgbàlá ilé Ọlọrun wa. Ẹ yin OLUWA, nítorí pé ó ṣeun; ẹ kọrin ìyìn sí i, nítorí pé olóore ọ̀fẹ́ ni. Nítorí pé OLUWA ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀, ó ti yan Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀. Èmi mọ̀ pé OLUWA tóbi, ati pé ó ju gbogbo oriṣa lọ. Bí ó ti wu OLUWA ni ó ń ṣe lọ́run ati láyé, ninu òkun ati ninu ibú. Òun ló gbá ìkùukùu jọ láti òpin ilẹ̀ ayé, ó fi mànàmáná fún òjò, ó sì mú afẹ́fẹ́ jáde láti inú ilé ìṣúra rẹ̀. Òun ló pa àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti, ati teniyan ati tẹran ọ̀sìn. Ẹni tí ó rán iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu sí ilẹ̀ Ijipti, ó rán sí Farao ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀. Ẹni tí ó pa orílẹ̀-èdè pupọ run; ó pa àwọn ọba alágbára: Sihoni ọba àwọn Amori, Ogu ọba Baṣani, ati gbogbo ọba ilẹ̀ Kenaani. Ó pín ilẹ̀ wọn fún àwọn eniyan rẹ̀; ó pín in fún Israẹli bí ohun ìní wọn. OLUWA, orúkọ rẹ yóo wà títí lae, òkìkí rẹ óo sì máa kàn títí ayé. OLUWA yóo dá àwọn eniyan rẹ̀ láre, yóo sì ṣàánú àwọn iranṣẹ rẹ̀. Wúrà ati fadaka ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù fi ṣe oriṣa wọn, iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n. Wọ́n lẹ́nu, ṣugbọn wọn kò lè sọ̀rọ̀, wọ́n lójú, ṣugbọn wọn kò lè ríran. Wọ́n létí, ṣugbọn wọn kò lè gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí èémí kan ní ẹnu wọn. Àwọn tí ń ṣe wọ́n yóo dàbí wọn, ati gbogbo àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé wọn. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin ará ilé Aaroni, ẹ yin OLUWA! Ẹ̀yin ará ilé Lefi, ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ yìn ín! Ẹ yin OLUWA ní Sioni, ẹni tí ń gbé Jerusalẹmu!

O. Daf 135:1-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ yin OLúWA. Ẹ yin orúkọ OLúWA; ẹ yìn ín, ẹ̀yin ìránṣẹ́ OLúWA. Ẹ̀yin tí ń dúró ní ilé OLúWA, nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run wa. Ẹ yin OLúWA: nítorí tí OLúWA ṣeun; ẹ kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ̀; nítorí tí ó dùn. Nítorí tí OLúWA ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀; àní Israẹli fún ìṣúra ààyò rẹ̀. Nítorí tí èmi mọ̀ pé OLúWA tóbi, àti pé Olúwa jù gbogbo òrìṣà lọ. OLúWA ṣe ohunkóhun tí ó wù ú, ní ọ̀run àti ní ayé, ní Òkun àti ní ọ̀gbun gbogbo. Ó mú ìkùùkuu gòkè láti òpin ilẹ̀ wá: ó dá mọ̀nàmọ́ná fún òjò: ó ń mú afẹ́fẹ́ ti inú ilẹ̀ ìṣúra rẹ̀ wá. Ẹni tí ó kọlu àwọn àkọ́bí Ejibiti, àti ti ènìyàn àti ti ẹranko. Ẹni tí ó rán iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu sí àárín rẹ̀, ìwọ Ejibiti, sí ara Farao àti sí ara àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo. Ẹni tí ó kọlu àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀, tí ó sì pa àwọn alágbára ọba. Sihoni, ọba àwọn ará Amori, àti Ogu, ọba Baṣani, àti gbogbo ìjọba Kenaani: Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní, ìní fún Israẹli, ènìyàn rẹ̀. OLúWA orúkọ rẹ dúró láéláé; ìrántí rẹ OLúWA, láti ìrandíran. Nítorí tí OLúWA yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀, yóò sì ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà, iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni. Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀; wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran. Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀; bẹ́ẹ̀ ni kò si èémí kan ní ẹnu wọn Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn. Ẹ̀yin ara ilé Israẹli, ẹ fi ìbùkún fún OLúWA, ẹ̀yin ará ilé Aaroni, fi ìbùkún fún OLúWA. Ẹ̀yin ará ilé Lefi, fi ìbùkún fún OLúWA; ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù OLúWA, fi ìbùkún fún OLúWA. Olùbùkún ni OLúWA, láti Sioni wá, tí ń gbé Jerusalẹmu.