Ẹ yìn Oluwa, Ẹ yìn orukọ Oluwa; ẹ yìn i, ẹnyin iranṣẹ Oluwa.
Ẹnyin ti nduro ni ile Oluwa, ninu agbalá ile Ọlọrun wa.
Ẹ yìn Oluwa: nitori ti Oluwa ṣeun; ẹ kọrin iyìn si orukọ rẹ̀; ni orin ti o dùn.
Nitori ti Oluwa ti yàn Jakobu fun ara rẹ̀; ani Israeli fun iṣura ãyo rẹ̀.
Nitori ti emi mọ̀ pe Oluwa tobi, ati pe Oluwa jù gbogbo oriṣa lọ.
Ohunkohun ti o wù Oluwa, on ni iṣe li ọrun, ati li aiye, li okun, ati ni ọgbun gbogbo.
O mu ikũku gòke lati opin ilẹ wá: o da manamana fun òjo: o nmu afẹfẹ ti inu ile iṣura rẹ̀ wá.
Ẹniti o kọlù awọn akọbi Egipti, ati ti enia ati ti ẹranko.
Ẹniti o rán àmi ati iṣẹ iyanu si ãrin rẹ, iwọ Egipti, si ara Farao, ati si ara awọn iranṣẹ rẹ̀ gbogbo.
Ẹniti o kọlu awọn orilẹ-ède pupọ̀, ti o si pa awọn alagbara ọba.
Sihoni, ọba awọn ara Amori, ati Ogu, ọba Baṣani, ati gbogbo ijọba Kenaani:
O si fi ilẹ wọn funni ni ini, ini fun Israeli, enia rẹ̀.
Oluwa, orukọ rẹ duro lailai; iranti rẹ Oluwa, lati iran-diran.
Nitori ti Oluwa yio ṣe idajọ awọn enia rẹ̀, yio si ṣe iyọ́nu si awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀,
Fadaka on wura li ere awọn keferi, iṣẹ ọwọ enia.
Nwọn li ẹnu, ṣugbọn nwọn kò sọ̀rọ; nwọn li oju, ṣugbọn nwọn kò fi riran.
Nwọn li eti, ṣugbọn nwọn kò fi gbọran; bẹ̃ni kò si ẽmi kan li ẹnu wọn.
Awọn ti o ṣe wọn dabi wọn: bẹ̃ si li olukuluku ẹniti o gbẹkẹle wọn.
Ẹnyin arale Israeli, ẹ fi ibukún fun Oluwa, ẹnyin arale Aaroni, ẹ fi ibukún fun Oluwa.
Ẹnyin arale Lefi, ẹ fi ibukún fun Oluwa; ẹnyin ti o bẹ̀ru Oluwa, ẹ fi ibukún fun Oluwa.
Olubukún li Oluwa, lati Sioni wá, ti ngbe Jerusalemu. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.