O. Daf 119:1-24

O. Daf 119:1-24 Bibeli Mimọ (YBCV)

IBUKÚN ni fun awọn ẹniti o pé li ọ̀na na, ti nrìn ninu ofin Oluwa. Ibukún ni fun awọn ti npa ẹri rẹ̀ mọ́, ti si nwá a kiri tinu-tinu gbogbo. Nwọn kò dẹṣẹ pẹlu: nwọn nrìn li ọ̀na rẹ̀. Iwọ ti paṣẹ fun wa lati pa ẹkọ́ rẹ mọ́ gidigidi. Ọ̀na mi iba jẹ là silẹ lati ma pa ilana rẹ mọ́! Nigbana li oju kì yio tì mi, nigbati emi ba njuba aṣẹ rẹ gbogbo. Emi o ma fi aiya diduro-ṣinṣin yìn ọ, nigbati emi ba ti kọ́ idajọ ododo rẹ. Emi o pa ilana rẹ mọ́: máṣe kọ̀ mi silẹ patapata. Nipa ewo li ọdọmọkunrin yio fi mu ọ̀na rẹ̀ mọ́? nipa ikiyesi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Tinu-tinu mi gbogbo li emi fi ṣe afẹri rẹ: máṣe jẹ ki emi ṣina kuro ninu aṣẹ rẹ. Ọ̀rọ rẹ ni mo pamọ́ li aiya mi, ki emi ki o má ba ṣẹ̀ si ọ. Olubukún ni iwọ, Oluwa: kọ́ mi ni ilana rẹ. Ẹnu mi li emi fi nsọ gbogbo idajọ ẹnu rẹ. Emi ti nyọ̀ li ọ̀na ẹri rẹ, bi lori oniruru ọrọ̀. Emi o ma ṣe àṣaro ninu ẹkọ́ rẹ emi o si ma juba ọ̀na rẹ. Emi o ma ṣe inu-didùn ninu ilana rẹ: emi kì yio gbagbe ọ̀rọ rẹ. Fi ọ̀pọlọpọ ba iranṣẹ rẹ ṣe, ki emi ki o le wà lãye, ki emi ki o le ma pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Là mi li oju, ki emi ki o le ma wò ohun iyanu wọnni lati inu ofin rẹ. Alejo li emi li aiye: máṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fun mi. Aiya mi bù nitori ifojusọna si idajọ rẹ nigbagbogbo. Iwọ ti ba awọn agberaga wi, ti a ti fi gégun, ti o ti ṣina kuro nipa aṣẹ rẹ. Mu ẹ̀gan ati àbuku kuro lara mi; nitoriti emi ti pa ẹri rẹ mọ́. Awọn ọmọ-alade joko pẹlu, nwọn nsọ̀rọ mi: ṣugbọn iranṣẹ rẹ nṣe àṣaro ninu ilana rẹ: Ẹri rẹ pẹlu ni didùn-inu mi ati ìgbimọ mi.

O. Daf 119:1-24 Yoruba Bible (YCE)

Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ìgbé ayé wọn kò lábàwọ́n, àní àwọn tí ń rìn gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́, tí wọn ń fi tọkàntọkàn ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Àwọn tí wọn kò dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn tí wọn ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀. O ti pàṣẹ pé kí á fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́, Ìbá ti dára tó tí mo bá lè dúró ṣinṣin ninu ìlànà rẹ! Òun ni ojú kò fi ní tì mí, nítorí pé òfin rẹ ni mò ń tẹ̀lé. N óo yìn ọ́ pẹlu inú mímọ́, bí mo ṣe ń kọ́ ìlànà òdodo rẹ. N óo máa pa òfin rẹ mọ́, má kọ̀ mí sílẹ̀ patapata. Báwo ni ọdọmọkunrin ṣe lè mú kí ọ̀nà rẹ̀ mọ́? Nípa títẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ ni. Tọkàntọkàn ni mo fi ń ṣe ìfẹ́ rẹ, má jẹ́ kí n ṣìnà kúrò ninu òfin rẹ. Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ sọ́kàn, kí n má baà ṣẹ̀ ọ́. Ìyìn ni fún ọ, OLUWA, kọ́ mi ní ìlànà rẹ! Mo fi ẹnu mi kéde gbogbo àṣẹ tí o pa. Mo láyọ̀ ninu pípa òfin rẹ mọ́, bí ẹni tí ó ní ọpọlọpọ ọrọ̀. N óo máa ṣe àṣàrò ninu òfin rẹ, n óo sì kọjú sí ọ̀nà rẹ. N óo láyọ̀ ninu àwọn ìlànà rẹ, n kò ní gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ. Ṣe ọpọlọpọ oore fún èmi iranṣẹ rẹ, kí n lè wà láàyè, kí n sì máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ. Là mí lójú, kí n lè rí àwọn nǹkan ìyanu tí ó wà ninu òfin rẹ. Àlejò ni mí láyé, má fi òfin rẹ pamọ́ fún mi. Òùngbẹ títẹ̀lé òfin rẹ ń gbẹ ọkàn mi, nígbà gbogbo. O bá àwọn onigbeeraga wí, àwọn ẹni ègún, tí wọn kò pa òfin rẹ mọ́. Mú ẹ̀gàn ati àbùkù wọn kúrò lára mi, nítorí pé mo ti pa òfin rẹ mọ́. Bí àwọn ìjòyè tilẹ̀ gbìmọ̀ràn ọ̀tẹ̀ nítorí mi, sibẹ, èmi iranṣẹ rẹ yóo ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ. Àwọn òfin rẹ ni dídùn inú mi, àwọn ni olùdámọ̀ràn mi.

O. Daf 119:1-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́ṣẹ̀, ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin OLúWA, Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́ tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn. Wọn kò ṣe ohun tí kò dára; wọ́n rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Ìwọ ti la ìlànà rẹ̀ sílẹ̀ kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi. Ọ̀nà mi ìbá dúró ṣinṣin láti máa pa òfin rẹ̀ mọ́! Nígbà náà, ojú kò ní tì mí nígbà tí mo bá ń kíyèsi àṣẹ rẹ̀ gbogbo. Èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú ọkàn ìdúró ṣinṣin bí èmi bá ti kọ́ òfin òdodo rẹ̀. Èmi yóò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀: Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ pátápátá. Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ yóò ti ṣe pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́? Láti máa gbé ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ rẹ. Èmi wá ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi má ṣe jẹ́ kí èmi yapa kúrò nínú àṣẹ rẹ. Èmi ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́ ní ọkàn mi kí èmi má ba à ṣẹ̀ sí ọ Ìyìn ni fún OLúWA; kọ́ mi ní àṣẹ rẹ. Pẹ̀lú ètè mi èmi tún ṣírò gbogbo òfin tí ó wá láti ẹnu rẹ. Èmi ń yọ̀ ní ọ̀nà ẹ̀rí rẹ, bí ènìyàn ṣe ń yọ̀ nínú ọláńlá. Èmi ń ṣe àṣàrò nínú ìlànà rẹ èmi sì kíyèsi ọ̀nà rẹ Inú mi dùn sí àṣẹ rẹ; èmi kì yóò gbàgbé ọ̀nà rẹ. Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ, èmi yóò sì wà láààyè; èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ rẹ. La ojú mi kí èmi lè ríran rí ohun ìyanu tí ó wà nínú òfin rẹ. Àlejò ní èmi jẹ́ láyé; Má ṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fún mi. Ọkàn mi pòruurù pẹ̀lú ìfojúsọ́nà nítorí òfin rẹ nígbà gbogbo. Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn ún tí ó ṣìnà kúrò nínú àṣẹ rẹ. Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi, nítorí èmi pa òfin rẹ mọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọpọ̀, wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi, ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ rẹ. Òfin rẹ ni dídùn inú mi; àwọn ní olùbádámọ̀ràn mi.

O. Daf 119:1-24

O. Daf 119:1-24 YBCVO. Daf 119:1-24 YBCV