O. Daf 116:1-19
O. Daf 116:1-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
EMI fẹ Oluwa nitori ti o gbọ́ ohùn mi ati ẹ̀bẹ mi. Nitori ti o dẹ eti rẹ̀ si mi, nitorina li emi o ma kepè e niwọn ọjọ mi. Ikẹkùn ikú yi mi ka, ati irora isà-òkú di mi mu; mo ri iyọnu ati ikãnu. Nigbana ni mo kepè orukọ Oluwa; Oluwa, emi bẹ̀ ọ, gbà ọkàn mi. Olore-ọfẹ li Oluwa, ati olododo; nitõtọ, alãnu li Ọlọrun wa. Oluwa pa awọn alaimọ̀kan mọ́: a rẹ̀ mi silẹ tan, o si ràn mi lọwọ. Pada si ibi isimi rẹ, iwọ ọkàn mi; nitori ti Oluwa ṣe é lọ́pọlọpọ fun ọ. Nitori ti iwọ gbà ọkàn mi lọwọ ikú, oju mi lọwọ omije, ati ẹsẹ mi lọwọ iṣubu. Emi o ma rìn niwaju Oluwa ni ilẹ alãye. Emi gbagbọ́, nitorina li emi ṣe sọ: mo ri ipọnju gidigidi. Mo wi ni iyara mi pe: Eke ni gbogbo enia. Kili emi o san fun Oluwa nitori gbogbo ore rẹ̀ si mi? Emi o mu ago igbala, emi o si ma kepè orukọ Oluwa. Emi o san ileri ifẹ mi fun Oluwa, nitõtọ li oju gbogbo awọn enia rẹ̀. Iyebiye ni ikú awọn ayanfẹ rẹ̀ li oju Oluwa. Oluwa nitõtọ iranṣẹ rẹ li emi; iranṣẹ rẹ̀ li emi, ati ọmọ iranṣẹ-birin rẹ: iwọ ti tú ìde mi. Emi o ru ẹbọ ọpẹ si ọ, emi o ma ke pè orukọ Oluwa. Emi o san ileri ifẹ mi fun Oluwa, nitõtọ li oju gbogbo awọn enia rẹ̀. Ninu àgbala ile Oluwa, li arin rẹ, iwọ Jerusalemu. Ẹ yìn Oluwa.
O. Daf 116:1-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi fẹ́ràn OLúWA, nítorí ó gbọ́ ohùn mi; ó gbọ́ ẹkún mi fún àánú. Nítorí ó yí etí rẹ̀ padà sí mi, èmi yóò máa pè é ni wọ́n ìgbà tí mo wà láààyè. Okùn ikú yí mi ká, ìrora isà òkú wá sórí mi; ìyọnu àti ìbànújẹ́ borí mi. Nígbà náà ni mo ké pe orúkọ OLúWA: “OLúWA, èmi bẹ̀ ọ́, gba ọkàn mi!” OLúWA ní oore-ọ̀fẹ́, ó sì ní òdodo; Ọlọ́run wa kún fún àánú. OLúWA pa àwọn ọlọ́kàn fífúyẹ́ mọ́ nígbà tí mo wà nínú àìní ńlá, ó gbà mí. Padà, ìwọ ọkàn mi, sí ibi ìsinmi rẹ, nítorí OLúWA ṣe dáradára sí ọ. Nítorí ìwọ, OLúWA, ti gba ọkàn mi kúrò lọ́wọ́ ikú, ojú mi kúrò lọ́wọ́ omijé, àti ẹsẹ̀ mi kúrò lọ́wọ́ ìṣubú, Nítorí èmi yóò máa rìn níwájú OLúWA ní ilẹ̀ alààyè. Èmi gbàgbọ́; nítorí náà mo wí pé, “èmi rí ìpọ́njú púpọ̀”. Àti nínú ìdààmú mi mo wí pé “Èké ni gbogbo ènìyàn”. Kí ni èmi yóò san fún OLúWA nítorí gbogbo rere rẹ̀ sí mi? Èmi yóò gbé ago ìgbàlà sókè èmi yóò sì máa ké pe orúkọ OLúWA. Èmi yóò mú ìlérí mi ṣẹ sí OLúWA ní ojú àwọn ènìyàn rẹ̀. Iyebíye ní ojú OLúWA àti ikú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀. OLúWA, nítòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ ni mo jẹ́; èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ; ó ti tú mi sílẹ̀ nínú ìdè mi. Èmi yóò rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ èmi yóò sì ké pe orúkọ OLúWA Èmi yóò mú ìlérí mi sẹ sí OLúWA ní ojú gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀, Nínú àgbàlá ilé OLúWA ní àárín rẹ̀, ìwọ Jerusalẹmu.
O. Daf 116:1-19 Yoruba Bible (YCE)
Mo fẹ́ràn OLUWA nítorí pé ó gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ mi. Nítorí pé ó tẹ́tí sí mi, nítorí náà, n óo máa ké pè é níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè. Tàkúté ikú yí mi ká; ìrora isà òkú dé bá mi; ìyọnu ati ìnira sì bò mí mọ́lẹ̀. Nígbà náà ni mo ké pe OLUWA, mo ní, “OLUWA, mo bẹ̀ ọ́, gbà mí!” Olóore ọ̀fẹ́ ati olódodo ni OLUWA, aláàánú ni Ọlọrun wa. OLUWA a máa pa àwọn onírẹ̀lẹ̀ mọ́; nígbà tí a rẹ̀ mí sílẹ̀, ó gbà mí. Sinmi ìwọ ọkàn mi, bíi ti àtẹ̀yìnwá, nítorí pé OLUWA ṣeun fún ọ lọpọlọpọ. Nítorí ìwọ OLUWA ti gba ọkàn mi lọ́wọ́ ikú, o gba ojú mi lọ́wọ́ omijé, o sì gba ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú. Mò ń rìn níwájú OLUWA, lórí ilẹ̀ alààyè. Igbagbọ mi kò yẹ̀, nígbà tí mo tilẹ̀ wí pé, “Ìpọ́njú dé bá mi gidigidi.” Mo wí ninu ìdààmú ọkàn pé, “Èké ni gbogbo eniyan.” Kí ni n óo san fún OLUWA, nítorí gbogbo oore rẹ̀ lórí mi? N óo mu ẹbọ nǹkan mímu wá fún OLUWA, n óo sì pe orúkọ rẹ̀. N óo san ẹ̀jẹ́ mi fún OLUWA, lójú gbogbo àwọn eniyan rẹ̀. Iyebíye ni ikú àwọn eniyan rẹ̀ mímọ́ lójú OLUWA. OLUWA, iranṣẹ rẹ ni mo jẹ́, iranṣẹ rẹ ni mo jẹ́, àní, ọmọ iranṣẹbinrin rẹ. O ti tú ìdè mi. N óo rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ, n óo sì pe orúkọ rẹ OLUWA. N óo san ẹ̀jẹ́ mi fún OLUWA lójú gbogbo àwọn eniyan rẹ̀, ninu àgbàlá ilé OLUWA, láàrin rẹ, ìwọ ìlú Jerusalẹmu.