O. Daf 109:1-31

O. Daf 109:1-31 Bibeli Mimọ (YBCV)

MÁṢE pa ẹnu rẹ mọ́, Ọlọrun iyìn mi; Nitori ti ẹnu awọn enia buburu, ati ẹnu awọn ẹlẹtan yà silẹ si mi: nwọn ti fi ahọn eke sọ̀rọ si mi. Nwọn si fi ọ̀rọ irira yi mi ka kiri; nwọn si mba mi ja li ainidi. Nipo ifẹ mi nwọn nṣe ọta mi: ṣugbọn emi ngba adura. Nwọn si fi ibi san ire fun mi, ati irira fun ifẹ mi. Yan enia buburu tì i: jẹ ki Olufisùn ki o duro li ọwọ ọtún rẹ̀. Nigbati a o ṣe idajọ rẹ̀, ki a da a lẹbi: ki adura rẹ̀ ki o di ẹ̀ṣẹ; Ki ọjọ rẹ̀ ki o kuru; ki ẹlomiran ki o rọpo iṣẹ rẹ̀. Ki awọn ọmọ rẹ̀ ki o di alainibaba, ki aya rẹ̀ ki o di opó. Jẹ ki awọn ọmọ rẹ̀ ki o di alarinkiri, ti nṣagbe: ki nwọn ki o ma tọrọ onjẹ jina si ibi ahoro wọn. Jẹ ki alọnilọwọ-gbà ki o mu ohun gbogbo ti o ni; ki alejo ki o kó èrè iṣẹ́ rẹ̀ lọ. Ki ẹnikẹni ki o má wà lati ṣãnu fun u: má si ṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o si lati ṣe oju rere fun awọn ọmọ rẹ̀ alainibaba. Ki a ke ati ọmọ-de-ọmọ rẹ̀ kuro, ati ni iran ti mbọ̀ ki orukọ wọn ki o parẹ. Ki a ma ranti ẹ̀ṣẹ awọn baba rẹ̀ lọdọ Oluwa; má si jẹ ki a nù ẹ̀ṣẹ iya rẹ̀ nù. Jẹ ki nwọn ki o wà niwaju Oluwa nigbagbogbo, ki o le ke iranti wọn kuro lori ilẹ. Nitori ti kò ranti lati ṣãnu, ṣugbọn o ṣe inunibini si ọkunrin talaka ati olupọnju nì, ki o le pa onirobinujẹ-ọkàn. Bi o ti fẹ egun, bẹ̃ni ki o de si i: bi inu rẹ̀ kò ti dùn si ire, bẹ̃ni ki o jina si i. Bi o ti fi egun wọ ara rẹ li aṣọ bi ẹwu rẹ̀, bẹ̃ni ki o wá si inu rẹ̀ bi omi, ati bi orõro sinu egungun rẹ̀. Jẹ ki o ri fun u bi aṣọ ti o bò o lara, ati fun àmure ti o fi gbajá nigbagbogbo. Eyi li ère awọn ọta mi lati ọwọ Oluwa wá, ati ti awọn ti nsọ̀rọ ibi si ọkàn mi. Ṣugbọn iwọ ṣe fun mi, Ọlọrun Oluwa, nitori orukọ rẹ: nitoriti ãnu rẹ dara, iwọ gbà mi. Nitoripe talaka ati olupọnju li emi aiya mi si gbọgbẹ ninu mi. Emi nkọja lọ bi ojiji ti o nfà sẹhin, emi ntì soke tì sodò bi eṣú. Ẽkun mi di ailera nitori igbawẹ; ẹran-ara mi si gbẹ nitori ailọra. Emi di ẹ̀gan fun wọn pẹlu: nigbati nwọn wò mi, nwọn mi ori wọn. Ràn mi lọwọ, Oluwa Ọlọrun mi: gbà mi gẹgẹ bi ãnu rẹ. Ki nwọn ki o le mọ̀ pe ọwọ rẹ li eyi; pe Iwọ, Oluwa, li o ṣe e. Nwọn o ma gegun, ṣugbọn iwọ ma sure: nigbati nwọn ba dide, ki oju ki o tì wọn; ṣugbọn iranṣẹ rẹ yio yọ̀. Jẹ ki a fi ìtiju wọ̀ awọn ọta mi li aṣọ, ki nwọn ki o si fi idaru-dapọ̀ wọn bò ara, bi ẹnipe ẹ̀wu. Emi o ma fi ẹnu mi yìn Oluwa gidigidi; nitõtọ, emi o ma yìn i lãrin ọ̀pọ enia. Nitori ti yio duro li ọwọ ọtún olupọnju, lati gbà a lọwọ awọn ti o nda ọkàn rẹ̀ lẹbi.

O. Daf 109:1-31 Yoruba Bible (YCE)

Má dákẹ́, ìwọ Ọlọrun tí mò ń yìn. Nítorí pé ẹnu àwọn eniyan burúkú ati ti àwọn ẹlẹ́tàn kò dákẹ́, wọ́n ń sọ̀rọ̀ èké nípa mi. Wọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ káàkiri nípa mi, wọ́n sì ń gbógun tì mí láìnídìí. Èmi fẹ́ràn wọn; ṣugbọn ẹ̀sùn ni wọ́n fi ń kàn mí, sibẹ, adura ni mò ń gbà fún wọn. Ibi ni wọ́n fí ń san oore fún mi, ìkórìíra ni wọ́n sì fi ń san ìfẹ́ tí mo ní sí wọn. Yan eniyan burúkú tì í, jẹ́ kí ẹlẹ́sùn èké kó o sẹ́jọ́. Nígbà tí a bá ń dá ẹjọ́ rẹ̀, jẹ́ kí wọn dá a lẹ́bi; kí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ di ọ̀ràn sí i lọ́rùn. Ṣe é ní ẹlẹ́mìí kúkúrú, kí ohun ìní rẹ̀ di ti àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà. Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìníbaba, kí aya rẹ̀ di opó. Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di alárìnká, kí wọn máa ṣagbe kiri; kí á lé wọn jáde kúrò ninu ahoro tí wọn ń gbé. Kí ẹni tí ó jẹ lówó gba gbogbo ohun ìní rẹ̀, kí ẹni ẹlẹ́ni sì kó èrè iṣẹ́ rẹ̀. Kí ó má bá aláàánú pàdé, kí ẹnikẹ́ni má sì ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ti di aláìníbaba. Kí ìran rẹ̀ run, kí orúkọ rẹ̀ parẹ́ lórí àwọn ọmọ rẹ̀. Kí OLUWA máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba rẹ̀, kí ó má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ ìyá rẹ̀ rẹ́. Kí OLUWA máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ wọn nígbà gbogbo, kí á má sì ranti ìran wọn mọ́ láyé. Nítorí pé kò ronú láti ṣàánú, ṣugbọn ó ṣe inúnibíni talaka ati aláìní, ati sí oníròbìnújẹ́ títí a fi pa wọ́n. Ó fẹ́ràn láti máa ṣépè; nítorí náà kí èpè rẹ̀ dà lé e lórí; inú rẹ̀ kò dùn sí ìre, nítorí náà kí ìre jìnnà sí i. Ó gbé èpè wọ̀ bí ẹ̀wù, kí èpè mù ún bí omi, kí ó sì wọ inú egungun rẹ̀ dé mùdùnmúdùn. Kí èpè di aṣọ ìbora fún un, ati ọ̀já ìgbànú. Bẹ́ẹ̀ ni kí OLUWA ṣe sí àwọn ọ̀tá mi, àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi nípa mi! Ṣugbọn, ìwọ OLUWA Ọlọrun mi, gbèjà mi nítorí orúkọ rẹ, gbà mí! Nítorí ìfẹ́ rere rẹ tí kì í yẹ̀. Nítorí pé talaka ati aláìní ni mí, ọkàn mí bàjẹ́ lọpọlọpọ. Mò ń parẹ́ lọ bí òjìji àṣáálẹ́, a ti gbọ̀n mí dànù bí eṣú. Ẹsẹ̀ mi kò ranlẹ̀ mọ́ nítorí ààwẹ̀ gbígbà, mo rù kan egungun. Mo di ẹni ẹ̀gàn níwájú àwọn ọ̀tá mi, wọ́n ń wò mí ní àwòmirí. Ràn mí lọ́wọ́, OLUWA, Ọlọrun mi, gbà mí, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni èyí, kí wọn mọ̀ pé, ìwọ OLUWA ni o ṣe é. Kí wọn máa ṣépè, ṣugbọn kí ìwọ máa súre. Kí ojú ti àwọn alátakò mi, kí inú èmi, iranṣẹ rẹ, sì máa dùn. Kí ìtìjú bo àwọn ọ̀tá mi bi aṣọ, àní, kí wọn gbé ìtìjú wọ̀ bí ẹ̀wù. N óo máa fi ẹnu mi yin OLUWA gidigidi, àní, n óo máa yìn ín ní àwùjọ ọ̀pọ̀ eniyan. Nítorí pé ó dúró ti aláìní láti gbà á lọ́wọ́ àwọn tí ó dájọ́ ikú fún un.

O. Daf 109:1-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọlọ́run, ti èmi ń fi ìyìn fún Má ṣe dákẹ́ Nítorí àwọn ènìyàn búburú àti ẹlẹ́tàn ti ya ẹnu wọn sí mi wọ́n ti fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ sí mi Wọ́n fi ọ̀rọ̀ ìríra yí mi káàkiri; wọ́n bá mi jà láìnídìí Nípò ìfẹ́ mi, wọn ń ṣe ọ̀tá mi, ṣùgbọ́n èmi ń gba àdúrà. Wọ́n sì fi ibi san ìre fún mi àti ìríra fún ìfẹ́ mi. Yan àwọn ènìyàn búburú láti dojúkọ jẹ́ kí àwọn olùfisùn dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Kí a dá a lẹ́bi nígbà tí a bá ṣe ìdájọ́ kí àdúrà rẹ̀ kí ó lè di ìkọ̀sílẹ̀ Kí ọjọ́ rẹ̀ kí ó kúrú kí ẹlòmíràn kí ó rọ́pò iṣẹ́ rẹ̀ Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìní baba kí aya rẹ̀ sì di opó Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe kiri kí wọn máa tọrọ oúnjẹ jìnnà sí ibi ahoro wọn Jẹ́ kí alọ́nilọ́wọ́gbà kí ó mú ohun gbogbo tí ó ní jẹ́ kí àlejò kí o kó èrè iṣẹ́ rẹ̀ lọ Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ṣe àánú fún un tàbí kí wọn káàánú lórí àwọn ọmọ rẹ̀ aláìní baba Kí a gé àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ kúrò kí orúkọ wọn kí ó parẹ́ ní ìran tí ń bọ̀ Kí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba rẹ̀ kí ó wà ní ìrántí ní ọ̀dọ̀ OLúWA Má ṣe jẹ́ kí a yọ ẹ̀ṣẹ̀ ìyá wọn kúrò Jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí ó wà ní ìrántí níwájú OLúWA kí ó lè gé ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀. Nítorí kò rántí láti ṣàánú, ṣùgbọ́n ó ṣe inúnibíni sí ọkùnrin tálákà àti olùpọ́njú, kí ó lè pa oníròbìnújẹ́ ọkàn. Ó fẹ́ràn láti máa mú ègún wá sí orí rẹ̀: bi inú rẹ̀ kò ti dùn si ìre, bẹ́ẹ̀ ni kí ó jìnnà sí. Bí ó ti fi ègún wọ ará rẹ̀ láṣọ bí ẹ̀wù bẹ́ẹ̀ ni kí ó wá sí inú rẹ̀ bí omi Jẹ́ kí ó rí fún un bí aṣọ tí a dà bò ó ní ara, àti fún àmùrè tí ó fi gba ọ̀já nígbà gbogbo Èyí ni èrè àwọn ọ̀tá mi láti ọwọ́ OLúWA wá; àti ti àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọkàn mi. Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ ṣe fún mi OLúWA Olódùmarè, ṣe rere fún mi nítorí orúkọ rẹ Nítorí tí àánú rẹ dára, ìwọ gbà mí Nítorí pé tálákà àti aláìní ni mí, àyà mi sì gbọgbẹ́ nínú mi. Èmi ń kọjá lọ bí òjìji tí àṣálẹ́, mo ń gbọ̀n sókè bí eṣú. Eékún mi di aláìlera nítorí àwẹ̀ gbígbà ẹran-ara mi sì gbẹ nítorí àìlera mi. Mo dàbí ẹ̀gàn fún àwọn olùfisùn mi; nígbà tí wọn wò mí, wọ́n gbọn orí wọn. Ràn mí lọ́wọ́, OLúWA Ọlọ́run mi; gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìṣeun ìfẹ́ rẹ. Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ọwọ́ rẹ ni èyí wí pé ìwọ, OLúWA, ni ó ṣe é. Wọ́n ó máa gégùn ún, ṣùgbọ́n ìwọ máa súre; Nígbà tí wọn bá dìde kí ojú kí ó tì wọ́n, ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ yóò yọ̀ Jẹ́ kí a wọ àwọn ọ̀tá mi ní aṣọ ìtìjú kí á sì fi ìdàrúdàpọ̀ bọ̀ wọ́n lára bí ẹ̀wù. Pẹ̀lú ẹnu mi èmi yóò máa yin OLúWA gidigidi ní àárín ọ̀pọ̀ ènìyàn èmi yóò máa yìn ín Nítorí ó dúró ní apá ọ̀tún aláìní láti gbà á lọ́wọ́ àwọn tí ń dá ọkàn rẹ̀ lẹ́bi.