O. Daf 105:37-45
O. Daf 105:37-45 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si mu wọn jade, ti awọn ti fadaka ati wura: kò si si alailera kan ninu ẹ̀ya rẹ̀. Inu Egipti dùn nigbati nwọn lọ: nitoriti ẹ̀ru wọn bà wọn. O nà awọsanma kan fun ibori; ati iná lati fun wọn ni imọlẹ li oru. Nwọn bère o si mu ẹiyẹ aparo wá, o si fi onjẹ ọrun tẹ wọn lọrun. O là apata, omi si tú jade; odò nṣan nibi gbigbẹ. Nitoriti o ranti ileri rẹ̀ mimọ́, ati Abrahamu iranṣẹ rẹ̀. O si fi ayọ̀ mu awọn enia rẹ̀ jade, ati awọn ayanfẹ rẹ̀ pẹlu orin ayọ̀: O si fi ilẹ awọn keferi fun wọn: nwọn si jogun ère iṣẹ awọn enia na. Ki nwọn ki o le ma kiye si aṣẹ rẹ̀, ki nwọn ki o si ma pa ofin rẹ̀ mọ́. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.
O. Daf 105:37-45 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn náà, ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde, tàwọn ti fadaka ati wúrà, kò sì sí ẹnikẹ́ni ninu ẹ̀yà kankan tí ó ṣe àìlera. Inú àwọn ará Ijipti dùn nígbà tí wọ́n jáde, nítorí ẹ̀rù àwọn ọmọ Israẹli ń bà wọ́n. OLUWA ta ìkùukùu bò wọ́n, ó sì pèsè iná láti tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn lóru. Wọ́n bèèrè ẹran, ó fún wọn ní àparò, ó sì pèsè oúnjẹ àjẹtẹ́rùn fún wọn láti ọ̀run. Ó la àpáta, omi tú jáde, ó sì ṣàn ninu aṣálẹ̀ bí odò. Nítorí pé ó ranti ìlérí mímọ́ rẹ̀, ati Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀. Ó fi ayọ̀ kó àwọn eniyan rẹ̀ jáde, ó kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jáde pẹlu orin. Ó fún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, wọ́n sì jogún èrè iṣẹ́ àwọn eniyan náà. Kí wọ́n lè máa mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ, kí wọ́n sì máa pa òfin rẹ̀ mọ́.
O. Daf 105:37-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó mú Israẹli jáde ti òun ti fàdákà àti wúrà, nínú ẹ̀yà rẹ̀ kò sí aláìlera kan. Inú Ejibiti dùn nígbà tí wọn ń lọ, nítorí ẹ̀rù àwọn Israẹli ń bá wọ́n. Ó ta àwọsánmọ̀ fún ìbòrí, àti iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ lálẹ́ Wọn béèrè, ó sì mú ẹyẹ àparò wá, ó sì fi oúnjẹ ọ̀run tẹ́ wọn lọ́rùn. Ó sì la àpáta, ó sì mú omi jáde; gẹ́gẹ́ bí odò tí ń sàn níbi gbígbẹ. Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ rẹ̀ àti Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀. Ó sì fi ayọ̀ mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde pẹ̀lú ayọ̀ ní ó yan àyànfẹ́ rẹ̀ Ó fún wọn ní ilẹ̀ ìní náà, wọ́n sì jogún iṣẹ́ àwọn ènìyàn náà, Kí wọn kí ó lè máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́ kí wọn kí ó lè kíyèsi òfin rẹ̀.