O. Daf 105:21-45

O. Daf 105:21-45 Bibeli Mimọ (YBCV)

O fi jẹ oluwa ile rẹ̀, ati ijoye gbogbo ini rẹ̀. Lati ma ṣe akoso awọn ọmọ-alade rẹ̀ nipa ifẹ rẹ̀; ati lati ma kọ́ awọn igbimọ rẹ̀ li ọgbọ́n. Israeli si wá si Egipti pẹlu; Jakobu si ṣe atipo ni ilẹ Hamu. O si mu awọn enia rẹ̀ bi si i pipọ̀-pipọ̀; o si mu wọn lagbara jù awọn ọta wọn lọ. O yi wọn li aiya pada lati korira awọn enia rẹ̀, lati ṣe arekereke si awọn iranṣẹ rẹ̀. O rán Mose iranṣẹ rẹ̀; ati Aaroni, ẹniti o ti yàn. Nwọn fi ọ̀rọ àmi rẹ̀ hán ninu wọn, ati iṣẹ iyanu ni ilẹ Hamu. O rán òkunkun, o si mu u ṣú; nwọn kò si ṣaigbọran si ọ̀rọ rẹ̀. O sọ omi wọn di ẹ̀jẹ, o si pa ẹja wọn. Ilẹ wọn mu ọ̀pọlọ jade wá li ọ̀pọlọpọ, ni iyẹwu awọn ọba wọn. O sọ̀rọ, oniruru eṣinṣin si de, ati ina-aṣọ ni gbogbo agbegbe wọn. O fi yinyin fun wọn fun òjo, ati ọwọ iná ni ilẹ wọn. O si lu àjara wọn, ati igi ọ̀pọtọ wọn; o si dá igi àgbegbe wọn. O sọ̀rọ, eṣú si de ati kokoro li ainiye. Nwọn si jẹ gbogbo ewebẹ ilẹ wọn, nwọn si jẹ eso ilẹ wọn run. O kọlu gbogbo akọbi pẹlu ni ilẹ wọn, ãyo gbogbo ipa wọn. O si mu wọn jade, ti awọn ti fadaka ati wura: kò si si alailera kan ninu ẹ̀ya rẹ̀. Inu Egipti dùn nigbati nwọn lọ: nitoriti ẹ̀ru wọn bà wọn. O nà awọsanma kan fun ibori; ati iná lati fun wọn ni imọlẹ li oru. Nwọn bère o si mu ẹiyẹ aparo wá, o si fi onjẹ ọrun tẹ wọn lọrun. O là apata, omi si tú jade; odò nṣan nibi gbigbẹ. Nitoriti o ranti ileri rẹ̀ mimọ́, ati Abrahamu iranṣẹ rẹ̀. O si fi ayọ̀ mu awọn enia rẹ̀ jade, ati awọn ayanfẹ rẹ̀ pẹlu orin ayọ̀: O si fi ilẹ awọn keferi fun wọn: nwọn si jogun ère iṣẹ awọn enia na. Ki nwọn ki o le ma kiye si aṣẹ rẹ̀, ki nwọn ki o si ma pa ofin rẹ̀ mọ́. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

O. Daf 105:21-45 Yoruba Bible (YCE)

Ó fi jẹ aláṣẹ ilé rẹ̀, ati alákòóso gbogbo nǹkan ìní rẹ̀; láti máa ṣe olórí àwọn ìjòyè rẹ̀, kí ó sì máa kọ́ àwọn àgbà ìlú ní ìmọ̀. Lẹ́yìn náà, Israẹli dé sí Ijipti, Jakọbu ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Hamu. OLUWA mú kí àwọn eniyan rẹ̀ pọ̀ sí i, ó sì mú kí wọ́n lágbára ju àwọn ọ̀tá wọn lọ. Ó yí àwọn ará Ijipti lọ́kàn pada, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi kórìíra àwọn eniyan rẹ̀, tí wọ́n sì hùwà àrékérekè sí àwọn iranṣẹ rẹ̀. Ó rán Mose, iranṣẹ rẹ̀, ati Aaroni, ẹni tí ó yàn. Wọ́n ṣe iṣẹ́ àmì rẹ̀ ní ilẹ̀ náà, wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ní ilẹ̀ Hamu, Ọlọrun rán òkùnkùn, ilẹ̀ sì ṣú, ṣugbọn wọ́n ṣe oríkunkun sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀, ó sì mú kí ẹja wọn kú. Ọ̀pọ̀lọ́ ń tú jáde ní ilẹ̀ wọn, títí kan ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn. Ọlọrun sọ̀rọ̀, eṣinṣin sì rọ́ dé, iná aṣọ sì bo gbogbo ilẹ̀ wọn. Ó rọ̀jò yìnyín lé wọn lórí, mànàmáná sì ń kọ káàkiri ilẹ̀ wọn. Ó kọlu àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn, ó sì wó àwọn igi ilẹ̀ wọn. Ó sọ̀rọ̀, àwọn eṣú sì rọ́ dé, ati àwọn tata tí kò lóǹkà; wọ́n jẹ gbogbo ewé tí ó wà ní ilẹ̀ wọn, ati gbogbo èso ilẹ̀ náà. Ó kọlu gbogbo àkọ́bí ilẹ̀ wọn, àní, gbogbo àrẹ̀mọ ilẹ̀ wọn. Lẹ́yìn náà, ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde, tàwọn ti fadaka ati wúrà, kò sì sí ẹnikẹ́ni ninu ẹ̀yà kankan tí ó ṣe àìlera. Inú àwọn ará Ijipti dùn nígbà tí wọ́n jáde, nítorí ẹ̀rù àwọn ọmọ Israẹli ń bà wọ́n. OLUWA ta ìkùukùu bò wọ́n, ó sì pèsè iná láti tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn lóru. Wọ́n bèèrè ẹran, ó fún wọn ní àparò, ó sì pèsè oúnjẹ àjẹtẹ́rùn fún wọn láti ọ̀run. Ó la àpáta, omi tú jáde, ó sì ṣàn ninu aṣálẹ̀ bí odò. Nítorí pé ó ranti ìlérí mímọ́ rẹ̀, ati Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀. Ó fi ayọ̀ kó àwọn eniyan rẹ̀ jáde, ó kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jáde pẹlu orin. Ó fún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, wọ́n sì jogún èrè iṣẹ́ àwọn eniyan náà. Kí wọ́n lè máa mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ, kí wọ́n sì máa pa òfin rẹ̀ mọ́.

O. Daf 105:21-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó fi jẹ olúwa lórí ilẹ̀ rẹ̀ aláṣẹ lórí ohun gbogbo tí ó ní, Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa ṣe àkóso àwọn ọmọ-aládé kí ó sì kọ́ àwọn àgbàgbà rẹ̀ ní ọgbọ́n. Israẹli wá sí Ejibiti; Jakọbu sì ṣe àtìpó ní ilé Hamu. OLúWA, sì mú àwọn ọmọ rẹ̀ bí sí i ó sì mú wọn lágbára jù àwọn ọ̀tá wọn lọ Ó yí wọn lọ́kàn padà láti kórìíra àwọn ènìyàn láti ṣe àrékérekè sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ó rán Mose ìránṣẹ́ rẹ̀ àti Aaroni tí ó ti yàn Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrín wọn ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní Hamu. Ó rán òkùnkùn, o sì mú ilẹ̀ ṣú wọn kò sì sọ̀rọ̀-òdì sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀, ó pa ẹja wọn. Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀lọ́ jáde wá, èyí tí ó lọ sí ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn. Ó sọ̀rọ̀, onírúurú eṣinṣin sì dìde, ó sì hu kantíkantí ní ilẹ̀ wọn Ó sọ òjò di yìnyín, àti ọ̀wọ́-iná ní ilẹ̀ wọn; Ó lu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn ó sì dá igi orílẹ̀-èdè wọn. Ó sọ̀rọ̀, eṣú sì dé, àti kòkòrò ní àìníye, Wọn sì jẹ gbogbo ewé ilẹ̀ wọn, wọ́n sì jẹ èso ilẹ̀ wọn run Nígbà náà, ó kọlu gbogbo àwọn ilẹ̀ wọn, ààyò gbogbo ipá wọn. Ó mú Israẹli jáde ti òun ti fàdákà àti wúrà, nínú ẹ̀yà rẹ̀ kò sí aláìlera kan. Inú Ejibiti dùn nígbà tí wọn ń lọ, nítorí ẹ̀rù àwọn Israẹli ń bá wọ́n. Ó ta àwọsánmọ̀ fún ìbòrí, àti iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ lálẹ́ Wọn béèrè, ó sì mú ẹyẹ àparò wá, ó sì fi oúnjẹ ọ̀run tẹ́ wọn lọ́rùn. Ó sì la àpáta, ó sì mú omi jáde; gẹ́gẹ́ bí odò tí ń sàn níbi gbígbẹ. Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ rẹ̀ àti Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀. Ó sì fi ayọ̀ mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde pẹ̀lú ayọ̀ ní ó yan àyànfẹ́ rẹ̀ Ó fún wọn ní ilẹ̀ ìní náà, wọ́n sì jogún iṣẹ́ àwọn ènìyàn náà, Kí wọn kí ó lè máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́ kí wọn kí ó lè kíyèsi òfin rẹ̀.