O. Daf 104:1-17

O. Daf 104:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

FI ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi. Oluwa, Ọlọrun mi, iwọ tobi jọjọ: ọlá ati ọla-nla ni iwọ wọ̀ li aṣọ. Ẹniti o fi imọlẹ bora bi aṣọ: ẹniti o ta ọrun bi aṣọ tita: Ẹniti o fi omi ṣe ìti igi-àja iyẹwu rẹ̀: ẹniti o ṣe awọsanma ni kẹkẹ́ rẹ̀, ẹniti o nrìn lori apa iyẹ afẹfẹ: Ẹniti o ṣe ẹfufu ni onṣẹ rẹ̀; ati ọwọ-iná ni iranṣẹ rẹ̀. Ẹniti o fi aiye sọlẹ lori ipilẹ rẹ̀, ti kò le ṣipò pada lailai. Iwọ fi ibu omi bò o mọlẹ bi aṣọ: awọn omi duro lori òke nla. Nipa ibawi rẹ nwọn sá; nipa ohùn ãra rẹ, nwọn yara lọ. Awọn òke nla nru soke; awọn afonifoji nsọkalẹ si ibi ti iwọ ti fi lelẹ fun wọn. Iwọ ti pa àla kan ki nwọn ki o má le kọja rẹ̀; ki nwọn ki o má tun pada lati bò aiye mọlẹ. Iwọ ran orisun si afonifoji, ti nṣàn larin awọn òke. Awọn ni nfi omi mimu fun gbogbo ẹranko igbẹ: awọn kẹtẹkẹtẹ igbẹ npa ongbẹ wọn; Lẹba wọn li awọn ẹiyẹ oju-ọrun yio ni ile wọn, ti nkọrin lãrin ẹka igi. O mbomi rin awọn òke lati iyẹwu rẹ̀ wá: ère iṣẹ ọwọ rẹ tẹ́ aiye lọrun. O mu koriko dagba fun ẹran, ati ewebẹ fun ìlo enia: ki o le ma mu onjẹ jade lati ilẹ wá; Ati ọti-waini ti imu inu enia dùn, ati oróro ti imu oju rẹ̀ dan, ati onjẹ ti imu enia li aiya le. Igi Oluwa kún fun oje, igi kedari Lebanoni, ti o ti gbìn. Nibiti awọn ẹiyẹ ntẹ́ itẹ́ wọn: bi o ṣe ti àkọ ni, igi firi ni ile rẹ̀.

O. Daf 104:1-17 Yoruba Bible (YCE)

Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi, OLUWA, Ọlọrun mi, ó tóbi pupọ, ọlá ati iyì ni ó wọ̀ bí ẹ̀wù. Ó fi ìmọ́lẹ̀ bora bí aṣọ, ó ta ojú ọ̀run bí ẹni taṣọ. Ìwọ tí o tẹ́ àjà ibùgbé rẹ sórí omi, tí o fi ìkùukùu ṣe kẹ̀kẹ́ ogun rẹ, tí o sì ń lọ geere lórí afẹ́fẹ́. Ìwọ tí o fi ẹ̀fúùfù ṣe iranṣẹ, tí o sì fi iná ati ahọ́n iná ṣe òjíṣẹ́ rẹ. Ìwọ tí o gbé ayé kalẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ rẹ̀, tí kò sì le yẹ̀ laelae. O fi ibú omi bò ó bí aṣọ, omi sì borí àwọn òkè ńlá. Nígbà tí o bá wọn wí, wọ́n sá, nígbà tí o sán ààrá, wọ́n sá sẹ́yìn. Wọ́n ṣàn kọjá lórí òkè lọ sí inú àfonífojì, sí ibi tí o yàn fún wọn. O ti pa ààlà tí wọn kò gbọdọ̀ kọjá, kí wọn má baà tún bo ayé mọ́lẹ̀ mọ́. Ìwọ ni o mú kí àwọn orísun máa tú omi jáde ní àfonífojì; omi wọn sì ń ṣàn láàrin àwọn òkè. Ninu omi wọn ni gbogbo ẹranko tí ń mu, ibẹ̀ sì ni àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń rẹ òùngbẹ. Lẹ́bàá orísun wọnyi ni àwọn ẹyẹ ń gbé, wọ́n sì ń kọrin lórí igi. Láti ibùgbé rẹ lókè ni o tí ń bomi rin àwọn òkè ńlá. Ilẹ̀ sì mu àmutẹ́rùn nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Ó ń mú kí koríko dàgbà fún àwọn ẹran láti jẹ, ati ohun ọ̀gbìn fún ìlò eniyan, kí ó lè máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀; ati ọtí waini tí ń mú inú eniyan dùn, ati epo tí ń mú ojú eniyan dán, ati oúnjẹ tí ń fún ara lókun. Àwọn igi OLUWA ń mu omi ní àmutẹ́rùn, àní àwọn igi kedari Lẹbanoni tí ó gbìn. Lórí wọn ni àwọn ẹyẹ ń tẹ́ ìtẹ́ wọn sí, àkọ̀ sì ń kọ́ ilé rẹ̀ sórí igi firi.

O. Daf 104:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Yin OLúWA, ìwọ ọkàn mi. OLúWA Ọlọ́run mi, ìwọ tóbi jọjọ; ọlá àti ọláńlá ni ìwọ wọ̀ ní aṣọ. Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara rẹ gẹ́gẹ́ bí aṣọ; ó tẹ ọ̀run bí títẹ́ ẹní Ìwọ tí ó fi omi ṣe ìtì igi àjà ìyẹ̀wù rẹ. Ìwọ tí o ṣe àwọsánmọ̀ ní kẹ̀kẹ́ ogun rẹ ìwọ tí ó ń rìn lórí apá ìyẹ́ afẹ́fẹ́. Ó fi ẹ̀fúùfù ṣe àwọn ìránṣẹ́ rẹ, Ọ̀wọ́-iná ni àwọn olùránṣẹ́ rẹ. O fi ayé gúnlẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀; tí a kò le è mì láéláé. Ìwọ fi ibú omi bò ó mọ́lẹ̀ bí aṣọ; àwọn omi sì dúró lórí àwọn òkè ńlá. Ṣùgbọ́n nípa ìbáwí rẹ ni àwọn omi lọ, nípa ohùn àrá rẹ ni wọ́n sálọ; Wọ́n sàn kọjá lórí àwọn òkè, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀, sí ibi tí ìwọ ti yàn fún wọn. Ìwọ gbé òpin tí wọn kò lè kọjá rẹ̀ kálẹ̀; láéláé ni wọ́n kò ní lè bo ayé mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ìwọ mú kí ìsun da omi sí àwọn Àfonífojì; tí ó ń sàn láàrín àwọn òkè. Wọ́n fún gbogbo àwọn ẹranko igbó ní omi àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ń pa òǹgbẹ wọn. Àwọn ẹyẹ ojú òfúrufú tẹ́ ìtẹ́ wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi wọ́n ń kọrin láàrín àwọn ẹ̀ka. Ó bu omi rin àwọn òkè láti ìyẹ̀wù rẹ̀ wá; a tẹ́ ayé lọ́rùn nípa èso iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Ó mú kí koríko hù jáde fún àwọn ẹranko láti jẹ àti àwọn ewébẹ̀ fún ènìyàn láti lò kí ó lè mú oúnjẹ jáde láti ilẹ̀ wá: Ọtí wáìnì tí ó ń mú ọkàn ènìyàn yọ̀, òróró láti mú ojú rẹ̀ tan, àti àkàrà láti ra ọkàn rẹ̀ padà. Àwọn igi OLúWA ni a bu omi rin dáradára, kedari ti Lebanoni tí ó gbìn. Níbẹ̀ ní àwọn ẹyẹ ṣe ìtẹ́ wọn bí ó ṣe tí àkọ̀ ni, orí igi gíga ni ilé rẹ̀.