ORIN DAFIDI 104:1-17

ORIN DAFIDI 104:1-17 YCE

Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi, OLUWA, Ọlọrun mi, ó tóbi pupọ, ọlá ati iyì ni ó wọ̀ bí ẹ̀wù. Ó fi ìmọ́lẹ̀ bora bí aṣọ, ó ta ojú ọ̀run bí ẹni taṣọ. Ìwọ tí o tẹ́ àjà ibùgbé rẹ sórí omi, tí o fi ìkùukùu ṣe kẹ̀kẹ́ ogun rẹ, tí o sì ń lọ geere lórí afẹ́fẹ́. Ìwọ tí o fi ẹ̀fúùfù ṣe iranṣẹ, tí o sì fi iná ati ahọ́n iná ṣe òjíṣẹ́ rẹ. Ìwọ tí o gbé ayé kalẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ rẹ̀, tí kò sì le yẹ̀ laelae. O fi ibú omi bò ó bí aṣọ, omi sì borí àwọn òkè ńlá. Nígbà tí o bá wọn wí, wọ́n sá, nígbà tí o sán ààrá, wọ́n sá sẹ́yìn. Wọ́n ṣàn kọjá lórí òkè lọ sí inú àfonífojì, sí ibi tí o yàn fún wọn. O ti pa ààlà tí wọn kò gbọdọ̀ kọjá, kí wọn má baà tún bo ayé mọ́lẹ̀ mọ́. Ìwọ ni o mú kí àwọn orísun máa tú omi jáde ní àfonífojì; omi wọn sì ń ṣàn láàrin àwọn òkè. Ninu omi wọn ni gbogbo ẹranko tí ń mu, ibẹ̀ sì ni àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń rẹ òùngbẹ. Lẹ́bàá orísun wọnyi ni àwọn ẹyẹ ń gbé, wọ́n sì ń kọrin lórí igi. Láti ibùgbé rẹ lókè ni o tí ń bomi rin àwọn òkè ńlá. Ilẹ̀ sì mu àmutẹ́rùn nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Ó ń mú kí koríko dàgbà fún àwọn ẹran láti jẹ, ati ohun ọ̀gbìn fún ìlò eniyan, kí ó lè máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀; ati ọtí waini tí ń mú inú eniyan dùn, ati epo tí ń mú ojú eniyan dán, ati oúnjẹ tí ń fún ara lókun. Àwọn igi OLUWA ń mu omi ní àmutẹ́rùn, àní àwọn igi kedari Lẹbanoni tí ó gbìn. Lórí wọn ni àwọn ẹyẹ ń tẹ́ ìtẹ́ wọn sí, àkọ̀ sì ń kọ́ ilé rẹ̀ sórí igi firi.