Owe 4:7-13
Owe 4:7-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ipilẹṣẹ ọgbọ́n ni lati ni ọgbọ́n: ati pẹlu ini rẹ gbogbo, ni oye. Gbé e ga, on o si ma gbé ọ lekè: on o mu ọ wá si ọlá, nigbati iwọ ba gbá a mọra. On o fi ohun-ọṣọ́ daradara si ọ li ori: on o fi ọjá daradara fun ori rẹ. Gbọ́, iwọ ọmọ mi, ki o si gbà ọ̀rọ mi; ọdun ẹmi rẹ yio si di pipọ. Emi ti kọ́ ọ li ọ̀na ọgbọ́n; emi ti mu ọ tọ̀ ipa-ọ̀na titọ. Nigbati iwọ nrìn, ọ̀na rẹ kì yio há fun àye; nigbati iwọ nsare, iwọ kì yio fi ẹsẹ kọ. Di ẹkọ́ mu ṣinṣin, máṣe jẹ ki o lọ; pa a mọ́, nitori on li ẹmi rẹ.
Owe 4:7-13 Yoruba Bible (YCE)
Bí o bá fẹ́ gbọ́n, bẹ̀rẹ̀ sí kọ́gbọ́n, ohun yòówù tí o lè tún ní, ọgbọ́n ló jù, nítorí náà jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Gbé ọgbọ́n lárugẹ, yóo sì gbé ọ ga, yóo bu ọlá fún ọ, bí o bá gbà á mọ́ra. Yóo fi nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà bò ọ́ lórí, yóo sì dé ọ ní adé dáradára.” Gbọ́, ọmọ mi, gba ẹ̀kọ́ mi, kí ẹ̀mí rẹ lè gùn. Mo ti kọ́ ọ ní ọgbọ́n, mo sì ti fẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà òtítọ́. Nígbà tí o bá ń rìn, o kò ní rí ìdínà, nígbà tí o bá ń sáré, o kò ní fi ẹsẹ̀ kọ. Di ẹ̀kọ́ mú ṣinṣin, má jẹ́ kí ó bọ́, pa á mọ́, nítorí òun ni ìyè rẹ.
Owe 4:7-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọgbọ́n ni ó ga jù; nítorí náà gba ọgbọ́n. Bí ó tilẹ̀ ná gbogbo ohun tí o ní, gba òye Gbé e ga, yóò sì gbé ọ ga dìrọ̀ mọ́ ọn, yóò sì bu iyì fún ọ. Yóò fi òdòdó ọ̀ṣọ́ ẹwà sí orí rẹ yóò sì fi adé ẹlẹ́wà fún ọ.” Tẹ́tí, ọmọ mi, gba ohun tí mo sọ, Ọjọ́ ayé è rẹ yóò sì gùn. Mo tọ́ ọ ṣọ́nà ní ọ̀nà ti ọgbọ́n mo sì mú ọ lọ ní ọ̀nà ti tààrà. Nígbà tí o rìn, ìgbésẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́ nígbà tí o bá sáré, ìwọ kì yóò kọsẹ̀. Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ; tọ́jú u rẹ̀ dáradára nítorí òun ni ìyè rẹ.