Owe 4:20-27
Owe 4:20-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọmọ mi, fetisi ọ̀rọ mi; dẹti rẹ silẹ si ọ̀rọ mi. Máṣe jẹ ki nwọn ki o lọ kuro li oju rẹ; pa wọn mọ́ li ãrin aiya rẹ. Nitori ìye ni nwọn iṣe fun awọn ti o wá wọn ri, ati imularada si gbogbo ẹran-ara wọn. Jù gbogbo ohun ipamọ́, pa aiya rẹ mọ́; nitoripe lati inu rẹ̀ wá ni orisun ìye. Mu arekereke kuro lọdọ rẹ, ati ète ẹ̀tan jina rére kuro lọdọ rẹ. Jẹ ki oju rẹ ki o ma wò ọkankan gan, ki ipenpeju rẹ ki o ma wò gan niwaju rẹ. Ronu ipa-ọ̀na rẹ, gbogbo ọ̀na rẹ ni yio si fi idi mulẹ. Máṣe yà si apa ọtun tabi si apa òsi, ṣi ẹsẹ rẹ kuro ninu ibi.
Owe 4:20-27 Yoruba Bible (YCE)
Ọmọ mi, fetí sí ọ̀rọ̀ mi, tẹ́tí sílẹ̀ sí ohun tí mò ń sọ. Má jẹ́ kí wọn rú ọ lójú, fi wọ́n sọ́kàn. Nítorí pé ìyè ni wọ́n jẹ́ fún àwọn tí ó rí wọn, ati ìwòsàn fún gbogbo ẹran ara wọn. Ṣọ́ra pẹlu èrò ọkàn rẹ, nítorí èrò ọkàn ni orísun ìyè. Má lọ́wọ́ ninu ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ, sì jìnnà sí ọ̀rọ̀ àgàbàgebè. Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán, kí o sì kọjú sí ibi tí ò ń lọ tààrà. Kíyèsí ìrìn ẹsẹ̀ rẹ, gbogbo ọ̀nà rẹ yóo sì là. Má ṣe yà sí ọ̀tún tabi sí òsì, yipada kúrò ninu ibi.
Owe 4:20-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọmọ mi, tẹ́tí sí ohun tí mo sọ; fetísílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi Má ṣe jẹ́ kí wọ́n rá mọ́ ọ lójú pa wọ́n mọ́ sínú ọkàn rẹ; Nítorí ìyè ni wọ́n jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó rí wọn àti ìlera fún gbogbo ara ènìyàn Ju gbogbo nǹkan tókù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́ Nítorí òun ni orísun ìyè, Mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ; sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ jìnnà réré sí ẹnu rẹ. Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo iwájú, jẹ́ kí ìwo ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán iwájú rẹ sá á. Kíyèsi ìrìn ẹsẹ̀ rẹ sì rìn ní àwọn ọ̀nà tí ó dára nìkan Má ṣe yà sọ́tùn ún tàbí sósì; pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú ibi.