Owe 4:10-13
Owe 4:10-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gbọ́, iwọ ọmọ mi, ki o si gbà ọ̀rọ mi; ọdun ẹmi rẹ yio si di pipọ. Emi ti kọ́ ọ li ọ̀na ọgbọ́n; emi ti mu ọ tọ̀ ipa-ọ̀na titọ. Nigbati iwọ nrìn, ọ̀na rẹ kì yio há fun àye; nigbati iwọ nsare, iwọ kì yio fi ẹsẹ kọ. Di ẹkọ́ mu ṣinṣin, máṣe jẹ ki o lọ; pa a mọ́, nitori on li ẹmi rẹ.
Owe 4:10-13 Yoruba Bible (YCE)
Gbọ́, ọmọ mi, gba ẹ̀kọ́ mi, kí ẹ̀mí rẹ lè gùn. Mo ti kọ́ ọ ní ọgbọ́n, mo sì ti fẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà òtítọ́. Nígbà tí o bá ń rìn, o kò ní rí ìdínà, nígbà tí o bá ń sáré, o kò ní fi ẹsẹ̀ kọ. Di ẹ̀kọ́ mú ṣinṣin, má jẹ́ kí ó bọ́, pa á mọ́, nítorí òun ni ìyè rẹ.
Owe 4:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Tẹ́tí, ọmọ mi, gba ohun tí mo sọ, Ọjọ́ ayé è rẹ yóò sì gùn. Mo tọ́ ọ ṣọ́nà ní ọ̀nà ti ọgbọ́n mo sì mú ọ lọ ní ọ̀nà ti tààrà. Nígbà tí o rìn, ìgbésẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́ nígbà tí o bá sáré, ìwọ kì yóò kọsẹ̀. Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ; tọ́jú u rẹ̀ dáradára nítorí òun ni ìyè rẹ.