Owe 31:27-31
Owe 31:27-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
O fi oju silẹ wò ìwa awọn ara ile rẹ̀, kò si jẹ onjẹ imẹlẹ. Awọn ọmọ rẹ̀ dide, nwọn si pè e li alabukúnfun, ati bãle rẹ̀ pẹlu, on si fi iyìn fun u. Ọpọlọpọ awọn ọmọbinrin li o hùwa rere, ṣugbọn iwọ ta gbogbo wọn yọ. Oju daradara li ẹ̀tan, ẹwà si jasi asan: ṣugbọn obinrin ti o bẹ̀ru Oluwa, on ni ki a fi iyìn fun. Fi fun u ninu eso-iṣẹ ọwọ rẹ̀; jẹ ki iṣẹ ọwọ ara rẹ̀ ki o si yìn i li ẹnu-bodè.
Owe 31:27-31 Yoruba Bible (YCE)
A máa ṣe ìtọ́jú ìdílé rẹ̀ dáradára, kì í sì í hùwà ọ̀lẹ. Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa pè é ní ẹni ibukun, ọkọ rẹ̀ pẹlu a sì máa yìn ín pé, “Ọpọlọpọ obinrin ni wọ́n ti ṣe ribiribi, ṣugbọn ìwọ ta gbogbo wọn yọ.” Ẹ̀tàn ni ojú dáradára, asán sì ni ẹwà, obinrin tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni ó yẹ kí á yìn. Fún un ninu èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, jẹ́ kí wọn máa yìn ín lẹ́nu ibodè nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
Owe 31:27-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó ń bojútó gbogbo ètò ilé rẹ̀ kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́ Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde wọ́n sì pè é ní alábùkún ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ń gbóríyìn fún un “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ní ń ṣe nǹkan ọlọ́lá ṣùgbọ́n ìwọ ju gbogbo wọn lọ” Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asán nítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù OLúWA yẹ kí ó gba oríyìn Sì fún un ní èrè tí ó tọ́ sí i kí o sì jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ̀ fún un ní ìyìn ní ẹnu ibodè ìlú.