Owe 31:27-29
Owe 31:27-29 Yoruba Bible (YCE)
A máa ṣe ìtọ́jú ìdílé rẹ̀ dáradára, kì í sì í hùwà ọ̀lẹ. Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa pè é ní ẹni ibukun, ọkọ rẹ̀ pẹlu a sì máa yìn ín pé, “Ọpọlọpọ obinrin ni wọ́n ti ṣe ribiribi, ṣugbọn ìwọ ta gbogbo wọn yọ.”
Pín
Kà Owe 31Owe 31:27-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
O fi oju silẹ wò ìwa awọn ara ile rẹ̀, kò si jẹ onjẹ imẹlẹ. Awọn ọmọ rẹ̀ dide, nwọn si pè e li alabukúnfun, ati bãle rẹ̀ pẹlu, on si fi iyìn fun u. Ọpọlọpọ awọn ọmọbinrin li o hùwa rere, ṣugbọn iwọ ta gbogbo wọn yọ.
Pín
Kà Owe 31