Owe 31:13-15
Owe 31:13-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Obinrin na yio ma ṣafẹri kubusu ati ọ̀gbọ, o si fi ọwọ rẹ̀ ṣiṣẹ tinutinu. O dabi ọkọ̀ oniṣowo: o si mu onjẹ rẹ̀ lati ọ̀na jijin rére wá. On a si dide nigbati ilẹ kò ti imọ́, a si fi onjẹ fun enia ile rẹ̀, ati iṣẹ õjọ fun awọn ọmọbinrin rẹ̀.
Pín
Kà Owe 31Owe 31:13-15 Yoruba Bible (YCE)
A máa lọ wá irun aguntan ati òwú ìhunṣọ, a sì máa fi tayọ̀tayọ̀ hun aṣọ. Obinrin náà dàbí ọkọ̀ ojú omi oníṣòwò, tí ó ń mú oúnjẹ wálé láti ọ̀nà jíjìn réré. Ìdájí níí tií jí láti wá oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀, ati láti yan iṣẹ́ fún àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀.
Pín
Kà Owe 31Owe 31:13-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sa aṣọ irun àgùntàn olówùú àti ọ̀gbọ̀ Ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyárí. Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò; ó ń gbé oúnjẹ rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn; ó ṣe oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀ àti ìpín oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀.
Pín
Kà Owe 31