Owe 31:10-24

Owe 31:10-24 Yoruba Bible (YCE)

Ta ló lè rí iyawo tí ó ní ìwà rere fẹ́? Ó ṣọ̀wọ́n ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ. Ọkọ rẹ̀ yóo fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀lé e, kò sì ní ṣaláì ní ohunkohun. Rere ni obinrin náà máa ń ṣe fún un kò ní ṣe é níbi, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. A máa lọ wá irun aguntan ati òwú ìhunṣọ, a sì máa fi tayọ̀tayọ̀ hun aṣọ. Obinrin náà dàbí ọkọ̀ ojú omi oníṣòwò, tí ó ń mú oúnjẹ wálé láti ọ̀nà jíjìn réré. Ìdájí níí tií jí láti wá oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀, ati láti yan iṣẹ́ fún àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀. Bí ó bá rí ilẹ̀ oko, a yẹ̀ ẹ́ wò, a sì rà á, a sì fi èrè iṣẹ́ rẹ̀ gbin ọgbà àjàrà. A fi agbára fún ọ̀já mọ́nú, a sì tẹpá mọ́ṣẹ́. A máa mójútó ọjà tí ó ń tà, fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú lóru. Ó fi ọwọ́ lé kẹ̀kẹ́ òwú, ó sì ń ran òwú. Ó lawọ́ sí àwọn talaka, a sì máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́. Kì í bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀ nígbà òtútù, nítorí gbogbo wọn ni ó ti bá hun aṣọ tí ó móoru. A máa hun aṣọ ọlọ́nà a sì fi bo ibùsùn rẹ̀, òun náà á wọ aṣọ funfun dáradára ati ti elése àlùkò. Wọ́n dá ọkọ rẹ̀ mọ̀ lẹ́nu ibodè, nígbà tí ó bá jókòó pẹlu àwọn àgbààgbà ìlú. A máa hun aṣọ funfun, a sì tà wọ́n, a máa ta ọ̀já ìgbànú fún àwọn oníṣòwò.

Owe 31:10-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ta ni ó le rí aya oníwà rere? Ó níye lórí ju iyùn lọ Ọkọ rẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé púpọ̀ nínú rẹ̀ kò sì ṣí ìwà rere tí kò pé lọ́wọ́ rẹ̀. Ire ní ó ń ṣe fún un, kì í ṣe ibi ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Ó sa aṣọ irun àgùntàn olówùú àti ọ̀gbọ̀ Ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyárí. Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò; ó ń gbé oúnjẹ rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn; ó ṣe oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀ àti ìpín oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀. Ó kíyèsi oko kan, ó sì rà á; nínú ohun tí ó ń wọlé fún un ó gbin ọgbà àjàrà rẹ̀ Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tagbára tagbára apá rẹ̀ le koko fún iṣẹ́ Ó rí i pé òwò òun pé fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú ní òru Ní ọwọ́ rẹ̀, ó di kẹ̀kẹ́ òwú mú ó sì na ọwọ́ rẹ̀ di ìrànwú mú O la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn tálákà ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní. Nígbà tí òjò-dídì rọ̀, kò bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀ nítorí gbogbo wọn ni ó wọ aṣọ tí ó nípọn. Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀; ẹ̀wù dáradára àti elése àlùkò ni aṣọ rẹ̀ A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibodè ìlú níbi tí ó ń jókòó láàrín àwọn àgbàgbà ìlú Ó ń ṣe àwọn aṣọ dáradára ó sì ń tà wọ́n ó sì ń kó ọjà fún àwọn oníṣòwò