Owe 31:1-7
Owe 31:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ ti Lemueli ọba, ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ìyá rẹ̀ kọ́ ọ. “Gbọ́ ìwọ ọmọ mi, gbọ́ ìwọ ọmọ inú mi! Gbọ́ ìwọ ọmọ ẹ̀jẹ́ mi. Má ṣe lo agbára rẹ lórí obìnrin, okun rẹ lórí àwọn tí ó pa àwọn ọba run. “Kì í ṣe fún àwọn ọba, ìwọ Lemueli kì í ṣe fún ọba láti mu ọtí wáìnì kì í ṣe fún alákòóso láti máa wá ọtí líle Kí wọn má ba à mu ọtí yó kí wọn sì gbàgbé ohun tí òfin wí kí wọn sì fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ara ń ni dù wọ́n Fi ọtí líle fún àwọn tí ń ṣègbé wáìnì fún àwọn tí ó wà nínú ìrora; Jẹ́ kí wọn mu ọtí kí wọn sì gbàgbé òsì wọn kí wọn má sì rántí òsì wọn mọ́.
Owe 31:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀RỌ Lemueli, ọba, ọ̀rọ-ẹkọ́ ti ìya rẹ̀ kọ́ ọ. Kini, ọmọ mi? ki si ni, ọmọ inu mi? ati kini, ọmọ ẹ̀jẹ́ mi? Máṣe fi agbara rẹ fun awọn obinrin, tabi ìwa rẹ fun awọn obinrin ti mbà awọn ọba jẹ. Kì iṣe fun awọn ọba, Lemueli, kì iṣe fun awọn ọba lati mu ọti-waini; bẹ̃ni kì iṣe fun awọn ọmọ alade lati fẹ ọti lile: Ki nwọn ki o má ba mu, nwọn a si gbagbe ofin, nwọn a si yi idajọ awọn olupọnju. Fi ọti lile fun ẹniti o mura tan lati ṣegbe, ati ọti-waini fun awọn oninu bibajẹ. Jẹ ki o mu, ki o si gbagbe aini rẹ̀, ki o má si ranti òṣi rẹ̀ mọ́.
Owe 31:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Èyí ni ọ̀rọ̀ Lemueli, ọba Masa, tí ìyá rẹ̀ kọ́ ọ: Ìwọ ni ọmọ mi, ọmọ bíbí inú mi, ìwọ ni ọmọ tí mo jẹ́jẹ̀ẹ́ bí. Má ṣe lo agbára rẹ lórí obinrin, má fi ọ̀nà rẹ lé àwọn tí wọn ń pa ọba run lọ́wọ́. Gbọ́, ìwọ Lemueli, ọba kò gbọdọ̀ máa mu ọtí, àwọn aláṣẹ kò sì gbọdọ̀ máa wá ọtí líle. Kí wọn má baà mu ún tán, kí wọn gbàgbé òfin, kí wọn sì yí ìdájọ́ ẹni tí ojú ń pọ́n po. Fún ẹni tí ń ṣègbé lọ ní ọtí mu, fún àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ ní ọtí líle, jẹ́ kí wọn mu ún, kí wọn gbàgbé òṣì wọn, kí wọn má sì ranti ìnira wọn mọ́.