Owe 31:1-31

Owe 31:1-31 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ọ̀RỌ Lemueli, ọba, ọ̀rọ-ẹkọ́ ti ìya rẹ̀ kọ́ ọ. Kini, ọmọ mi? ki si ni, ọmọ inu mi? ati kini, ọmọ ẹ̀jẹ́ mi? Máṣe fi agbara rẹ fun awọn obinrin, tabi ìwa rẹ fun awọn obinrin ti mbà awọn ọba jẹ. Kì iṣe fun awọn ọba, Lemueli, kì iṣe fun awọn ọba lati mu ọti-waini; bẹ̃ni kì iṣe fun awọn ọmọ alade lati fẹ ọti lile: Ki nwọn ki o má ba mu, nwọn a si gbagbe ofin, nwọn a si yi idajọ awọn olupọnju. Fi ọti lile fun ẹniti o mura tan lati ṣegbe, ati ọti-waini fun awọn oninu bibajẹ. Jẹ ki o mu, ki o si gbagbe aini rẹ̀, ki o má si ranti òṣi rẹ̀ mọ́. Yà ẹnu rẹ fun ayadi, ninu ọ̀ran gbogbo ẹniti iṣe ọmọ iparun. Yà ẹnu rẹ, fi ododo ṣe idajọ, ki o si gbèja talaka ati alaini. Tani yio ri obinrin oniwà rere? nitoriti iye rẹ̀ kọja iyùn. Aiya ọkọ rẹ̀ gbẹkẹle e laibẹ̀ru, bẹ̃ni on kì yio ṣe alaini ère iṣẹ. Rere li obinrin na yio ma ṣe fun u, kì iṣe buburu li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo. Obinrin na yio ma ṣafẹri kubusu ati ọ̀gbọ, o si fi ọwọ rẹ̀ ṣiṣẹ tinutinu. O dabi ọkọ̀ oniṣowo: o si mu onjẹ rẹ̀ lati ọ̀na jijin rére wá. On a si dide nigbati ilẹ kò ti imọ́, a si fi onjẹ fun enia ile rẹ̀, ati iṣẹ õjọ fun awọn ọmọbinrin rẹ̀. O kiyesi oko, o si mu u: ère ọwọ rẹ̀ li o fi gbin ọgbà-ajara. O fi agbara gbá ẹ̀gbẹ rẹ̀ li ọjá, o si mu apa rẹ̀ mejeji le. O kiyesi i pe ọjà on dara: fitila rẹ̀ kò kú li oru. O fi ọwọ rẹ̀ le kẹkẹ́-owú, ọwọ rẹ̀ si di ìranwu mu. O nà ọwọ rẹ̀ si talaka; nitõtọ, ọwọ rẹ̀ si kàn alaini. On kò si bẹ̀ru òjo-didì fun awọn ara ile rẹ̀; nitoripe gbogbo awọn ara ile rẹ̀ li a wọ̀ li aṣọ iṣẹpo meji. On si wun aṣọ titẹ́ fun ara rẹ̀; ẹ̀wu daradara ati elese aluko li aṣọ rẹ̀. A mọ̀ ọkọ rẹ̀ li ẹnu-bode, nigbati o ba joko pẹlu awọn àgba ilẹ na. O da aṣọ ọ̀gbọ daradara, o si tà a, pẹlupẹlu o fi ọjá amure fun oniṣòwo tà. Agbara ati iyìn li aṣọ rẹ̀; on o si yọ̀ si ọjọ ti mbọ. O fi ọgbọ́n yà ẹnu rẹ̀; ati li ahọn rẹ̀ li ofin iṣeun. O fi oju silẹ wò ìwa awọn ara ile rẹ̀, kò si jẹ onjẹ imẹlẹ. Awọn ọmọ rẹ̀ dide, nwọn si pè e li alabukúnfun, ati bãle rẹ̀ pẹlu, on si fi iyìn fun u. Ọpọlọpọ awọn ọmọbinrin li o hùwa rere, ṣugbọn iwọ ta gbogbo wọn yọ. Oju daradara li ẹ̀tan, ẹwà si jasi asan: ṣugbọn obinrin ti o bẹ̀ru Oluwa, on ni ki a fi iyìn fun. Fi fun u ninu eso-iṣẹ ọwọ rẹ̀; jẹ ki iṣẹ ọwọ ara rẹ̀ ki o si yìn i li ẹnu-bodè.

Owe 31:1-31 Yoruba Bible (YCE)

Èyí ni ọ̀rọ̀ Lemueli, ọba Masa, tí ìyá rẹ̀ kọ́ ọ: Ìwọ ni ọmọ mi, ọmọ bíbí inú mi, ìwọ ni ọmọ tí mo jẹ́jẹ̀ẹ́ bí. Má ṣe lo agbára rẹ lórí obinrin, má fi ọ̀nà rẹ lé àwọn tí wọn ń pa ọba run lọ́wọ́. Gbọ́, ìwọ Lemueli, ọba kò gbọdọ̀ máa mu ọtí, àwọn aláṣẹ kò sì gbọdọ̀ máa wá ọtí líle. Kí wọn má baà mu ún tán, kí wọn gbàgbé òfin, kí wọn sì yí ìdájọ́ ẹni tí ojú ń pọ́n po. Fún ẹni tí ń ṣègbé lọ ní ọtí mu, fún àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ ní ọtí líle, jẹ́ kí wọn mu ún, kí wọn gbàgbé òṣì wọn, kí wọn má sì ranti ìnira wọn mọ́. Gba ẹjọ́ àwọn tí kò ní ẹnu ọ̀rọ̀ rò, ati ti àwọn tí a sọ di aláìní. Má dákẹ́, kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, bá talaka ati aláìní gba ẹ̀tọ́ wọn. Ta ló lè rí iyawo tí ó ní ìwà rere fẹ́? Ó ṣọ̀wọ́n ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ. Ọkọ rẹ̀ yóo fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀lé e, kò sì ní ṣaláì ní ohunkohun. Rere ni obinrin náà máa ń ṣe fún un kò ní ṣe é níbi, ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. A máa lọ wá irun aguntan ati òwú ìhunṣọ, a sì máa fi tayọ̀tayọ̀ hun aṣọ. Obinrin náà dàbí ọkọ̀ ojú omi oníṣòwò, tí ó ń mú oúnjẹ wálé láti ọ̀nà jíjìn réré. Ìdájí níí tií jí láti wá oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀, ati láti yan iṣẹ́ fún àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀. Bí ó bá rí ilẹ̀ oko, a yẹ̀ ẹ́ wò, a sì rà á, a sì fi èrè iṣẹ́ rẹ̀ gbin ọgbà àjàrà. A fi agbára fún ọ̀já mọ́nú, a sì tẹpá mọ́ṣẹ́. A máa mójútó ọjà tí ó ń tà, fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú lóru. Ó fi ọwọ́ lé kẹ̀kẹ́ òwú, ó sì ń ran òwú. Ó lawọ́ sí àwọn talaka, a sì máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́. Kì í bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀ nígbà òtútù, nítorí gbogbo wọn ni ó ti bá hun aṣọ tí ó móoru. A máa hun aṣọ ọlọ́nà a sì fi bo ibùsùn rẹ̀, òun náà á wọ aṣọ funfun dáradára ati ti elése àlùkò. Wọ́n dá ọkọ rẹ̀ mọ̀ lẹ́nu ibodè, nígbà tí ó bá jókòó pẹlu àwọn àgbààgbà ìlú. A máa hun aṣọ funfun, a sì tà wọ́n, a máa ta ọ̀já ìgbànú fún àwọn oníṣòwò. Agbára ati ọlá ni ó fi ń bora bí aṣọ, ó sì ní ìrètí ayọ̀ nípa ọjọ́ iwájú. Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ní ń jáde láti ẹnu rẹ̀, a sì máa kọ́ni ní ẹ̀kọ́ àánú. A máa ṣe ìtọ́jú ìdílé rẹ̀ dáradára, kì í sì í hùwà ọ̀lẹ. Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa pè é ní ẹni ibukun, ọkọ rẹ̀ pẹlu a sì máa yìn ín pé, “Ọpọlọpọ obinrin ni wọ́n ti ṣe ribiribi, ṣugbọn ìwọ ta gbogbo wọn yọ.” Ẹ̀tàn ni ojú dáradára, asán sì ni ẹwà, obinrin tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni ó yẹ kí á yìn. Fún un ninu èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, jẹ́ kí wọn máa yìn ín lẹ́nu ibodè nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

Owe 31:1-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ ti Lemueli ọba, ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ìyá rẹ̀ kọ́ ọ. “Gbọ́ ìwọ ọmọ mi, gbọ́ ìwọ ọmọ inú mi! Gbọ́ ìwọ ọmọ ẹ̀jẹ́ mi. Má ṣe lo agbára rẹ lórí obìnrin, okun rẹ lórí àwọn tí ó pa àwọn ọba run. “Kì í ṣe fún àwọn ọba, ìwọ Lemueli kì í ṣe fún ọba láti mu ọtí wáìnì kì í ṣe fún alákòóso láti máa wá ọtí líle Kí wọn má ba à mu ọtí yó kí wọn sì gbàgbé ohun tí òfin wí kí wọn sì fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ara ń ni dù wọ́n Fi ọtí líle fún àwọn tí ń ṣègbé wáìnì fún àwọn tí ó wà nínú ìrora; Jẹ́ kí wọn mu ọtí kí wọn sì gbàgbé òsì wọn kí wọn má sì rántí òsì wọn mọ́. “Sọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn tí kò le sọ̀rọ̀ fúnrawọn fún ẹ̀tọ́ àwọn ẹni tí ń parun Sọ̀rọ̀ kí o sì ṣe ìdájọ́ àìṣègbè jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà àti aláìní.” Ta ni ó le rí aya oníwà rere? Ó níye lórí ju iyùn lọ Ọkọ rẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé púpọ̀ nínú rẹ̀ kò sì ṣí ìwà rere tí kò pé lọ́wọ́ rẹ̀. Ire ní ó ń ṣe fún un, kì í ṣe ibi ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Ó sa aṣọ irun àgùntàn olówùú àti ọ̀gbọ̀ Ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyárí. Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò; ó ń gbé oúnjẹ rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn; ó ṣe oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀ àti ìpín oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀. Ó kíyèsi oko kan, ó sì rà á; nínú ohun tí ó ń wọlé fún un ó gbin ọgbà àjàrà rẹ̀ Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tagbára tagbára apá rẹ̀ le koko fún iṣẹ́ Ó rí i pé òwò òun pé fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú ní òru Ní ọwọ́ rẹ̀, ó di kẹ̀kẹ́ òwú mú ó sì na ọwọ́ rẹ̀ di ìrànwú mú O la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn tálákà ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní. Nígbà tí òjò-dídì rọ̀, kò bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀ nítorí gbogbo wọn ni ó wọ aṣọ tí ó nípọn. Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀; ẹ̀wù dáradára àti elése àlùkò ni aṣọ rẹ̀ A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibodè ìlú níbi tí ó ń jókòó láàrín àwọn àgbàgbà ìlú Ó ń ṣe àwọn aṣọ dáradára ó sì ń tà wọ́n ó sì ń kó ọjà fún àwọn oníṣòwò Agbára àti ọlá ni ó wò ọ́ láṣọ ó le fi ọjọ́ iwájú rẹ́rìn-ín. A sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n ìkọ́ni òtítọ́ sì ń bẹ létè e rẹ̀ Ó ń bojútó gbogbo ètò ilé rẹ̀ kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́ Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde wọ́n sì pè é ní alábùkún ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ń gbóríyìn fún un “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ní ń ṣe nǹkan ọlọ́lá ṣùgbọ́n ìwọ ju gbogbo wọn lọ” Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asán nítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù OLúWA yẹ kí ó gba oríyìn Sì fún un ní èrè tí ó tọ́ sí i kí o sì jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ̀ fún un ní ìyìn ní ẹnu ibodè ìlú.