Owe 3:27-32
Owe 3:27-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
Máṣe fawọ ire sẹhin kuro lọdọ ẹniti iṣe tirẹ̀, bi o ba wà li agbara ọwọ rẹ lati ṣe e. Máṣe wi fun ẹnikeji rẹ pe, Lọ, ki o si pada wá, bi o ba si di ọla, emi o fi fun ọ; nigbati iwọ ni i li ọwọ rẹ. Máṣe gbìro buburu si ọmọnikeji rẹ, bi on ti joko laibẹ̀ru lẹba ọdọ rẹ. Máṣe ba enia jà lainidi, bi on kò ba ṣe ọ ni ibi. Máṣe ilara aninilara, má si ṣe yàn ọkan ninu gbogbo ọ̀na rẹ̀. Nitoripe irira li ẹlẹgan loju Oluwa; ṣugbọn aṣiri rẹ̀ wà pẹlu awọn olododo.
Owe 3:27-32 Yoruba Bible (YCE)
Má ṣe fa ọwọ́ ire sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn tí ó tọ́ sí, nígbà tí ó bá wà ní ìkáwọ́ rẹ láti ṣe é. Má sọ fún aládùúgbò rẹ pé, “Máa lọ ná, n óo fún ọ tí o bá pada wá lọ́la,” nígbà tí ohun tí ó fẹ́ wà lọ́dọ̀ rẹ. Má ṣe gbèrò ibi sí aládùúgbò rẹ tí ń fi inú kan bá ọ gbé. Má ṣe bá ẹnikẹ́ni jà láìnídìí, nígbà tí kò ṣe ọ́ níbi. Má ṣe ìlara ẹni ibi má sì ṣe tẹ̀ sí èyíkéyìí ninu àwọn ọ̀nà rẹ̀. Nítorí OLUWA kórìíra alárèékérekè, ṣugbọn ó ní igbẹkẹle ninu àwọn tí wọn dúró ṣinṣin.
Owe 3:27-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Má ṣe fa ọwọ́ ìre sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ṣe tìrẹ, nígbà tí ó bá wà ní ìkápá rẹ láti ṣe ohun kan. Má ṣe wí fún aládùúgbò rẹ pé, “Padà wá nígbà tó ṣe díẹ̀; èmi yóò fi fún ọ ní ọ̀la,” nígbà tí o ní i pẹ̀lú rẹ nísinsin yìí. Má ṣe pète ohun búburú fún aládùúgbò rẹ, ti o gbé nítòsí rẹ, tí ó sì fọkàn tán ọ. Má ṣe fẹ̀sùn kan ènìyàn láìnídìí, nígbà tí kò ṣe ọ́ ní ibi kankan rárá. Má ṣe ṣe ìlara ènìyàn jàgídíjàgan tàbí kí o yàn láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Nítorí OLúWA kórìíra ènìyàn aláyídáyidà ṣùgbọ́n a máa fọkàn tán ẹni dídúró ṣinṣin.