Owe 3:19-24
Owe 3:19-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọgbọ́n li Oluwa fi fi idi aiye sọlẹ, oye li o si fi pese awọn ọrun. Nipa ìmọ rẹ̀ ni ibú ya soke, ti awọsanma si nsẹ̀ ìri rẹ̀ silẹ. Ọmọ mi, máṣe jẹ ki nwọn ki o lọ kuro li oju rẹ: pa ọgbọ́n ti o yè, ati imoye mọ́: Bẹ̃ni nwọn o ma jẹ ìye si ọkàn rẹ, ati ore-ọfẹ si ọrùn rẹ. Nigbana ni iwọ o ma rìn ọ̀na rẹ lailewu, iwọ ki yio si fi ẹsẹ̀ kọ. Nigbati iwọ dubulẹ, iwọ kì yio bẹ̀ru: nitõtọ, iwọ o dubulẹ, orun rẹ yio si dùn.
Owe 3:19-24 Yoruba Bible (YCE)
Ọgbọ́n ni OLUWA fi fi ìdí ayé sọlẹ̀, òye ni ó sì fi dá ọ̀run. Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni ibú fi ń tú omi jáde, tí ìrì fi ń sẹ̀ láti inú ìkùukùu. Ọmọ mi, di ọgbọ́n tí ó yè kooro ati làákàyè mú, má sì ṣe jẹ́ kí wọn bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ, wọ́n yóo jẹ́ ìyè fún ẹ̀mí rẹ, ati ohun ọ̀ṣọ́ ní ọrùn rẹ. Nígbà náà ni o óo máa rìn láìléwu ati láìkọsẹ̀. Bí o bá jókòó, ẹ̀rù kò ní bà ọ́, bí o bá sùn, oorun yóo máa dùn mọ́ ọ.
Owe 3:19-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nípa ọgbọ́n, OLúWA fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn; Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní yà, àwọsánmọ̀ sì ń sẹ ìrì. Ọmọ mi, pa ọgbọ́n tí ó yè kooro àti ìmòye mọ́, má jẹ́ kí wọn lọ kúrò ní ibi tí ojú rẹ ti le tó wọn. Wọn yóò jẹ́ ìyè fún ọ, àti ẹ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ ní àìléwu, ìwọ kì yóò sì kọsẹ̀; Nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò bẹ̀rù, nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, oorun rẹ yóò jẹ́ oorun ayọ̀.