Owe 3:1-35

Owe 3:1-35 Bibeli Mimọ (YBCV)

ỌMỌ mi, máṣe gbagbe ofin mi; si jẹ ki aiya rẹ ki o pa ofin mi mọ́. Nitori ọjọ gigùn, ati ẹmi gigùn, ati alafia ni nwọn o fi kún u fun ọ. Máṣe jẹ ki ãnu ati otitọ ki o fi ọ silẹ: so wọn mọ ọrùn rẹ; kọ wọn si walã aiya rẹ: Bẹ̃ni iwọ o ri ojurere, ati ọ̀na rere loju Ọlọrun ati enia. Fi gbogbo aiya rẹ gbẹkẹle Oluwa; ma si ṣe tẹ̀ si ìmọ ara rẹ. Mọ̀ ọ ni gbogbo ọ̀na rẹ: on o si ma tọ́ ipa-ọna rẹ. Máṣe ọlọgbọ́n li oju ara rẹ; bẹ̀ru Oluwa, ki o si kuro ninu ibi. On o ṣe ilera si idodo rẹ, ati itura si egungun rẹ. Fi ohun-ini rẹ bọ̀wọ fun Oluwa, ati lati inu gbogbo akọbi ibisi-oko rẹ: Bẹ̃ni aká rẹ yio kún fun ọ̀pọlọpọ, ati agbá rẹ yio si kún fun ọti-waini titun. Ọmọ mi, máṣe kọ̀ ibawi Oluwa; bẹ̃ni ki agara itọ́ni rẹ̀ ki o máṣe dá ọ: Nitoripe ẹniti Oluwa fẹ on ni itọ́, gẹgẹ bi baba ti itọ́ ọmọ ti inu rẹ̀ dùn si. Ibukún ni fun ọkunrin na ti o wá ọgbọ́n ri, ati ọkunrin na ti o gbà oye. Nitori ti òwo rẹ̀ ju òwo fadaka lọ, ère rẹ̀ si jù ti wura daradara lọ. O ṣe iyebiye jù iyùn lọ: ati ohun gbogbo ti iwọ le fẹ, kò si eyi ti a le fi we e. Ọjọ gigùn mbẹ li ọwọ ọtún rẹ̀; ati li ọwọ osì rẹ̀, ọrọ̀ ati ọlá. Ọ̀na rẹ̀, ọ̀na didùn ni, ati gbogbo ipa-ọ̀na rẹ̀, alafia. Igi ìye ni iṣe fun gbogbo awọn ti o dì i mu: ibukún si ni fun ẹniti o dì i mu ṣinṣin. Ọgbọ́n li Oluwa fi fi idi aiye sọlẹ, oye li o si fi pese awọn ọrun. Nipa ìmọ rẹ̀ ni ibú ya soke, ti awọsanma si nsẹ̀ ìri rẹ̀ silẹ. Ọmọ mi, máṣe jẹ ki nwọn ki o lọ kuro li oju rẹ: pa ọgbọ́n ti o yè, ati imoye mọ́: Bẹ̃ni nwọn o ma jẹ ìye si ọkàn rẹ, ati ore-ọfẹ si ọrùn rẹ. Nigbana ni iwọ o ma rìn ọ̀na rẹ lailewu, iwọ ki yio si fi ẹsẹ̀ kọ. Nigbati iwọ dubulẹ, iwọ kì yio bẹ̀ru: nitõtọ, iwọ o dubulẹ, orun rẹ yio si dùn. Máṣe fòya ẹ̀ru ojijì, tabi idahoro awọn enia buburu, nigbati o de. Nitori Oluwa ni yio ṣe igbẹkẹle rẹ, yio si pa ẹsẹ rẹ mọ́ kuro ninu atimu. Máṣe fawọ ire sẹhin kuro lọdọ ẹniti iṣe tirẹ̀, bi o ba wà li agbara ọwọ rẹ lati ṣe e. Máṣe wi fun ẹnikeji rẹ pe, Lọ, ki o si pada wá, bi o ba si di ọla, emi o fi fun ọ; nigbati iwọ ni i li ọwọ rẹ. Máṣe gbìro buburu si ọmọnikeji rẹ, bi on ti joko laibẹ̀ru lẹba ọdọ rẹ. Máṣe ba enia jà lainidi, bi on kò ba ṣe ọ ni ibi. Máṣe ilara aninilara, má si ṣe yàn ọkan ninu gbogbo ọ̀na rẹ̀. Nitoripe irira li ẹlẹgan loju Oluwa; ṣugbọn aṣiri rẹ̀ wà pẹlu awọn olododo. Egún Oluwa mbẹ ni ile awọn enia buburu: ṣugbọn o bukún ibujoko awọn olõtọ. Nitõtọ o ṣe ẹ̀ya si awọn ẹlẹya: ṣugbọn o fi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ. Awọn ọlọgbọ́n ni yio jogun ogo: ṣugbọn awọn aṣiwere ni yio ru itiju wọn.

Owe 3:1-35 Yoruba Bible (YCE)

Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ọ, sì pa òfin mi mọ́ lọ́kàn rẹ, nítorí wọn óo fún ọ ní ẹ̀mí gígùn ati ọpọlọpọ alaafia. Má jẹ́ kí ìwà ìṣòótọ́ kí ó fi ọ́ sílẹ̀, so àánú ati òtítọ́ mọ́ ọrùn rẹ, kọ wọ́n sí oókan àyà rẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, o óo rí ojurere ati iyì lọ́dọ̀ Ọlọrun ati eniyan. Fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, má sì tẹ̀lé ìmọ̀ ara rẹ. Mọ Ọlọrun ní gbogbo ọ̀nà rẹ, yóo sì mú kí ọ̀nà rẹ tọ́. Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ, bẹ̀rù OLUWA, kí o sì yẹra fún ibi. Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóo jẹ́ ìwòsàn fún ara rẹ, ati ìtura fún egungun rẹ. Fi ohun ìní rẹ bọ̀wọ̀ fún OLUWA pẹlu gbogbo àkọ́so oko rẹ. Nígbà náà ni àká rẹ yóo kún bámúbámú, ìkòkò waini rẹ yóo sì kún àkúnya. Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìtọ́ni OLUWA, má sì ṣe jẹ́ kí ìbáwí rẹ̀ sú ọ. Nítorí ẹni tí OLUWA bá fẹ́ níí báwí gẹ́gẹ́ bí baba tí máa ń bá ọmọ rẹ̀ tí ó bá fẹ́ràn wí. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó wá ọgbọ́n rí, ati ẹni tí ó ní òye. Nítorí èrè rẹ̀ dára ju èrè orí fadaka ati ti wúrà lọ. Ọgbọ́n níye lórí ó ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ, kò sí ohun tí o lè fi wé e, ninu gbogbo ohun tí ọkàn rẹ lè fẹ́. Ẹ̀mí gígùn wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ọrọ̀ ati iyì sì wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀. Ọ̀nà rẹ̀ tura pupọ, alaafia sì ni gbogbo ọ̀nà rẹ̀. Igi ìyè ni fún àwọn tí wọ́n rọ̀ mọ́ ọn, ayọ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí wọ́n dì í mú ṣinṣin. Ọgbọ́n ni OLUWA fi fi ìdí ayé sọlẹ̀, òye ni ó sì fi dá ọ̀run. Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni ibú fi ń tú omi jáde, tí ìrì fi ń sẹ̀ láti inú ìkùukùu. Ọmọ mi, di ọgbọ́n tí ó yè kooro ati làákàyè mú, má sì ṣe jẹ́ kí wọn bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ, wọ́n yóo jẹ́ ìyè fún ẹ̀mí rẹ, ati ohun ọ̀ṣọ́ ní ọrùn rẹ. Nígbà náà ni o óo máa rìn láìléwu ati láìkọsẹ̀. Bí o bá jókòó, ẹ̀rù kò ní bà ọ́, bí o bá sùn, oorun yóo máa dùn mọ́ ọ. Má bẹ̀rù àjálù òjijì, tabi ìparun àwọn ẹni ibi, nígbà tí ó bá dé bá ọ, nítorí pé, OLUWA ni igbẹkẹle rẹ, kò sì ní jẹ́ kí o ti ẹsẹ̀ bọ tàkúté. Má ṣe fa ọwọ́ ire sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn tí ó tọ́ sí, nígbà tí ó bá wà ní ìkáwọ́ rẹ láti ṣe é. Má sọ fún aládùúgbò rẹ pé, “Máa lọ ná, n óo fún ọ tí o bá pada wá lọ́la,” nígbà tí ohun tí ó fẹ́ wà lọ́dọ̀ rẹ. Má ṣe gbèrò ibi sí aládùúgbò rẹ tí ń fi inú kan bá ọ gbé. Má ṣe bá ẹnikẹ́ni jà láìnídìí, nígbà tí kò ṣe ọ́ níbi. Má ṣe ìlara ẹni ibi má sì ṣe tẹ̀ sí èyíkéyìí ninu àwọn ọ̀nà rẹ̀. Nítorí OLUWA kórìíra alárèékérekè, ṣugbọn ó ní igbẹkẹle ninu àwọn tí wọn dúró ṣinṣin. Ègún OLUWA wà lórí ìdílé ẹni ibi, ṣugbọn a máa bukun ibùgbé àwọn olódodo. A máa fi àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn ṣe ẹlẹ́yà, ṣugbọn a máa fi ojurere wo àwọn onírẹ̀lẹ̀. Ọlọ́gbọ́n yóo jogún iyì, ṣugbọn ojú yóo ti òmùgọ̀.

Owe 3:1-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ mi. Ṣùgbọ́n pa òfin mi mọ́ sí ọkàn rẹ. Nítorí ọjọ́ gígùn, ẹ̀mí gígùn, àti àlàáfíà, ni wọn yóò fi kùn un fún ọ. Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláé so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ, kọ wọ́n sí wàláà àyà rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojúrere àti orúkọ rere ní ojú Ọlọ́run àti lójú ènìyàn. Gbẹ́kẹ̀lé OLúWA pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ má ṣe sinmi lé òye ara à rẹ; Mọ̀ ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹ òun yóò sì máa tọ́ ipa ọ̀nà rẹ. Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ bẹ̀rù OLúWA kí o sì kórìíra ibi. Èyí yóò mú ìlera fún ara rẹ àti okun fún àwọn egungun rẹ. Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún OLúWA, pẹ̀lú àkọ́so oko rẹ Nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnya àgbá rẹ yóò kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún wáìnì tuntun. Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí OLúWA má sì ṣe bínú nígbà tí ó bá ń bá ọ wí, Nítorí OLúWA a máa bá àwọn tí ó fẹ́ràn wí bí baba ti í bá ọmọ tí ó bá nínú dídùn sí wí. Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀, ẹni tí ó tún ní òye sí i Nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ ó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ. Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ; kò sí ohunkóhun tí a lè fiwé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́. Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; ní ọwọ́ òsì rẹ sì ni ọrọ̀ àti ọlá. Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ ọ̀nà ìtura, òpópónà rẹ sì jẹ́ ti àlàáfíà. Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbà á; àwọn tí ó bá sì dìímú yóò rí ìbùkún gbà. Nípa ọgbọ́n, OLúWA fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn; Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní yà, àwọsánmọ̀ sì ń sẹ ìrì. Ọmọ mi, pa ọgbọ́n tí ó yè kooro àti ìmòye mọ́, má jẹ́ kí wọn lọ kúrò ní ibi tí ojú rẹ ti le tó wọn. Wọn yóò jẹ́ ìyè fún ọ, àti ẹ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ ní àìléwu, ìwọ kì yóò sì kọsẹ̀; Nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò bẹ̀rù, nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, oorun rẹ yóò jẹ́ oorun ayọ̀. Má ṣe bẹ̀rù ìdààmú òjijì, tàbí ti ìparun tí ó ń dé bá àwọn ènìyàn búburú. Nítorí OLúWA yóò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ, kì yóò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ bọ́ sínú pàkúté. Má ṣe fa ọwọ́ ìre sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ṣe tìrẹ, nígbà tí ó bá wà ní ìkápá rẹ láti ṣe ohun kan. Má ṣe wí fún aládùúgbò rẹ pé, “Padà wá nígbà tó ṣe díẹ̀; èmi yóò fi fún ọ ní ọ̀la,” nígbà tí o ní i pẹ̀lú rẹ nísinsin yìí. Má ṣe pète ohun búburú fún aládùúgbò rẹ, ti o gbé nítòsí rẹ, tí ó sì fọkàn tán ọ. Má ṣe fẹ̀sùn kan ènìyàn láìnídìí, nígbà tí kò ṣe ọ́ ní ibi kankan rárá. Má ṣe ṣe ìlara ènìyàn jàgídíjàgan tàbí kí o yàn láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Nítorí OLúWA kórìíra ènìyàn aláyídáyidà ṣùgbọ́n a máa fọkàn tán ẹni dídúró ṣinṣin. Ègún OLúWA ń bẹ lórí ilé ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n ó bùkún fún ilé olódodo. Ó fi àwọn ẹlẹ́yà ṣe yẹ̀yẹ́, ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún onírẹ̀lẹ̀. Ọlọ́gbọ́n jogún iyì, ṣùgbọ́n àwọn aṣiwèrè ni yóò ru ìtìjú wọn.