Owe 29:1-27

Owe 29:1-27 Bibeli Mimọ (YBCV)

ẸNITI a ba mbawi ti o wà ọrùn kì, yio parun lojiji, laisi atunṣe. Nigbati awọn olododo wà lori oyè, awọn enia a yọ̀; ṣugbọn nigbati enia buburu ba gori oyè, awọn enia a kẹdùn. Ẹnikẹni ti o fẹ ọgbọ́n, a mu baba rẹ̀ yọ̀: ṣugbọn ẹniti o mba panṣaga kẹgbẹ, a ba ọrọ̀ rẹ̀ jẹ. Nipa idajọ li ọba imu ilẹ tòro: ṣugbọn ẹniti o ba ngbà ọrẹ a bì i ṣubu. Ẹniti o npọ́n ẹnikeji rẹ̀ ta àwọn silẹ fun ẹsẹ rẹ̀. Ninu irekọja enia ibi, ikẹkùn mbẹ: ṣugbọn olododo a ma kọrin, a si ma yọ̀. Olododo a ma rò ọ̀ran talaka: ṣugbọn enia buburu kò ṣú si i lati rò o. Awọn ẹlẹgàn enia da irukerudo si ilu: ṣugbọn awọn ọlọgbọ́n enia ṣẹ́ri ibinu kuro. Ọlọgbọ́n enia ti mba aṣiwère enia ja, bi inu li o mbi, bi ẹrín li o nrín, isimi kò si. Awọn enia-ẹ̀jẹ korira aduro-ṣinṣin: ṣugbọn awọn olododo a ma ṣe afẹri ọkàn rẹ̀. Aṣiwère a sọ gbogbo inu rẹ̀ jade: ṣugbọn ọlọgbọ́n a pa a mọ́ di ìgba ikẹhin. Bi ijoye ba feti si ọ̀rọ-eke, gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ni yio buru. Talaka ati aninilara enia pejọ pọ̀: Oluwa li o ntan imọlẹ si oju awọn mejeji. Ọba ti o fi otitọ ṣe idajọ talaka, itẹ́ rẹ̀ yio fi idi mulẹ lailai. Paṣan ati ibawi funni li ọgbọ́n: ṣugbọn ọmọ ti a ba jọwọ rẹ̀ fun ara rẹ̀, a dojuti iya rẹ̀. Nigbati awọn enia buburu ba npọ̀ si i, irekọja a pọ̀ si i: ṣugbọn awọn olododo yio ri iṣubu wọn. Tọ́ ọmọ rẹ, yio si fun ọ ni isimi; yio si fi inu-didùn si ọ li ọkàn. Nibiti iran-woli kò si, enia a yapa, ṣugbọn ibukún ni fun ẹniti o pa ofin mọ́. A kì ifi ọ̀rọ kilọ fun ọmọ-ọdọ; bi o tilẹ ye e kì yio dahùn. Iwọ ri enia ti o yara li ọ̀rọ rẹ̀? ireti mbẹ fun aṣiwère jù fun u lọ. Ẹniti o ba fi ikẹ́ tọ́ ọmọ-ọdọ rẹ̀ lati igba-ewe wá, oun ni yio jogún rẹ̀. Ẹni ibinu ru ìja soke, ati ẹni ikannu pọ̀ ni irekọja. Igberaga enia ni yio rẹ̀ ẹ silẹ: ṣugbọn onirẹlẹ ọkàn ni yio gbà ọlá. Ẹniti o kó ẹgbẹ ole korira ọkàn ara rẹ̀: o ngbọ́ ifiré, kò si fihan. Ibẹ̀ru enia ni imu ikẹkùn wá: ṣugbọn ẹnikẹni ti o gbẹkẹ rẹ̀ le Oluwa li a o gbe leke. Ọpọlọpọ enia li o nwá ojurere ijoye: ṣugbọn idajọ enia li o nti ọdọ Oluwa wá. Alaiṣõtọ enia, irira ni si awọn olododo: ẹniti o si ṣe aduro-ṣinṣin li ọ̀na, irira ni si enia buburu.

Owe 29:1-27 Yoruba Bible (YCE)

Ẹni tí à ń báwí tí ó ń ṣoríkunkun, yóo parun lójijì láìsí àtúnṣe. Nígbà tí olódodo bá di eniyan pataki, àwọn eniyan a máa yọ̀, ṣugbọn nígbà tí eniyan burúkú bá wà lórí oyè, àwọn eniyan a máa kérora. Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa mú inú baba rẹ̀ dùn, ṣugbọn ẹni tí ń tẹ̀lé aṣẹ́wó kiri, ń fi ọrọ̀ ara rẹ̀ ṣòfò. Ọba tí ó bá ń ṣe ìdájọ́ òdodo, a máa fìdí orílẹ̀-èdè múlẹ̀, ṣugbọn ọba onírìbá a máa dojú orílẹ̀-èdè bolẹ̀. Ẹni tí ó bá ń pọ́n aládùúgbò rẹ̀, ń dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ̀. Eniyan burúkú bọ́ sinu àwọ̀n ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn olódodo lè kọrin, ó sì lè máa yọ̀. Olódodo a máa bìkítà fún ẹ̀tọ́ àwọn talaka, ṣugbọn àwọn eniyan burúkú kò ní òye irú rẹ̀. Àwọn ẹlẹ́gàn a máa dá rúkèrúdò sílẹ̀ láàrin ìlú, ṣugbọn àwọn ọlọ́gbọ́n a máa paná ibinu. Nígbà tí ọlọ́gbọ́n bá pe òmùgọ̀ lẹ́jọ́, ẹ̀rín ni òmùgọ̀ yóo máa fi rín, yóo máa pariwo, kò sì ní dákẹ́. Àwọn apànìyàn kórìíra olóòótọ́ inú, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á. Òmùgọ̀ eniyan a máa bínú, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa mú sùúrù. Bí aláṣẹ bá ń fetí sí irọ́, gbogbo àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ yóo di eniyankeniyan. Ohun tí ó sọ talaka ati aninilára di ọ̀kan náà ni pé, OLUWA ló fún àwọn mejeeji ní ojú láti ríran. Ọba tí ó dájọ́ ẹ̀tọ́ fún talaka, ní a óo fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ títí. Pàṣán ati ìbáwí a máa kọ́ ọmọ lọ́gbọ́n, ọmọ tí a bá fi sílẹ̀ yóo dójúti ìyá rẹ̀. Nígbà tí eniyan burúkú bá wà lórí oyè, ẹ̀ṣẹ̀ a máa pọ̀ síi, ṣugbọn lójú olódodo ni wọn yóo ti ṣubú. Tọ́ ọmọ rẹ, yóo sì fún ọ ní ìsinmi, yóo sì mú inú rẹ dùn. Orílẹ̀-èdè tí kò bá ní ìfihàn láti ọ̀run, yóo dàrú, ṣugbọn ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń pa òfin mọ́. Ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan kò tó láti fi bá ẹrú wí, ó lè fi etí gbọ́ ṣugbọn kí ó má ṣe ohunkohun. Òmùgọ̀ nírètí ju ẹni tí yóo sọ̀rọ̀ sọ̀rọ̀, tí kò lè kó ara rẹ̀ ní ìjánu lọ. Bí eniyan bá kẹ́ ẹrú ní àkẹ́jù, yóo ya ìyàkuyà níkẹyìn. Ẹni tí inú ń bí a máa dá rògbòdìyàn sílẹ̀, onínúfùfù a sì máa ṣe ọpọlọpọ àṣìṣe. Ìgbéraga eniyan a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, ṣugbọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn yóo gba iyì. Ẹni tí ó ṣe alábàápín pẹlu olè kò fẹ́ràn ẹ̀mí ara rẹ̀, ó gbọ́ ọ̀rọ̀ ègún, ṣugbọn kò sọ fún ẹnikẹ́ni. Ìbẹ̀rù eniyan a máa di ìdẹkùn fún eniyan, ṣugbọn ẹni bá gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo wà láìléwu. Ọ̀pọ̀ ń wá ojurere olórí, ṣugbọn OLUWA níí dáni ní ẹjọ́ òdodo. Olódodo a máa kórìíra alaiṣootọ, eniyan burúkú a sì kórìíra eniyan rere.

Owe 29:1-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹni tí ó sì ń ṣorí kunkun lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbáwí yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe. Nígbà tí olódodo bá ń gbilẹ̀, àwọn ènìyàn a yọ̀ nígbà tí ènìyàn búburú ń ṣàkóso, àwọn ènìyàn ń kórìíra. Ènìyàn tí ó fẹ́ràn ọgbọ́n mú kí baba rẹ̀ láyọ̀ ṣùgbọ́n ẹni ti ń bá panṣágà kẹ́gbẹ́ ba ọrọ̀ ọ rẹ̀ jẹ́. Nípa ìdájọ́ òdodo ni ọba fi í mú ìlú tòrò nini, ṣùgbọ́n èyí tí ń ṣe ojúkòkòrò àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fà á lulẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tan aládùúgbò rẹ̀ ó ń dẹ àwọ̀n de ẹsẹ̀ ẹ rẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn ibi ni ó jẹ́ ìdẹ̀kùn rẹ̀ ṣùgbọ́n olódodo le è kọrin kí ó sì máa yọ̀. Olódodo ń máa ro ọ̀rọ̀ tálákà, ṣùgbọ́n ènìyàn búburú kò sú sí i láti rò ó. Àwọn ẹlẹ́yà a máa ru ìlú sókè, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn máa ń mú ìbínú kúrò. Bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn bá lọ sí ilé ẹjọ́ pẹ̀lú aláìgbọ́n aláìgbọ́n a máa bínú a sì máa jà, kò sì ní sí àlàáfíà. Àwọn tí ó ń tàjẹ̀ sílẹ̀ kò rí ẹni dídúró ṣinṣin wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa olódodo. Aláìgbọ́n ènìyàn fi gbogbo ẹnu rẹ̀ bínú ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa kó ìbínú rẹ̀ ní ìjánu. Bí olórí bá fetí sí irọ́, gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ a di ènìyàn búburú lójú rẹ̀. Tálákà ènìyàn àti aninilára jọ ní àbùdá yìí, OLúWA jẹ́ kí ojú àwọn méjèèjì máa ríran. Bí ọba kan bá ń ṣe ìdájọ́ tálákà pẹ̀lú òtítọ́ ìtẹ́ ìjọba rẹ yóò fìdímúlẹ̀ nígbà gbogbo. Ọ̀pá ìbániwí ń fún ni ní ọgbọ́n ṣùgbọ́n ọmọ tí a fi sílẹ̀ fúnrarẹ̀ a dójútì ìyá rẹ̀. Nígbà tí ènìyàn búburú ń gbilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀ṣẹ̀ ń gbilẹ̀ ṣùgbọ́n olódodo yóò rí ìṣubú wọn. Bá ọmọ rẹ wí, yóò sì fún ọ ní àlàáfíà yóò sì mú inú dídùn wá sí inú ọkàn rẹ. Níbi tí kò ti sí ìfihàn, àwọn ènìyàn a gbé ìgbé ayé àìbìkítà, ṣùgbọ́n ìbùkún ní fún àwọn tí ń pa òfin mọ́. A kò le fi ọ̀rọ̀ lásán kìlọ̀ fún ìránṣẹ́ bí ó tilẹ̀ yé e, kò ní kọbi ara sí i. Ǹjẹ́ ó rí ènìyàn tí ń kánjú sọ̀rọ̀? Ìrètí wà fún aláìgbọ́n jù ú lọ. Bí ènìyàn kan bá kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lákẹ̀ẹ́jù láti kékeré yóò mú ìbànújẹ́ wá ní ìgbẹ̀yìn. Oníbìínú ènìyàn a ru ìjà sókè, onínú-fùfù ènìyàn a sì máa dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀. Ìgbéraga ènìyàn a máa sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀ ṣùgbọ́n onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn a máa gba iyì kún iyì. Ẹni tí ó ń kó ẹgbẹ́, olè kórìíra ọkàn ara rẹ̀, ó ń gbọ́ èpè olóhun kò sì le è fọhùn. Ìbẹ̀rù ènìyàn kan yóò sì di ìdẹ̀kùn ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bẹ̀rù OLúWA wà láìléwu. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ń wá ojúrere alákòóso, ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ OLúWA ni ènìyàn tí ń gba ìdájọ́ òdodo. Olódodo kórìíra àwọn aláìṣòótọ́: ènìyàn búburú kórìíra olódodo.