Owe 26:23-25
Owe 26:23-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ete jijoni, ati aiya buburu, dabi idarọ fadaka ti a fi bò ìkoko. Ẹniti o ba korira, ti o fi ète rẹ̀ ṣe agabagebe, yio si pa ẹ̀tan mọ́ ninu rẹ̀. Nigbati o ba sọ̀rọ daradara, máṣe gbà a gbọ́: nitoripe irira meje li o wà li aiya rẹ̀
Owe 26:23-25 Yoruba Bible (YCE)
Ètè mímú ati inú burúkú, dàbí ìdàrọ́ fadaka tí a yọ́ bo ìkòkò amọ̀. Ẹni tí ó bá kórìíra eniyan, lè máa fi ọ̀rọ̀ ẹnu bo ara rẹ̀ láṣìírí, ṣugbọn ẹ̀tàn wà ninu rẹ̀, bí ó bá sọ̀rọ̀ dáradára, má ṣe gbà á gbọ́, nítorí ọpọlọpọ ìríra kún inú ọkàn rẹ̀.
Owe 26:23-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ètè jíjóni, àti àyà búburú, dà bí ìdàrọ́ fàdákà tí a fi bo ìkòkò. Ènìyàn tí ó kórìíra máa ń fi ètè rẹ̀ bo àṣírí ara rẹ̀ ṣùgbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ ni ìtànjẹ wà. Bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ fanimọ́ra, má ṣe gbà á gbọ́ nítorí ìríra méje ni ó kún inú ọkàn rẹ̀.