Owe 22:1-16
Owe 22:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
ORUKỌ rere sàn ni yiyàn jù ọrọ̀ pupọ lọ, ati ojurere ifẹ jù fadaka ati wura lọ. Ọlọrọ̀ ati talaka pejọ pọ̀: Oluwa li ẹlẹda gbogbo wọn. Ọlọgbọ́n enia ti ri ibi tẹlẹ, o si pa ara rẹ̀ mọ́: ṣugbọn awọn òpe a kọja, a si jẹ wọn niya. Ere irẹlẹ ati ibẹ̀ru Oluwa li ọrọ̀, ọlá, ati ìye. Ẹgún ati idẹkùn mbẹ li ọ̀na alayidayida: ẹniti o ba pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yio jina si wọn. Tọ́ ọmọde li ọ̀na ti yio tọ̀: nigbati o si dàgba tan, kì yio kuro ninu rẹ̀. Ọlọrọ̀ ṣe olori olupọnju, ajigbese si ṣe iranṣẹ fun onigbese. Ẹniti o ba funrugbin ẹ̀ṣẹ, yio ri asan ka: ọpá ibinu rẹ̀ si ti mura tan. Ẹniti o li oju ãnu li a o bukun fun; nitoriti o fi ninu onjẹ rẹ̀ fun olupọnju. Ṣá ẹlẹgàn tì sode, ìja yio si jade; nitõtọ ìja ati ẹ̀gan yio dẹkun. Ẹniti o fẹ ìwa funfun aiya, ti o fẹ ọ̀rọ pẹlẹ, ọba yio ṣe ọrẹ́ rẹ̀. Oju Oluwa pa ìmọ mọ́, o si yi ọ̀rọ olurekọja po. Ọlẹ wipe, kiniun mbẹ lode, a o pa mi ni igboro. Ẹnu awọn ajeji obinrin, iho jijin ni; ẹniti a mbinu si lati ọdọ Oluwa wá ni yio ṣubu sinu rẹ̀. Li aiya ọmọde ni wère dì si; ṣugbọn paṣan itọ́ni ni yio le e jina kuro lọdọ rẹ̀. Ẹniti o nni talaka lara lati mu ọrọ̀ pọ̀, ti o si nta ọlọrọ̀ lọrẹ, yio di alaini bi o ti wu ki o ṣe.

Owe 22:1-16 Yoruba Bible (YCE)
Orúkọ rere dára láti yàn ju ọrọ̀ pupọ lọ, kí á rí ojurere sì dára ju kí á ní fadaka ati wúrà lọ. Ọlọ́rọ̀ ati talaka pàdé, OLUWA ló dá ekinni-keji wọn. Ọlọ́gbọ́n rí ibi, ó farapamọ́, ṣugbọn òpè ń bá tirẹ̀ lọ láìbìkítà, ó sì kó sinu ìyọnu. Èrè ìrẹ̀lẹ̀ ati ìbẹ̀rù OLUWA ni ọrọ̀, ọlá, ati ìyè. Ẹ̀gún ati tàkúté ń bẹ lọ́nà àwọn ẹlẹ́tàn, ẹni tí ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóo jìnnà sí wọn. Tọ́ ọmọ rẹ sí ọ̀nà tí ó yẹ kí ó máa rìn, bí ó bá dàgbà tán, kò ní kúrò ninu rẹ̀. Ọlọ́rọ̀ máa ń jọba lé talaka lórí, ẹni tí ó lọ yá owó sì ni ẹrú ẹni tí ó yá a lówó. Ẹni tí ó bá gbin aiṣododo yóo kórè ìdààmú, pàṣán ibinu rẹ̀ yóo sì parun. Olójú àánú yóo rí ibukun gbà, nítorí pé ó ń fún talaka ninu oúnjẹ rẹ̀. Lé pẹ̀gànpẹ̀gàn síta, ìjà yóo rọlẹ̀, asọ̀ ati èébú yóo sì dópin. Ẹni tí ó fẹ́ ọkàn mímọ́, tí ó sì ní ọ̀rọ̀ rere lẹ́nu yóo bá ọba ṣọ̀rẹ́. Ojú OLUWA ń ṣọ́ ìmọ̀ tòótọ́, ṣugbọn a máa yí ọ̀rọ̀ àwọn alaigbagbọ po. Ọ̀lẹ a máa sọ pé, “Kinniun wà níta! Yóo pa mí jẹ lójú pópó!” Ẹnu alágbèrè obinrin dàbí kòtò ńlá, ẹni tí OLUWA bá ń bínú sí níí já sinu rẹ̀. Ìwà agídí dì sí ọkàn ọmọde, ṣugbọn pàṣán ìbáwí níí lé e jáde. Ẹni tí ó ni talaka lára kí ó lè ní ohun ìní pupọ, tabi tí ó ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ yóo pada di talaka.
Owe 22:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Yíyan orúkọ rere sàn ju púpọ̀ ọrọ̀ lọ, àti ojúrere dára ju fàdákà àti wúrà lọ. Ọlọ́rọ̀ àti tálákà péjọpọ̀: OLúWA ni ẹlẹ́dàá gbogbo wọn. Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀, ó ṣé ara rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n àwọn òpè tẹ̀síwájú, a sì jẹ wọ́n ní yà. Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù OLúWA ni ọrọ̀ ọlá, àti ìyè. Ègún àti ìdẹ̀kùn ń bẹ ní ọ̀nà aláyídáyidà: ẹni tí ó bá pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóò jìnnà sí wọn. Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀: nígbà tí ó bá dàgbà, kì yóò kúrò nínú rẹ̀. Ọlọ́rọ̀ ṣe olórí olùpọ́njú, ajigbèsè sì ṣe ìránṣẹ́ fún ẹni tí a jẹ ní gbèsè. Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn ẹ̀ṣẹ̀, yóò ká asán: ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò kùnà. Ẹni tí ó ní ojú àánú ni a ó bùkún fún; nítorí tí ó fi nínú oúnjẹ rẹ̀ fún olùpọ́njú. Lé ẹlẹ́gàn sí ìta, ìjà yóò sì jáde; nítòótọ́ ìjà àti ẹ̀gàn yóò dẹ́kun. Ẹni tí ó fẹ́ ìwà funfun ti àyà, tí ó sì ń sọ̀rọ̀ iyì jáde, ọba yóò ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ojú OLúWA pa ìmọ̀ mọ́, ó sì yí ọ̀rọ̀ olùrékọjá pò. Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún ń bẹ lóde! Yóò pa mí ní ìgboro!” Ẹnu àwọn àjèjì obìnrin, ihò jíjìn ni; ẹni tí a ń bínú sí láti ọ̀dọ̀ OLúWA wá ni yóò ṣubú sínú rẹ̀. Àyà ọmọdé ni ìwà wèrè dì sí; ṣùgbọ́n pàṣán ìtọ́ni ni yóò lé e jìnnà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Ẹni tó ń ni tálákà lára láti ní ọrọ̀, tí ó sì ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ, yóò di aláìní bí ó ti wù kó rí. Gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn.