Owe 22:1-16

Owe 22:1-16 YBCV

ORUKỌ rere sàn ni yiyàn jù ọrọ̀ pupọ lọ, ati ojurere ifẹ jù fadaka ati wura lọ. Ọlọrọ̀ ati talaka pejọ pọ̀: Oluwa li ẹlẹda gbogbo wọn. Ọlọgbọ́n enia ti ri ibi tẹlẹ, o si pa ara rẹ̀ mọ́: ṣugbọn awọn òpe a kọja, a si jẹ wọn niya. Ere irẹlẹ ati ibẹ̀ru Oluwa li ọrọ̀, ọlá, ati ìye. Ẹgún ati idẹkùn mbẹ li ọ̀na alayidayida: ẹniti o ba pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yio jina si wọn. Tọ́ ọmọde li ọ̀na ti yio tọ̀: nigbati o si dàgba tan, kì yio kuro ninu rẹ̀. Ọlọrọ̀ ṣe olori olupọnju, ajigbese si ṣe iranṣẹ fun onigbese. Ẹniti o ba funrugbin ẹ̀ṣẹ, yio ri asan ka: ọpá ibinu rẹ̀ si ti mura tan. Ẹniti o li oju ãnu li a o bukun fun; nitoriti o fi ninu onjẹ rẹ̀ fun olupọnju. Ṣá ẹlẹgàn tì sode, ìja yio si jade; nitõtọ ìja ati ẹ̀gan yio dẹkun. Ẹniti o fẹ ìwa funfun aiya, ti o fẹ ọ̀rọ pẹlẹ, ọba yio ṣe ọrẹ́ rẹ̀. Oju Oluwa pa ìmọ mọ́, o si yi ọ̀rọ olurekọja po. Ọlẹ wipe, kiniun mbẹ lode, a o pa mi ni igboro. Ẹnu awọn ajeji obinrin, iho jijin ni; ẹniti a mbinu si lati ọdọ Oluwa wá ni yio ṣubu sinu rẹ̀. Li aiya ọmọde ni wère dì si; ṣugbọn paṣan itọ́ni ni yio le e jina kuro lọdọ rẹ̀. Ẹniti o nni talaka lara lati mu ọrọ̀ pọ̀, ti o si nta ọlọrọ̀ lọrẹ, yio di alaini bi o ti wu ki o ṣe.