Owe 16:18-20
Owe 16:18-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Igberaga ni iṣaju iparun, agidi ọkàn ni iṣaju iṣubu. O san lati ṣe onirẹlẹ ọkàn pẹlu awọn talaka, jù ati ba awọn agberaga pin ikógun. Ẹniti o fi oye ṣe ọ̀ran yio ri ire; ẹniti o si gbẹkẹ le Oluwa, ibukún ni fun u.
Pín
Kà Owe 16Owe 16:18-20 Yoruba Bible (YCE)
Ìgbéraga ní ń ṣáájú ìparun, agídí ní ń ṣáájú ìṣubú. Ó sàn kí eniyan jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ pẹlu àwọn talaka ju kí ó bá agbéraga pín ìkógun lọ. Yóo dára fún ẹni tí ó bá ń gbọ́ràn, ẹni tí ó bá sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo ní ayọ̀.
Pín
Kà Owe 16