Owe 16:1-3
Owe 16:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
IMURA aiya, ti enia ni, ṣugbọn lati ọdọ Oluwa ni idadùn ahọn. Gbogbo ọ̀na enia li o mọ́ li oju ara rẹ̀; ṣugbọn Oluwa li o ndiwọ̀n ọkàn. Kó iṣẹ rẹ le Oluwa lọwọ, a o si fi idi ìro-inu rẹ kalẹ.
Pín
Kà Owe 16Owe 16:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Èrò ọkàn ni ti eniyan ṣugbọn OLUWA ló ni ìdáhùn. Gbogbo ọ̀nà eniyan ni ó mọ́ lójú ara rẹ̀, ṣugbọn OLUWA ló rí ọkàn. Fi gbogbo àdáwọ́lé rẹ lé OLUWA lọ́wọ́, èrò ọkàn rẹ yóo sì yọrí sí rere.
Pín
Kà Owe 16Owe 16:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ti ènìyàn ni ìgbèrò inú ọkàn ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ OLúWA ni ìdáhùn ahọ́n ti ń wá. Gbogbo ọ̀nà ènìyàn ni ó dàbí i pé ó dára lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n OLúWA ló ń díwọ̀n èrò inú ọkàn. Fi ohun gbogbo tí o bá ṣe lé OLúWA lọ́wọ́ Èrò rẹ yóò sì ṣe é ṣe.
Pín
Kà Owe 16