Owe 15:20-33

Owe 15:20-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọlọ́gbọ́n ọmọ mú inú baba rẹ̀ dùn, ṣùgbọ́n aṣiwèrè ènìyàn kẹ́gàn ìyá rẹ̀. Inú ènìyàn aláìlóye a máa dùn sí ìwà òmùgọ̀; ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa rin ọ̀nà tààrà. Ìgbèrò a máa dasán níbi tí kò sí ìmọ̀ràn; ṣùgbọ́n a máa yege níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn wà. Inú ènìyàn a máa dùn nígbà tí ó bá fèsì tó yẹ ọ̀rọ̀ tí ó bá sì wá lásìkò tó yẹ dára púpọ̀! Ọ̀nà ìyè ń lọ sókè fún ọlọ́gbọ́n láti sọ kí ó má bá à sọ̀kalẹ̀ lọ sí ipò òkú. OLúWA fa ilé onígbèéraga ya lulẹ̀, ṣùgbọ́n ó pa ààlà opó onírẹ̀lẹ̀ mọ́ láìyẹ̀. OLúWA kórìíra èrò ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n mímọ́ ni ọ̀rọ̀ ẹni pípé. Ọ̀kánjúwà ènìyàn mú ìyọnu bá ilé rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóò yè. Ọkàn olódodo ń wọn ìdáhùn wò ṣùgbọ́n ẹnu ènìyàn búburú ń tú ibi jáde. OLúWA jìnnà sí ènìyàn búburú ṣùgbọ́n ó ń gbọ́ àdúrà olódodo. Ojú tó túká máa ń mú ayọ̀ wá fún ọkàn, ìròyìn ayọ̀ sì ń mú ìlera wá sínú egungun. Ẹni tí ó fetí sí ìbáwí tí ń fún ni ní ìyè, yóò wà ní àpéjọpọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n. Ẹni tí ó kọ̀ ìbáwí kẹ́gàn ara rẹ̀, Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí yóò ní ìmọ̀ sí i. Ìbẹ̀rù OLúWA kọ́ ènìyàn ní ọgbọ́n, Ìrẹ̀lẹ̀ sì ni ó máa ń ṣáájú ọlá.