ÌWÉ ÒWE 15:20-33

ÌWÉ ÒWE 15:20-33 YCE

Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa mú inú baba rẹ̀ dùn, ṣugbọn òmùgọ̀ ọmọ níí kẹ́gàn ìyá rẹ̀. Ayọ̀ ni ìwà òmùgọ̀ jẹ́ fún aláìgbọ́n, ṣugbọn ẹni tí ó ní òye a máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Àìsí ìmọ̀ràn a máa mú kí ètò dàrú, ṣugbọn ọpọlọpọ ìmọ̀ràn a máa mú kí ó yọrí sí rere. Ìdáhùn kíkún a máa fúnni láyọ̀, kí ọ̀rọ̀ bọ́ sí àsìkò dára lọpọlọpọ! Ọ̀nà ọlọ́gbọ́n lọ tààrà sinu ìyè, kí ó má baà bọ́ sinu isà òkú. OLUWA a máa wó ilé agbéraga, ṣugbọn ó ṣe àmójútó ààlà opó. Ohun ìríra ni èrò ọkàn ẹni ibi lójú OLUWA, ṣugbọn ọrọ̀ àwọn ẹni mímọ́ jẹ́ dídùn inú rẹ̀. Àwọn tí ń ṣojúkòkòrò èrè àìtọ́ ń kó ìyọnu bá ilé wọn, ṣugbọn àwọn tí wọn kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóo yè. Olódodo a máa ronú kí ó tó fèsì ọ̀rọ̀, ṣugbọn ọ̀rọ̀ burúkú níí máa jáde lẹ́nu àwọn eniyan burúkú. OLUWA jìnnà sí eniyan burúkú, ṣugbọn a máa gbọ́ adura olódodo. Ọ̀yàyà a máa mú inú dùn, ìròyìn ayọ̀ a sì máa mú ara yá. Ẹni tó gbọ́ ìbáwí rere yóo wà láàrin àwọn ọlọ́gbọ́n. Ẹni tí kò náání ìbáwí tàbùkù ara rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó bá gba ìmọ̀ràn yóo ní òye. Ìbẹ̀rù OLUWA níí kọ́ni lọ́gbọ́n, ìwà ìrẹ̀lẹ̀ níí ṣáájú iyì.