Owe 12:21-23
Owe 12:21-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kò si ibi kan ti yio ba olododo; ṣugbọn awọn enia buburu ni yio kún fun ibi. Irira loju Oluwa li ahọn eke; ṣugbọn awọn ti nṣe rere ni didùn-inu rẹ̀. Ọlọgbọ́n enia pa ìmọ mọ; ṣugbọn aiya awọn aṣiwere nkede iwere.
Pín
Kà Owe 12Owe 12:21-23 Yoruba Bible (YCE)
Nǹkan burúkú kò ní ṣẹlẹ̀ sí olódodo, ṣugbọn eniyan burúkú yóo kún fún ìyọnu. OLUWA kórìíra ẹni tí ń parọ́, ṣugbọn inú rẹ̀ dùn sí olóòótọ́. Ọlọ́gbọ́n a máa fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́, ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa kéde agọ̀ wọn.
Pín
Kà Owe 12Owe 12:21-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ibi kì í ṣubú lu olódodo rárá ṣùgbọ́n ènìyàn búburú gba ìpín ìyọnu tiwọn. OLúWA kórìíra ètè tí ń parọ́ ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn olóòtítọ́. Ènìyàn olóye fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú ń gbé ìwà òmùgọ̀ jáde.
Pín
Kà Owe 12