Owe 12:11-23

Owe 12:11-23 Yoruba Bible (YCE)

Ẹni tí ó bá ń dáko yóo ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń lo àkókò rẹ̀ lórí ohun tí kò lérè, kò lọ́gbọ́n lórí. Ilé ìṣọ́ àwọn eniyan burúkú yóo di òkítì àlàpà, ṣugbọn gbòǹgbò eniyan rere a máa fìdí múlẹ̀ sí i. Ọ̀rọ̀ ẹnu eniyan burúkú a máa mú un bíi tàkúté, ṣugbọn olódodo a máa bọ́ ninu ìyọnu. Ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa mú ìtẹ́lọ́rùn bá a, a sì máa jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Ọ̀nà òmùgọ̀ níí dára lójú tirẹ̀, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa fetí sí ìmọ̀ràn. Bí inú bá ń bí òmùgọ̀, kíá ni gbogbo eniyan yóo mọ̀, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n kìí ka ọ̀rọ̀ àbùkù sí. Ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ a máa jẹ́rìí òdodo, ṣugbọn irọ́ ni ẹlẹ́rìí èké máa ń pa. Ẹni tí í bá máa ń sọ̀rọ̀ jàbùjàbù láìronú, ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí kí á fi idà gún eniyan, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹni wo ọgbẹ́ sàn. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ yóo máa wà títí ayé ṣugbọn irọ́, fún ìgbà díẹ̀ ni. Ẹ̀tàn ń bẹ lọ́kàn àwọn tí ń pète ibi, ṣugbọn àwọn tí ń gbèrò rere ní ayọ̀. Nǹkan burúkú kò ní ṣẹlẹ̀ sí olódodo, ṣugbọn eniyan burúkú yóo kún fún ìyọnu. OLUWA kórìíra ẹni tí ń parọ́, ṣugbọn inú rẹ̀ dùn sí olóòótọ́. Ọlọ́gbọ́n a máa fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́, ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa kéde agọ̀ wọn.

Owe 12:11-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹni tí ó bá dá oko yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ, ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa òjìji lásán làsàn kò gbọ́n. Ènìyàn búburú ń fẹ́ ìkógun àwọn ènìyàn ìkà ṣùgbọ́n gbòǹgbò olódodo ń gbilẹ̀. A mú ènìyàn búburú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n olódodo bọ́ kúrò lọ́wọ́ ìdààmú. Láti inú èso rẹ̀, ènìyàn kún fún onírúurú ohun rere bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ti ń pín in lérè dájúdájú. Ọ̀nà aláìgbọ́n dára lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa gba ìmọ̀ràn. Aláìgbọ́n ènìyàn fi ìbínú un rẹ̀ hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ṣùgbọ́n olóye ènìyàn fojú fo ìyànjẹ. Ẹni tí ó jẹ́ ajẹ́rìí òtítọ́ jẹ́rìí ohun tí ojú rẹ̀ rí ṣùgbọ́n ajẹ́rìí èké máa ń parọ́. Ọ̀rọ̀ tí a kò rò jinlẹ̀ máa ń gún ni bí ọ̀kọ̀ ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń mú ìwòsàn wá. Ètè tí ń ṣọ òtítọ́ yóò wà láéláé ṣùgbọ́n ahọ́n tí ń parọ́ kì í tọ́jọ́. Ẹ̀tàn wà nínú ọkàn àwọn tí ń pète búburú ṣùgbọ́n ayọ̀ wà fún àwọn tí ń mú kí àlàáfíà gbilẹ̀. Ibi kì í ṣubú lu olódodo rárá ṣùgbọ́n ènìyàn búburú gba ìpín ìyọnu tiwọn. OLúWA kórìíra ètè tí ń parọ́ ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn olóòtítọ́. Ènìyàn olóye fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú ń gbé ìwà òmùgọ̀ jáde.