Owe 12:1-25

Owe 12:1-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ ẹ̀kọ́ fẹ́ ìmọ̀, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kórìíra ìbáwí jẹ́ aláìgbọ́n. Ènìyàn rere gba ojúrere lọ́dọ̀ OLúWA ṣùgbọ́n ènìyàn ètè búburú ni yóò dá lẹ́bi. A kò lè fi ẹsẹ̀ ènìyàn múlẹ̀ nípa ìwà búburú ṣùgbọ́n a kò le è fa olódodo tu. Aya oníwà rere ni adé ọkọ rẹ̀ ṣùgbọ́n aya adójútini dàbí inú egungun rẹ̀ jẹrà. Èrò àwọn olódodo tọ́, ṣùgbọ́n ìgbìmọ̀ ènìyàn búburú jẹ́ ẹ̀tàn. Ọ̀rọ̀ ènìyàn búburú lúgọ de ẹ̀jẹ̀ ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ àwọn Olódodo gbà wọ́n là. A ṣí àwọn ènìyàn búburú ní ìdí, wọn kò sì sí mọ́; ṣùgbọ́n ilé olódodo dúró ṣinṣin. A ń yín ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ọgbọ́n rẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ọlọ́pọlọ wúruwùru ni a kẹ́gàn. Ó sàn kí a má jẹ́ ènìyàn pàtàkì kí a sì ní ìránṣẹ́ ju kí a díbọ́n pé a jẹ́ ẹni pàtàkì láìní oúnjẹ. Olódodo ènìyàn ń ṣe aájò ohun tí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ nílò, ṣùgbọ́n ìyọ́nú àwọn ènìyàn búburú, ìkà ni. Ẹni tí ó bá dá oko yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ, ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa òjìji lásán làsàn kò gbọ́n. Ènìyàn búburú ń fẹ́ ìkógun àwọn ènìyàn ìkà ṣùgbọ́n gbòǹgbò olódodo ń gbilẹ̀. A mú ènìyàn búburú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n olódodo bọ́ kúrò lọ́wọ́ ìdààmú. Láti inú èso rẹ̀, ènìyàn kún fún onírúurú ohun rere bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ti ń pín in lérè dájúdájú. Ọ̀nà aláìgbọ́n dára lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa gba ìmọ̀ràn. Aláìgbọ́n ènìyàn fi ìbínú un rẹ̀ hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ṣùgbọ́n olóye ènìyàn fojú fo ìyànjẹ. Ẹni tí ó jẹ́ ajẹ́rìí òtítọ́ jẹ́rìí ohun tí ojú rẹ̀ rí ṣùgbọ́n ajẹ́rìí èké máa ń parọ́. Ọ̀rọ̀ tí a kò rò jinlẹ̀ máa ń gún ni bí ọ̀kọ̀ ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń mú ìwòsàn wá. Ètè tí ń ṣọ òtítọ́ yóò wà láéláé ṣùgbọ́n ahọ́n tí ń parọ́ kì í tọ́jọ́. Ẹ̀tàn wà nínú ọkàn àwọn tí ń pète búburú ṣùgbọ́n ayọ̀ wà fún àwọn tí ń mú kí àlàáfíà gbilẹ̀. Ibi kì í ṣubú lu olódodo rárá ṣùgbọ́n ènìyàn búburú gba ìpín ìyọnu tiwọn. OLúWA kórìíra ètè tí ń parọ́ ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn olóòtítọ́. Ènìyàn olóye fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú ń gbé ìwà òmùgọ̀ jáde. Ọwọ́ àìṣọ̀lẹ yóò jẹ ọba ṣùgbọ́n ọ̀lẹ ṣíṣe a máa yọrí sí ẹrú ṣíṣe. Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodò ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀.

Owe 12:1-25 Bibeli Mimọ (YBCV)

ẸNIKẸNI ti o fẹ ẹkọ́, o fẹ ìmọ: ṣugbọn ẹniti o korira ibawi, ẹranko ni. Enia rere ni ojurere lọdọ Oluwa: ṣugbọn enia ete buburu ni yio dalẹbi. A kì yio fi ẹsẹ enia mulẹ nipa ìwa-buburu: ṣugbọn gbòngbo olododo kì yio fatu. Obinrin oniwa-rere li ade ọkọ rẹ̀: ṣugbọn eyi ti ndojuti ni dabi ọyún ninu egungun rẹ̀. Ìro olododo tọ́: ṣugbọn ìgbimọ awọn enia buburu, ẹ̀tan ni. Ọ̀rọ enia buburu ni lati luba fun ẹ̀jẹ: ṣugbọn ẹnu aduro-ṣinsin ni yio gbà wọn silẹ. A bì enia buburu ṣubu, nwọn kò si si: ṣugbọn ile olododo ni yio duro. A o yìn enia gẹgẹ bi ọgbọ́n rẹ̀: ṣugbọn ẹni alayidayida aiya li a o gàn. Ẹniti a ngàn, ti o si ni ọmọ-ọdọ, o san jù ẹ̀niti nyìn ara rẹ̀ ti kò si ni onjẹ. Olododo enia mọ̀ ãjo ẹmi ẹran rẹ̀: ṣugbọn iyọ́nu awọn enia buburu, ìka ni. Ẹniti o ro ilẹ rẹ̀ li a o fi onjẹ tẹlọrun: ṣugbọn ẹniti ntọ̀ enia-lasan lẹhin ni oye kù fun. Enia buburu fẹ ilu-odi awọn enia buburu: ṣugbọn gbòngbo olododo so eso. Irekọja ète enia buburu li a fi idẹkùn rẹ̀: ṣugbọn olododo yio yọ kuro ninu ipọnju. Nipa ère ẹnu enia li a o fi ohun rere tẹ ẹ lọrun: ère-iṣẹ ọwọ enia li a o si san fun u. Ọ̀na aṣiwere tọ li oju ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o fetisi ìgbimọ li ọlọgbọ́n. Ibinu aṣiwere kò pẹ imọ̀: ṣugbọn amoye enia bò itiju mọlẹ. Ẹniti o sọ otitọ, o fi ododo hàn jade; ṣugbọn ẹlẹri eke, ẹ̀tan. Awọn kan mbẹ ti nyara sọ̀rọ lasan bi igunni idà; ṣugbọn ahọn ọlọgbọ́n, ilera ni. Ete otitọ li a o mu duro lailai; ṣugbọn ahọn eke, ìgba diẹ ni. Ẹtan wà li aiya awọn ti nrò ibi: ṣugbọn fun awọn ìgbimọ alafia, ayọ̀ ni. Kò si ibi kan ti yio ba olododo; ṣugbọn awọn enia buburu ni yio kún fun ibi. Irira loju Oluwa li ahọn eke; ṣugbọn awọn ti nṣe rere ni didùn-inu rẹ̀. Ọlọgbọ́n enia pa ìmọ mọ; ṣugbọn aiya awọn aṣiwere nkede iwere. Ọwọ alãpọn ni yio ṣe akoso; ṣugbọn ọlẹ ni yio wà labẹ irú-sisìn. Ibinujẹ li aiya enia ni idori rẹ̀ kọ odò; ṣugbọn ọ̀rọ rere ni imu u yọ̀.

Owe 12:1-25 Yoruba Bible (YCE)

Ẹni tí ó fẹ́ ìtọ́sọ́nà, ó fẹ́ ìmọ̀, ṣugbọn ẹni tí ó kórìíra ìbáwí òmùgọ̀ ni. Eniyan rere a máa ní ojurere lọ́dọ̀ OLUWA, ṣugbọn ẹni tí ń pète ìkà ni yóo dá lẹ́bi. Kò sí ẹni tí ó lè ti ipa ìwà ìkà fi ìdí múlẹ̀, ṣugbọn gbòǹgbò olódodo kò ní fà tu. Obinrin oníwàrere ni adé orí ọkọ rẹ̀, ṣugbọn obinrin tí ń dójúti ọkọ dàbí ọyún inú egungun. Èrò ọkàn olódodo dára, ṣugbọn ẹ̀tàn ni ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú. Ọ̀rọ̀ àwọn eniyan burúkú dàbí ẹni tí ó lúgọ láti pa eniyan, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo a máa gbani là. A bi àwọn eniyan burúkú lulẹ̀, wọ́n sì parun, ṣugbọn ìdílé olódodo yóo dúró gbọningbọnin. À máa ń yin eniyan gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe gbọ́n tó, ṣugbọn ọlọ́kàn àgàbàgebè yóo di ẹni ẹ̀gàn. Mẹ̀kúnnù tí ó ní iṣẹ́, tí ó tún gba ọmọ-ọ̀dọ̀ ó sàn ju ẹni tí ó ń ṣe bí eniyan pataki, ṣugbọn tí kò rí oúnjẹ jẹ lọ. Olódodo a máa ka ẹ̀mí ẹran ọ̀sìn rẹ̀ sí, ṣugbọn eniyan burúkú rorò sí tirẹ̀. Ẹni tí ó bá ń dáko yóo ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń lo àkókò rẹ̀ lórí ohun tí kò lérè, kò lọ́gbọ́n lórí. Ilé ìṣọ́ àwọn eniyan burúkú yóo di òkítì àlàpà, ṣugbọn gbòǹgbò eniyan rere a máa fìdí múlẹ̀ sí i. Ọ̀rọ̀ ẹnu eniyan burúkú a máa mú un bíi tàkúté, ṣugbọn olódodo a máa bọ́ ninu ìyọnu. Ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa mú ìtẹ́lọ́rùn bá a, a sì máa jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Ọ̀nà òmùgọ̀ níí dára lójú tirẹ̀, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa fetí sí ìmọ̀ràn. Bí inú bá ń bí òmùgọ̀, kíá ni gbogbo eniyan yóo mọ̀, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n kìí ka ọ̀rọ̀ àbùkù sí. Ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ a máa jẹ́rìí òdodo, ṣugbọn irọ́ ni ẹlẹ́rìí èké máa ń pa. Ẹni tí í bá máa ń sọ̀rọ̀ jàbùjàbù láìronú, ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí kí á fi idà gún eniyan, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n dàbí ẹni wo ọgbẹ́ sàn. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ yóo máa wà títí ayé ṣugbọn irọ́, fún ìgbà díẹ̀ ni. Ẹ̀tàn ń bẹ lọ́kàn àwọn tí ń pète ibi, ṣugbọn àwọn tí ń gbèrò rere ní ayọ̀. Nǹkan burúkú kò ní ṣẹlẹ̀ sí olódodo, ṣugbọn eniyan burúkú yóo kún fún ìyọnu. OLUWA kórìíra ẹni tí ń parọ́, ṣugbọn inú rẹ̀ dùn sí olóòótọ́. Ọlọ́gbọ́n a máa fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́, ṣugbọn àwọn òmùgọ̀ a máa kéde agọ̀ wọn. Ẹni tí ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ ni yóo máa jẹ́ olórí, ṣugbọn ọ̀lẹ ni a óo máa mú ṣiṣẹ́ tipátipá. Ọ̀pọ̀ ìpayà máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá eniyan, ṣugbọn ọ̀rọ̀ rere a máa mú inú eniyan dùn.