Owe 10:8-19
Owe 10:8-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọlọgbọ́n inu ni yio gbà ofin: ṣugbọn ete werewere li a o parun. Ẹniti o nrìn dede, o rìn dajudaju: ṣugbọn ẹniti o ba nṣe ayida ọ̀na rẹ̀, on li a o mọ̀. Ẹniti nṣẹ́ oju o mu ibanujẹ wá: ṣugbọn ète werewere li a o parun. Kanga ìye li ẹnu olododo: ṣugbọn ìwa-agbara ni yio bo ẹnu enia buburu. Irira ni irú ìja soke: ṣugbọn ifẹ bò gbogbo ẹ̀ṣẹ mọlẹ. Li ète ẹniti o moye li a ri ọgbọ́n: ṣugbọn kùmọ ni fun ẹhin ẹniti oye kù fun. Awọn ọlọgbọ́n a ma to ìmọ jọ: ṣugbọn ẹnu awọn aṣiwere sunmọ iparun. Ọrọ̀ ọlọlà ni agbára rẹ̀: aini awọn talaka ni iparun wọn. Iṣẹ olododo tẹ̀ si ìye; èro awọn enia buburu si ẹ̀ṣẹ. Ẹniti o ba pa ẹkọ́ mọ́, o wà ni ipa-ọ̀na ìye; ṣugbọn ẹniti o ba kọ̀ ibawi o ṣìna. Ẹniti o ba pa ikorira mọ́ li ète eke, ati ẹniti o ba ngba ọ̀rọ-ẹ̀hin, aṣiwere ni. Ninu ọ̀rọ pipọ, a kò le ifẹ ẹ̀ṣẹ kù: ṣugbọn ẹniti o fi ète mọ ète li o gbọ́n.
Owe 10:8-19 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọ́gbọ́n a máa pa òfin mọ́, ṣugbọn òmùgọ̀ onísọkúsọ yóo di ẹni ìparun. Ẹni tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ eniyan, yóo máa rìn láìfòyà, ṣugbọn àṣírí alágàbàgebè yóo tú. Ẹni tí bá ń ṣẹ́jú sí ni láti sọ̀rọ̀ èké, a máa dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀, ṣugbọn ẹni tí bá ń báni wí ní gbangba, ń wá alaafia. Ẹnu olódodo dàbí orísun omi ìyè, ṣugbọn eniyan burúkú a máa fi ìwà ìkà sinu, a sì máa sọ̀rọ̀ rere jáde lẹ́nu. Ìkórìíra a máa rú ìjà sókè, ṣugbọn ìfẹ́ a máa fojú fo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ dá. Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n níí máa ń jáde lẹ́nu ẹni tí ó ní òye, ṣugbọn kùmọ̀ ló yẹ ẹ̀yìn ẹni tí kò gbọ́n. Ọlọ́gbọ́n eniyan a máa wá ìmọ̀ kún ìmọ̀, ṣugbọn ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ máa ń fa ìparun mọ́ra. Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ààbò rẹ̀, ṣugbọn àìní talaka ni yóo pa talaka run. Èrè àwọn olódodo a máa fa ìyè, ṣugbọn èrè àwọn eniyan burúkú a máa fà wọ́n sinu ẹ̀ṣẹ̀. Ẹni tí ó bá gba ìtọ́ni wà ní ọ̀nà ìyè, ṣugbọn ẹni tí ó bá kọ ìbáwí yóo ṣìnà. Ẹni tí ó di eniyan sinu jẹ́ ẹlẹ́tàn eniyan, ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́, òmùgọ̀ ni. Bí ọ̀rọ̀ bá ti pọ̀ jù, àṣìsọ a máa wọ̀ ọ́, ṣugbọn ẹni tí ó bá kó ẹnu ara rẹ̀ ní ìjánu, ọlọ́gbọ́n ni.
Owe 10:8-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹni tí ó gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ máa ń gba àṣẹ, ṣùgbọ́n ètè wérewère yóò parun. Ẹni tí ó ń rìn déédé, ń rìn láìléwu ṣùgbọ́n àṣírí ẹni tí ń rin ọ̀nà pálapàla yóò tú. Ẹni tí ń ṣẹ́jú pàkòpàkò fún ibi ń fa àìbalẹ̀ ọkàn aláìgbọ́n tí ń ṣàròyé kiri yóò parun. Ẹnu olódodo jẹ́ orísun ìyè ṣùgbọ́n ìwà ipá ni ó gba gbogbo ẹnu ènìyàn búburú. Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀. Ọgbọ́n ni a ń bá lẹ́nu àwọn olóye ṣùgbọ́n kùmọ̀ wà fún ẹ̀yìn àwọn aláìlóye. Ọlọ́gbọ́n ènìyàn kó ìmọ̀ jọ ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n a máa ṣokùnfà ìparun. Ọrọ̀ àwọn olódodo ni ìlú olódi wọn, ṣùgbọ́n òsì ni ìparun aláìní. Èrè olódodo ń mú ìyè wá fún wọn ṣùgbọ́n èrè ènìyàn búburú ń mú ìjìyà wá fún wọn. Ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí fi ọ̀nà sí ìyè hàn ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ ìbáwí mú àwọn mìíràn ṣìnà. Ẹni tí ó pa ìkórìíra rẹ̀ mọ́ jẹ́ òpùrọ́ ẹni tí ó sì ń ba ni jẹ́ jẹ́ aláìgbọ́n. Nínú ọ̀rọ̀ púpọ̀ a kò le fẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kù ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n.