Num 33:40-56
Num 33:40-56 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ara Kenaani, ọba Aradi, ti ngbé ìha gusù ni ilẹ Kenaani, o gburó pe awọn ọmọ Israeli mbọ̀. Nwọn si ṣí kuro ni òke Hori, nwọn si dó si Salmona. Nwọn si ṣí ni Salmona, nwọn si dó si Punoni. Nwọn si ṣí kuro ni Punoni, nwọn si dó si Obotu. Nwọn si ṣí kuro ni Obotu, nwọn si dó si Iye-abarimu, li àgbegbe Moabu. Nwọn si ṣí kuro ni Iyimu, nwọn si dó si Dibon-gadi. Nwọn si ṣí kuro ni Dibon-gadi, nwọn si dó si Almon-diblataimu. Nwọn si ṣí kuro ni Almon-diblataimu, nwọn si dó si òke Abarimu, niwaju Nebo. Nwọn si ṣí kuro ni òke Abarimu, nwọn si dó si pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko. Nwọn si dó si ẹba Jordani, lati Beti-jeṣimotu titi dé Abeli-ṣittimu ni pẹtẹlẹ̀ Moabu. OLUWA si sọ fun Mose ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko, wipe, Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba gòke odò Jordani si ilẹ Kenaani: Nigbana ni ki ẹnyin ki o lé gbogbo awọn ara ilẹ na kuro niwaju nyin; ki ẹnyin si run gbogbo aworán wọn, ki ẹnyin si run gbogbo ere didà wọn, ki ẹnyin si wó gbogbo ibi giga wọn palẹ: Ki ẹnyin ki o si gbà ilẹ na, ki ẹnyin ki o si ma gbé inu rẹ̀: nitoripe mo ti fi ilẹ na fun nyin lati ní i. Ki ẹnyin ki o si fi keké pín ilẹ na ni iní fun awọn idile nyin; fun ọ̀pọ ni ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní pupọ̀ fun, ati fun diẹ ni ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní diẹ fun: ki ilẹ-iní olukuluku ki o jẹ́ ibiti keké rẹ̀ ba bọ́ si; gẹgẹ bi ẹ̀ya awọn baba nyin ni ki ẹnyin ki o ní i. Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba lé awọn ara ilẹ na kuro niwaju nyin; yio si ṣe, awọn ti ẹnyin jẹ ki o kù ninu wọn yio di ẹgún si oju nyin, ati ẹgún si nyin ni ìha, nwọn o si ma yọ nyin lẹnu ni ilẹ na, ninu eyiti ẹnyin ngbé. Yio si ṣe, bi emi ti rò lati ṣe si wọn, bẹ̃ni emi o ṣe si nyin.
Num 33:40-56 Yoruba Bible (YCE)
Ọba ìlú Aradi, ní ilẹ̀ Kenaani, tí ń gbé Nẹgẹbu gbúròó pé àwọn ọmọ Israẹli ń bọ̀. Wọ́n kúrò ní Òkè Hori wọn lọ sí Salimona. Wọ́n kúrò ní Salimona wọ́n lọ sí Punoni. Láti Punoni wọ́n lọ sí Obotu. Láti Obotu wọ́n lọ sí Òkè Abarimu ní agbègbè Moabu. Láti Iyimu wọ́n lọ sí Diboni Gadi. Láti Diboni Gadi wọ́n lọ sí Alimoni Dibilataimu. Láti Alimoni Dibilataimu wọ́n lọ sí Òkè Abarimu níwájú Nebo. Láti Òkè Abarimu wọ́n lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá odò Jọdani létí Jẹriko. Wọ́n sì pàgọ́ wọn sí ẹ̀bá odò Jọdani láti Beti Jeṣimotu títí dé Abeli Ṣitimu ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu. OLUWA sọ fún Mose ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá odò Jọdani létí Jẹriko pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Nígbà tí ẹ bá ré odò Jọdani kọjá sí ilẹ̀ Kenaani, ẹ gbọdọ̀ lé gbogbo àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ náà kúrò. Ẹ run gbogbo àwọn oriṣa tí wọ́n fi òkúta ati irin ṣe ati gbogbo ilé oriṣa wọn. Kí ẹ gba ilẹ̀ náà kí ẹ sì máa gbé inú rẹ̀, nítorí pé mo ti fun yín gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní yín. Gègé ni kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún àwọn ẹ̀yà Israẹli. Fún àwọn tí ó pọ̀ ní ilẹ̀ pupọ, sì fún àwọn tí ó kéré ní ilẹ̀ kékeré. Ilẹ̀ tí gègé olukuluku bá mú ni yóo jẹ́ tirẹ̀, láàrin àwọn ẹ̀yà yín ni ẹ óo ti pín ilẹ̀ náà. Ṣugbọn bí ẹ kò bá lé gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò, àwọn tí ó bá kù yóo di ẹ̀gún ní ojú yín ati ẹ̀gún ní ìhà yín, wọn yóo sì máa yọ yín lẹ́nu lórí ilẹ̀ náà. Bí ẹ kò bá lé gbogbo wọn jáde, ohun tí mo ti pinnu láti ṣe sí wọn, ẹ̀yin ni n óo ṣe é sí.”
Num 33:40-56 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ará Kenaani, ọba Aradi, tí ń gbé ìhà gúúsù ní ilẹ̀ Kenaani gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ń bọ̀. Wọ́n kúrò ní orí òkè Hori, wọ́n sì pàgọ́ ní Salmona. Wọ́n kúrò ní Salmona wọ́n sì pàgọ́ ní Punoni. Wọ́n kúrò ní Punoni wọ́n sì pàgọ́ ní Obotu. Wọ́n kúrò ní Obotu wọ́n sì pàgọ́ ní Iye-Abarimu, ní agbègbè Moabu. Wọ́n kúrò ní Iyimu, wọ́n sì pàgọ́ ní Diboni-Gadi. Wọ́n kúrò ní Diboni-Gadi wọ́n sì pàgọ́ ní Alimon-Diblataimu. Wọ́n kúrò ní Alimon-Diblataimu wọ́n sì pàgọ́ sí orí òkè Abarimu lẹ́bàá Nebo. Wọ́n kúrò ní orí òkè Abarimu wọ́n sì pàgọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá Jordani ní ìkọjá Jeriko. Níbí ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu wọ́n pàgọ́ lẹ́gbẹ́ Jordani láti Beti-Jeṣimoti títí dé Abeli-Ṣittimu. Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, lẹ́bàá Jordani, létí Jeriko, OLúWA sọ fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí o sì wí fún wọn pé, ‘Ní ìgbà tí ẹ̀yin bá ń rékọjá odò Jordani lọ sí Kenaani, Lé gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín. Run gbogbo àwòrán ère wọn àti gbogbo ère dídá wọn, kí ẹ sì wó gbogbo ibi gíga wọn palẹ̀. Ẹ gba ilẹ̀ náà, kí ẹ̀yin sì máa gbé inú rẹ̀, nítorí èmi ti fi ilẹ̀ náà fún yín gẹ́gẹ́ bí ìní yín. Ẹ̀yin pín ilẹ̀ náà pẹ̀lú kèké, gẹ́gẹ́ bí ìdílé yín. Fún ọ̀pọ̀ ni kí ẹ̀yin ó fi ilẹ̀ ìní púpọ̀ fún, àti fún díẹ̀, ni kí ẹ̀yin kí ó fi ilẹ̀ ìní díẹ̀ fún. Ohunkóhun tí ó bá bọ́ sí ọ̀dọ̀ wọn nípa kèké yóò jẹ́ tiwọn. Pín wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ìran wọn. “ ‘Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá lé àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín, àwọn tí ẹ bá jẹ́ kí ó kù yóò di ọfà nínú ojú yín, àti ẹ̀gún ní ìhà yín. Wọn yóò fún yín ní wàhálà ní ilẹ̀ náà tí ẹ̀yin yóò gbé. Nígbà náà, èmi yóò ṣe sí yín, ohun tí mo ti rò láti ṣe sí wọn.’ ”