Num 3:12-13
Num 3:12-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati emi, kiyesi i, emi ti gbà awọn ọmọ Lefi kuro lãrin awọn ọmọ Israeli ni ipò gbogbo akọ́bi ti o ṣí inu ninu awọn ọmọ Israeli; nitorina ti emi li awọn ọmọ Lefi iṣe: Nitoripe ti emi ni gbogbo akọ́bi; nitoripe li ọjọ́ na ti mo kọlù gbogbo akọ́bi ni ilẹ Egipti, ni mo yà gbogbo akọ́bi sọ̀tọ fun ara mi ni Israeli, ati enia ati ẹran: ti emi ni nwọn o ma ṣe: Emi li OLUWA.
Num 3:12-13 Yoruba Bible (YCE)
“Mo ti yan àwọn ọmọ Lefi láàrin àwọn eniyan Israẹli dípò àwọn àkọ́bí ọmọ Israẹli. Tèmi ni àwọn ọmọ Lefi, nítorí tèmi ni gbogbo àwọn àkọ́bí. Nígbà tí mo pa gbogbo àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti ni mo ya gbogbo àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Israẹli sọ́tọ̀; kì báà ṣe ti eniyan tabi ti ẹranko, tèmi ni gbogbo wọn. Èmi ni OLUWA.”
Num 3:12-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Báyìí èmi fúnra mi ti mú ẹ̀yà Lefi láàrín àwọn ọmọ Israẹli dípò gbogbo àkọ́bí ọkùnrin àwọn ọmọbìnrin Israẹli. Ti èmi ni àwọn ọmọ Lefi, nítorí pé ti èmi ni gbogbo àkọ́bí. Ní ọjọ́ tí mo pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Ejibiti ni mo ti ya gbogbo àkọ́bí sọ́tọ̀ ní Israẹli yálà ti ènìyàn tàbí ti ẹranko. Gbogbo wọn gbọdọ̀ jẹ́ ti èmi. Èmi ni OLúWA.”