NỌMBA 3

3
Àwọn Ọmọ Aaroni
1Àwọn wọnyi ni ìdílé Aaroni ati ti Mose, nígbà tí OLUWA bá Mose sọ̀rọ̀ ní orí òkè Sinai. 2Orúkọ àwọn ọmọ Aaroni lọkunrin nìwọ̀nyí: Nadabu ni àkọ́bí, lẹ́yìn rẹ̀ ni Abihu, Eleasari ati Itamari.#Nọm 26:60 3Àwọn ni ó ta òróró sí lórí, láti yà wọ́n sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ alufaa. 4Nadabu ati Abihu kú nígbà tí wọ́n fi iná tí a kò yà sí mímọ́ rúbọ sí OLUWA ninu aṣálẹ̀ Sinai. Wọn kò bímọ. Nítorí náà Eleasari ati Itamari ní ń ṣe iṣẹ́ alufaa ní ìgbà ayé Aaroni, baba wọn.#Lef 10:1-2; Nọm 26:61
Wọ́n yan Àwọn Ọmọ Lefi láti máa ṣe Iranṣẹ fún Àwọn Alufaa
5OLUWA sọ fún Mose pé, 6“Mú ẹ̀yà Lefi wá siwaju Aaroni alufaa, kí wọ́n sì máa ṣe iranṣẹ fún un. 7Àwọn ni yóo máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn alufaa ati fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli níwájú Àgọ́ Àjọ bí àwọn alufaa tí ń ṣe iṣẹ́ níbi mímọ́. 8Àwọn ọmọ Lefi yóo máa ṣe ìtọ́jú gbogbo ohun èlò Àgọ́ Àjọ, wọn óo sì máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún gbogbo ọmọ Israẹli bí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ níbi mímọ́. 9Fi àwọn ọmọ Lefi fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀. Àwọn nìkan ni wọn óo jẹ́ iranṣẹ fún wọn láàrin àwọn ọmọ Israẹli. 10Yan Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ibi mímọ́, pípa ni kí ẹ pa á.”
11OLUWA sọ fún Mose pé, 12“Mo ti yan àwọn ọmọ Lefi láàrin àwọn eniyan Israẹli dípò àwọn àkọ́bí ọmọ Israẹli. Tèmi ni àwọn ọmọ Lefi, 13nítorí tèmi ni gbogbo àwọn àkọ́bí. Nígbà tí mo pa gbogbo àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti ni mo ya gbogbo àwọn àkọ́bí ní ilẹ̀ Israẹli sọ́tọ̀; kì báà ṣe ti eniyan tabi ti ẹranko, tèmi ni gbogbo wọn. Èmi ni OLUWA.”#Eks 13:2
Kíka Àwọn Ọmọ Lefi
14OLUWA sọ fún Mose ninu aṣálẹ̀ Sinai, ó ní, 15“Ka iye àwọn ọmọkunrin Lefi gẹ́gẹ́ bí ìdílé baba wọn. Bẹ̀rẹ̀ láti ọmọ oṣù kan lọ sókè.” 16Mose sì kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. 17Lefi ní ọmọkunrin mẹta: Geriṣoni, Kohati ati Merari, wọ́n sì jẹ́ olórí àwọn ìdílé wọn. 18Orúkọ àwọn ọmọ Geriṣoni ni Libini ati Ṣimei. 19Orúkọ àwọn ọmọ Kohati ni Amramu, Iṣari, Heburoni ati Usieli. 20Orúkọ àwọn ọmọ Merari ni Mahili ati Muṣi. Àwọn ìdílé Lefi nìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.
21Geriṣoni ni baba ńlá àwọn ọmọ Libini ati àwọn ọmọ Ṣimei. 22Gbogbo àwọn ọkunrin tí a kà ninu wọn, láti ọmọ oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaarin ó dín ẹẹdẹgbẹta (7,500). 23Àwọn ọmọ Geriṣoni yóo pàgọ́ tiwọn sẹ́yìn Àgọ́ Àjọ ní ìhà ìwọ̀ oòrùn. 24Eliasafu ọmọ Laeli ni yóo jẹ́ olórí wọn. 25Àwọn ni yóo máa ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́ ati Àgọ́ Àjọ, aṣọ ìbòrí rẹ̀, ati aṣọ tí wọ́n ń ta sí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé rẹ̀; 26aṣọ tí wọ́n ń ta sí àgbàlá, aṣọ tí wọ́n ń ta sí ẹnu ọ̀nà àbáwọ àgbàlá tí ó yí ibi mímọ́ ati pẹpẹ ká, ati okùn, ati gbogbo nǹkan tí wọ́n ń lò pẹlu rẹ̀.
27Kohati ni baba ńlá àwọn ọmọ Amramu ati àwọn ọmọ Iṣari, àwọn ọmọ Heburoni ati àwọn ọmọ Usieli. 28Gbogbo àwọn ọkunrin tí a kà ninu wọn láti ọmọ oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaarin ó lé ẹgbẹta (8,600). Àwọn ni wọ́n ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́. 29Àwọn ọmọ Kohati yóo pàgọ́ tiwọn sí ẹ̀gbẹ́ Àgọ́ Àjọ ní ìhà gúsù. 30Elisafani ọmọ Usieli ni yóo jẹ́ olórí wọn. 31Àwọn ni yóo máa ṣe ìtọ́jú Àpótí majẹmu ati tabili, ọ̀pá fìtílà ati àwọn pẹpẹ, ati àwọn ohun èlò ní ibi mímọ́, tí àwọn alufaa máa ń lò fún iṣẹ́ ìsìn; ati aṣọ ìbòjú, ati gbogbo iṣẹ́ tí ó jẹ mọ́ ti àwọn ohun èlò wọnyi.
32Eleasari ọmọ Aaroni alufaa ni yóo máa ṣe alákòóso àwọn olórí àwọn ọmọ Lefi, òun ni yóo sì máa ṣe àkóso àwọn tí ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́.
33Merari ni baba ńlá àwọn ọmọ Mahili, ati ti àwọn ọmọ Muṣi. 34Gbogbo àwọn ọkunrin tí a kà ninu wọn láti ọmọ oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaata lé igba (6,200). 35Surieli ọmọ Abihaili ni yóo jẹ́ olórí wọn. Kí wọ́n pàgọ́ tiwọn sí ìhà àríwá Àgọ́ Àjọ. 36Àwọn ni yóo máa ṣe ìtọ́jú àwọn igi àkànpọ̀ ibi mímọ́, ati àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀ pẹlu àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀, ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, ati gbogbo iṣẹ́ tí ó jẹ mọ́ wọn; 37ati gbogbo òpó àgbàlá yíká, pẹlu àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn, èèkàn wọn, ati okùn wọn.
38Mose pẹlu Aaroni ati àwọn ọmọ wọn yóo pa àgọ́ tiwọn sí ìhà ìlà oòrùn, níwájú Àgọ́ Àjọ. Àwọn ni yóo máa ṣe iṣẹ́ ìsìn fún àwọn ọmọ Israẹli ní ibi mímọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ibi mímọ́, pípa ni kí wọ́n pa á. 39Gbogbo àwọn ọmọ Lefi lọkunrin, láti ọmọ oṣù kan sókè tí Mose kà ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA jẹ́ ẹgbaa mọkanla (22,000).
Àwọn Ọmọ Lefi Rọ́pò Àwọn Àkọ́bí
40OLUWA sọ fún Mose pé, “Ka gbogbo àkọ́bí lọkunrin láàrin àwọn ọmọ Israẹli láti ọmọ oṣù kan sókè, kí o sì kọ orúkọ wọn sílẹ̀. 41Gba àwọn ọmọ Lefi fún mi dípò awọn àkọ́bí ní Israẹli, sì gba àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, dípò àwọn àkọ́bí ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli. Èmi ni OLUWA.” 42Mose bá ka gbogbo àwọn àkọ́bí ninu àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un. 43Gbogbo àkọ́bí ọkunrin, gẹ́gẹ́ bí orúkọ wọn, lati ọmọ oṣù kan lọ sókè ní iye wọn, lápapọ̀, wọn jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé igba ati mẹtalelaadọrin (22,273).
44OLUWA sọ fún Mose pé, 45“Gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àwọn àkọ́bí ninu àwọn ọmọ Israẹli, ati ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Lefi dípò ohun ọ̀sìn wọn. Àwọn ọmọ Lefi yóo sì jẹ́ tèmi. Èmi ni OLUWA. 46Níwọ̀n ìgbà tí àwọn àkọ́bí Israẹli fi igba ó lé mẹtalelaadọrin (273) pọ̀ ju àwọn ọmọ Lefi lọ, wọ́n níláti rà wọ́n pada. 47Kí o gba ṣekeli marun-un-marun-un lórí ẹnìkọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ní ibi mímọ́. 48Kí o sì kó owó náà fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀.” 49Mose gba owó ìràpadà náà lórí àwọn tí iye àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli fi pọ̀ ju àwọn ọmọ Lefi lọ. 50Owó tí ó gbà jẹ́ egbeje ìwọ̀n ṣekeli fadaka ó dín marundinlogoji (1,365), gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ní ibi mímọ́. 51Mose fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ní owó ìràpadà náà gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

NỌMBA 3: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀