Num 14:34-35
Num 14:34-35 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gẹgẹ bi iye ọjọ́ ti ẹnyin fi rìn ilẹ na wò, ani ogoji ọjọ́, ọjọ́ kan fun ọdún kan, li ẹnyin o rù ẹ̀ṣẹ nyin, ani ogoji ọdún, ẹnyin o si mọ̀ ibà ileri mi jẹ́. Emi OLUWA ti sọ, Emi o ṣe e nitõtọ si gbogbo ijọ buburu yi, ti nwọn kójọ pọ̀ si mi: li aginjù yi ni nwọn o run, nibẹ̀ ni nwọn o si kú si.
Num 14:34-35 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ óo sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ogoji ọdún. Ọdún kọ̀ọ̀kan yóo dípò ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ninu ogoji ọjọ́ tí àwọn amí fi wo ilẹ̀ náà. Ẹ óo rí ibinu mi. Mo ti ṣe ìlérí pé n óo ṣe àwọn nǹkan wọnyi sí ẹ̀yin eniyan burúkú, tí ẹ̀ ń lòdì sí mi wọnyi. Gbogbo yín ni yóo kú ninu aṣálẹ̀ yìí. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ”
Num 14:34-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Fún ogójì ọdún èyí jẹ́ ọdún kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ogójì ọjọ́ tí ẹ fi yẹ ilẹ̀ náà wò ẹ̀yin ó sì jìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ ó sì mọ bí ó ti rí láti lòdì sí mi. Èmi, OLúWA, lo sọ bẹ́ẹ̀; Èmi ó sì ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí ìjọ ènìyàn búburú yìí tí wọ́n kó ra wọn jọ lòdì sí mi. Nínú aginjù yìí ni òpin yóò dé bá wọn, ibẹ̀ ni wọn yóò kú sí.”