Num 14:22-24
Num 14:22-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori gbogbo awọn enia wọnyi ti o ti ri ogo mi, ati iṣẹ-àmi mi, ti mo ti ṣe ni Egipti ati li aginjù, ti nwọn si dan mi wò nigba mẹwa yi, ti nwọn kò si fetisi ohùn mi; Nitõtọ nwọn ki yio ri ilẹ na ti mo ti fi bura fun awọn baba wọn, bẹ̃ni ọkan ninu awọn ti o gàn mi ki yio ri i: Ṣugbọn Kalebu iranṣẹ mi, nitoriti o ní ọkàn miran ninu rẹ̀, ti o si tẹle mi mọtimọti, on li emi o múlọ sinu ilẹ na nibiti o ti rè; irú-ọmọ rẹ̀ ni yio si ní i.
Num 14:22-24 Yoruba Bible (YCE)
àwọn eniyan wọnyi, tí wọ́n ti rí ògo mi ati àwọn iṣẹ́ ìyanu tí mo ṣe ní Ijipti ati ninu aṣálẹ̀, ṣugbọn tí wọ́n ti dán mi wò nígbà mẹ́wàá, tí wọ́n sì ṣàìgbọràn sí mi, ẹnikẹ́ni ninu wọn kò ní dé ilẹ̀ tí mo ti ṣe ìlérí fún àwọn baba wọn. Ẹyọ kan ninu àwọn tí wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀ wọnyi kò ní débẹ̀. Ṣugbọn nítorí pé iranṣẹ mi, Kalebu, ní ẹ̀mí tí ó yàtọ̀, ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí mi, n óo mú un dé ilẹ̀ tí ó lọ wò, ilẹ̀ náà yóo sì jẹ́ ti àwọn ọmọ rẹ̀.
Num 14:22-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tó rí ògo mi àti àwọn iṣẹ́ ààmì tí mo ṣe ní ilẹ̀ Ejibiti àti nínú aginjù ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí mi, tí wọn sì dán mi wò ní ìgbà mẹ́wàá yìí, Ọ̀kan nínú wọn kò ní rí ilẹ̀ náà tí mo ṣe ìlérí ní ìbúra láti fún baba ńlá wọn. Kò sí ọ̀kan nínú àwọn tó kẹ́gàn mi tí yóò rí ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n nítorí pé Kalebu ìránṣẹ́ mi ní ẹ̀mí ọ̀tọ̀, tí ó sì tún tẹ̀lé mi tọkàntọkàn, èmi ó mu dé ilẹ̀ náà tó lọ yẹ̀ wò, irú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì jogún rẹ̀.