Neh 4:1-9

Neh 4:1-9 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí Sanbalati gbọ́ pé a ti ń kọ́ odi náà, inú bíi gidigidi, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn Juu. Ó sọ lójú àwọn arakunrin rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun Samaria pé, “Kí ni àwọn Juu aláìlera wọnyi ń ṣé? Ṣé wọn yóo tún ìlú wọn kọ́ ni? Ṣé wọn yóo tún máa rúbọ ni? Ṣé ọjọ́ kan ṣoṣo ni wọ́n fẹ́ parí rẹ̀ ni? Ṣé wọn yóo lè yọ àwọn òkúta kúrò ninu àlàpà tí wọ́n wà, kí wọn sì fi òkúta tí ó ti jóná gbẹ́ òkúta ìkọ́lé?” Tobaya ará Amoni náà sì fara mọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, bí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ bá gun orí ohun tí wọ́n mọ, tí wọn ń pè ní odi olókùúta, wíwó ni yóo wó o lulẹ̀!” Mo bá gbadura pé, “Gbọ́, Ọlọrun wa, nítorí pé wọ́n kẹ́gàn wa. Yí ẹ̀gàn wọn pada lé wọn lórí, kí o sì fi wọ́n lé alágbèédá lọ́wọ́ ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ. Má mójú fo àìdára wọn, má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúrò ninu àkọsílẹ̀ tí ó wà níwájú rẹ, nítorí pé wọ́n ti mú ọ bínú níwájú àwọn tí wọn ń mọ odi.” Bẹ́ẹ̀ ni, à ń mọ odi náà, a mọ ọ́n já ara wọn yípo, ó sì ga dé ìdajì ibi tí ó yẹ kí ó ga dé, nítorí pé àwọn eniyan náà ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn. Ṣugbọn nígbà tí Sanbalati ati Tobaya ati àwọn ará Arabu, ati àwọn ará Amoni, ati àwọn ará Aṣidodu, gbọ́ pé a ti ń ṣe àtúnṣe àwọn odi Jerusalẹmu ati pé a ti ń dí àwọn ihò ibẹ̀, inú bí wọn gidigidi. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí dìtẹ̀ láti wá gbógun ti Jerusalẹmu kí wọ́n lè dá rúkèrúdò sílẹ̀. Ṣugbọn a gbadura sí Ọlọrun wa, a sì yan àwọn olùṣọ́ láti máa ṣọ́ ibẹ̀ tọ̀sán-tòru.

Neh 4:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí Sanballati gbọ́ pé àwa ń tún odi náà mọ, ó bínú, ó sì bínú púpọ̀. Ó fi àwọn ará Júù ṣe ẹlẹ́yà, ó sọ níwájú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ àti níwájú àwọn ọmọ-ogun Samaria pé, “Kí ni àwọn aláìlera Júù wọ̀nyí ń ṣe yìí? Ṣé wọn yóò mú odi wọn padà ni? Ṣé wọn yóò rú ẹbọ ni? Ṣé wọn yóò parí i rẹ̀ lóòjọ́ ni bí? Ṣé wọ́n lè mú òkúta tí a ti sun láti inú òkìtì padà bọ̀ sípò tí ó jóná bí wọ́n ṣe wà?” Tobiah ará Ammoni, ẹni tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, wí pé, “Ohun tí wọ́n ń mọ—bí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ lásán bá gùn ún sókè, yóò fọ́ odi òkúta wọn lulẹ̀!” Gbọ́ ti wa, Ọlọ́run wa, nítorí àwa di ẹni ẹ̀gàn. Dá ẹ̀gàn wọn padà sórí ara wọn. Kí o sì fi wọ́n fún ìkógun ní ilẹ̀ ìgbèkùn. Má ṣe bo ẹ̀bi wọn tàbí wẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn nù kúrò níwájú rẹ, nítorí wọ́n mú ọ bínú níwájú àwọn ọ̀mọ̀lé. Bẹ́ẹ̀ ni àwa mọ odi náà títí gbogbo rẹ̀ fi dé ìdajì gíga rẹ̀, nítorí àwọn ènìyàn ṣiṣẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn an wọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí Sanballati, Tobiah, àwọn ará Arabia, ará Ammoni, àti àwọn ènìyàn Aṣdodu gbọ́ pé àtúnṣe odi Jerusalẹmu ti ga dé òkè àti pé a ti mọ àwọn ibi tí ó yá dí, inú bí wọn gidigidi. Gbogbo wọn jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti wá bá Jerusalẹmu jà àti láti dìde wàhálà sí í. Ṣùgbọ́n àwa gbàdúrà sí Ọlọ́run wa, a sì yan olùṣọ́ ọ̀sán àti ti òru láti kojú ìhàlẹ̀ yìí.