O SI ṣe, nigbati Sanballati gbọ́ pe awa mọ odi na, inu rẹ̀ rú, o si binu pupọ, o si gàn awọn ara Juda. O si sọ niwaju awọn arakunrin rẹ̀ ati awọn ọmọ-ogun Samaria pe, Kini awọn alailera Juda wọnyi nṣe yi? nwọn o ha dá wà fun ara wọn bi? nwọn o ha rubọ? nwọn o ha ṣe aṣepari ni ijọkan? nwọn o ha mu okuta ti a ti sun lati inu okìti sọji? Tobiah ara Ammoni si wà li eti ọ̀dọ rẹ̀, o si wipe, Eyi ti nwọn mọ gidi, bi kọ̀lọkọlọ ba gùn u, yio tilẹ wo odi okuta wọn lulẹ̀. Gbọ́, Ọlọrun wa; nitoriti awa di ẹni ẹ̀gan: ki iwọ ki o si dà ẹgan wọn si ori ara wọn, ki o si fi wọn fun ikogun ni ilẹ ìgbekun. Ki o má si bo irekọja wọn, má si jẹ ki a wẹ ẹ̀ṣẹ wọn nù kuro niwaju rẹ: nitoriti nwọn bi ọ ni inu niwaju awọn ọ̀mọle, Bẹ̃ni awa mọ odi na: gbogbo odi na ni a si mọ kàn ara wọn titi de ida meji rẹ̀: nitori awọn enia na ni ọkàn lati ṣiṣẹ. O si ṣe, nigbati Sanballati, ati Tobiah, ati awọn ara Arabia, ati awọn ara Ammoni, ati awọn ara Aṣdodi gbọ́ pe, a mọ odi Jerusalemu de oke, ati pe a bẹ̀rẹ si tun ibi ti o ya ṣe, inu wọn ru gidigidi. Gbogbo wọn si jọ gbìmọ pọ̀ lati wá iba Jerusalemu jà, ati lati ṣe ika si i. Ṣugbọn awa gba adura wa si Ọlọrun wa, a si yan iṣọ si wọn lọsan ati loru, nitori wọn.
Kà Neh 4
Feti si Neh 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Neh 4:1-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò