Neh 3:1-32

Neh 3:1-32 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBANA ni Eliaṣibu olori alufa dide pẹlu awọn alufa arakunrin rẹ̀, nwọn si mọ ẹnu-bode agutan; nwọn sọ ọ di mimọ́, nwọn si gbe ilẹkùn rẹ̀ duro, titi de ile-iṣọ Mea, ni nwọn sọ di mimọ́ titi de ile-iṣọ Hananeeli. Lọwọkọwọ rẹ̀ ni awọn ọkunrin Jeriko si mọ: lọwọkọwọ wọn ni Sakkuri ọmọ Imri si mọ. Ṣugbọn ẹnu-bode Ẹja ni awọn ọmọ Hasenaa mọ, ẹniti o tẹ́ igi idabu rẹ̀, ti o si gbe ilẹkun rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀, ati itikùn rẹ̀. Lọwọkọwọ wọn ni Meremoti ọmọ Urijah, ọmọ Kosi, tun ṣe. Ati lọwọkọwọ wọn ni Meṣullamu, ọmọ Berekiah, ọmọ Meṣesabeli tun ṣe. Ati lọwọkọwọ wọn ni Sadoku, ọmọ Baana tun ṣe. Ati lọwọkọwọ wọn ni awọn ará Tekoa tun ṣe, ṣugbọn awọn ọlọla kò fi ọrùn si iṣẹ Oluwa wọn. Jehoida, ọmọ Pasea, ati Meṣullamu, ọmọ Besodiah, si tun ẹnu-bode atijọ ṣe, nwọn tẹ̀ igi idabu rẹ̀, nwọn si gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, ati àgadágodo rẹ̀, ati itikùn rẹ̀. Lọwọkọwọ wọn ni Melatiah, ará Gibeoni, tun ṣe, ati Jadoni, ara Merono, awọn ọkunrin ti Gibeoni, ati ti Mispa, ti o jẹ ti itẹ bãlẹ̀ apa ihin odò. Lọwọkọwọ rẹ̀ ni Ussieli ọmọ Harhiah, alagbẹdẹ wura tun ṣe; ati lọwọkọwọ rẹ̀ ni Hananiah ọmọ alapolu, tun ṣe; nwọn si ti fi Jerusalemu silẹ̀ titi de odi gbigbõro. Lọwọkọwọ wọn ni Refaiah, ọmọ Huri ijòye idaji Jerusalemu si tun ṣe. Lọwọkọwọ wọn ni Jedaiah, ọmọ Haramafu, si tun ṣe, ani ọkánkan ile rẹ̀. Lọwọkọwọ rẹ̀ ni Hattuṣi ọmọ Haṣabaniah si tun ṣe. Malkijah ọmọ Harimu, ati Haṣubu ọmọ Pahati-Moabu, tun apa keji ṣe, ati ile-iṣọ ileru. Ati lọwọkọwọ rẹ̀ Ṣallumu ọmọ Haloheṣi, ijòye apa kan Jerusalemu, tun ṣe, on ati awọn ọmọbinrin rẹ̀. Hanuni pẹlu awọn ará Sanoa si tun ẹnu-bode afonifoji ṣe; nwọn kọ́ ọ, nwọn si gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀ ati itikùn rẹ̀, ati ẹgbẹrun igbọnwọ odi titi de ẹnu-bode ãtàn. Ẹnu-bode ãtàn ni Malkiah ọmọ Rekabu, ijòye apa kan Bet-hakkeremu tun ṣe; o kọ́ ọ, o gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀ ati itìkun rẹ̀. Ṣallumu, ọmọ Kol-hose, ijòye apakan Mispa si tun ẹnu-bode orisun ṣe; o kọ́ ọ, o si bò o, o si gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀, ati itìkun rẹ̀ ati odi adagun Ṣiloa li ẹ̀ba ọgba ọba, ati titi de atẹ̀gun ti o sọkalẹ lati ile Dafidi lọ. Lẹhin rẹ̀ ni Nehemiah, ọmọ Asbuku, ijòye idaji Bet-huri, tun ṣe titi de ibi ọkánkán iboji Dafidi, ati de adagun ti a ṣe, ati titi de ile awọn alagbara. Lẹhin rẹ̀ ni awọn ọmọ Lefi, Rehumu, ọmọ Bani tun ṣe. Lẹhin rẹ̀ ni Haṣabiah ijòye idaji Keila tun ṣe li apa tirẹ̀. Lẹhin rẹ̀ ni awọn arakunrin wọn tun ṣe, Bafai ọmọ Henadadi, ijoye idaji Keila. Lọwọkọwọ rẹ̀ ni Eseri ọmọ Jeṣua, ijòye Mispa, tun apa miran ṣe li ọkánkán titọ lọ si ile-ihamọra kọrọ̀ odi. Lẹhin rẹ̀ ni Baruku ọmọ Sabbai fi itara tun apa miran ṣe, lati igun ogiri titi de ilẹkùn ile Eliaṣibu, olori alufa. Lẹhin rẹ̀ ni Meremoti ọmọ Urijah, ọmọ Kosi tun apa miran ṣe lati ilẹkùn ile Eliaṣibu titi de ipẹkun ile Eliaṣibu. Lẹhin rẹ̀ ni awọn alufa si tun ṣe, awọn ọkunrin pẹtẹlẹ [Jordani]. Lẹhin wọn ni Benjamini ati Haṣubu tun ṣe li ọkánkán ile wọn. Lẹhin wọn ni Asariah ọmọ Maasiah ọmọ Ananiah tun ṣe lẹba ile rẹ̀. Lẹhin rẹ̀ ni Binnui, ọmọ Henadadi tun apa miran ṣe, lati ile Asariah titi de igun odi, ani titi de kọrọ̀. Palali ọmọ Usai li ọkánkán igun odi, ati ile-iṣọ ti o yọ sode lati ile giga ti ọba wá ti o wà lẹba ile tubu. Lẹhin rẹ̀ ni Padaiah ọmọ Paroṣi. Ṣugbọn awọn Netinimu gbe Ofeli, titi de ọkánkán ẹnu-bode omi niha ila-õrùn ati ile iṣọ ti o yọ sode. Lẹhin wọn ni awọn ara Tekoa tun apa miran ṣe, li ọkánkán ile-iṣọ nla ti o yọ sode, titi de odi Ofeli. Lati oke ẹnu-bode ẹṣin ni awọn alufa tun apa miran ṣe, olukuluku li ọkánkán ile rẹ̀. Lẹhin wọn ni Sadoku, ọmọ Immeri tun ṣe li ọkánkán ile rẹ̀: lẹhin rẹ̀ ni Ṣemaiah ọmọ Ṣekaniah, olùtọju ẹnubode ila-õrùn tun ṣe. Lẹhin wọn ni Hananiah ọmọ Selamiah tun ṣe, ati Hanuni ọmọ Salafu kẹfa tun apa miran ṣe. Lẹhin rẹ̀ ni Meṣullamu, ọmọ Berekiah li ọkánkán yàra rẹ̀. Lẹhin rẹ̀ ni Malkiah ọmọ alagbẹdẹ wura tun ṣe, titi de ile awọn Netinimu ati ti awọn oniṣòwo, li ọkánkán ẹnu bode Mifkadi ati yàra òke igun-odi. Ati larin yàra òke igun-odi titi de ẹnu-bode agutan ni awọn alagbẹdẹ wura ati awọn oniṣòwo tun ṣe.

Neh 3:1-32 Yoruba Bible (YCE)

Eliaṣibu, Olórí alufaa, ati àwọn arakunrin rẹ̀ tí àwọn náà jẹ́ alufaa bíi rẹ̀ múra, wọ́n sì kọ́ Ẹnubodè Aguntan. Wọ́n yà á sí mímọ́ wọn sì ṣe àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, wọ́n yà á sí mímọ́ títí dé Ilé Ìṣọ́ Ọgọrun-un, ati títí dé Ilé Ìṣọ́ Hananeli. Ibẹ̀ ni àwọn ará Jẹriko ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Lẹ́yìn wọn ni Sakuri ọmọ Imiri bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, ó mọ abala tí ó tẹ̀lé e. Àwọn ọmọ Hasenaa ni wọ́n kọ́ Ẹnubodè Ẹja, wọ́n ṣe àwọn ẹnu ọ̀nà, wọ́n so àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, wọ́n sì ṣe ọ̀pá ìdábùú sí àwọn ìlẹ̀kùn náà. Lẹ́yìn wọn ni Meremoti, ọmọ Uraya, ọmọ Hakosi ṣe àtúnṣe abala ọ̀dọ̀ wọn. Lẹ́yìn wọn, Meṣulamu ọmọ Berekaya, ọmọ Meṣesabeli náà ṣe àtúnṣe abala ọ̀dọ̀ wọn. Lẹ́yìn wọn ni Sadoku, ọmọ Baana náà ṣe àtúnṣe abala tiwọn. Lẹ́yìn wọn, àwọn ará Tekoa ṣe àtúnṣe ọ̀dọ̀ tiwọn, ṣugbọn àwọn ọlọ́lá ààrin wọn kò lọ́wọ́ sí iṣẹ́ àtúnṣe náà. Joiada, ọmọ Pasea, ati Meṣulamu, ọmọ Besodeaya, ni wọ́n ṣe àtúnṣe Ẹnubodè Àtijọ́. Wọ́n ṣe ẹnu ọ̀nà, wọ́n ṣe àwọn ìlẹ̀kùn, wọ́n sì ṣe ọ̀pá ìdábùú sí wọn. Lẹ́yìn wọn ni àwọn Melataya, ará Gibeoni, Jadoni, ará Meronoti, ati àwọn ará Gibeoni ati àwọn ará Misipa tí wọ́n wà ní abẹ́ ìjọba Ìkọjá Odò ṣe àtúnṣe abala ọ̀dọ̀ tiwọn. Usieli ọmọ Hariaya alágbẹ̀dẹ wúrà ló ṣiṣẹ́ tẹ̀lé wọn. Lẹ́yìn wọn ni Hananaya, ọ̀kan ninu àwọn onítùràrí ṣe àtúnṣe ọ̀dọ̀ tirẹ̀, wọ́n sì ṣe é dé ibi Odi Gbígbòòrò. Lẹ́yìn wọn ni Refaaya ọmọ Huri, aláṣẹ ìdajì agbègbè Jerusalẹmu ṣe àtúnṣe abala tí ó kàn. Jedaaya ọmọ Harumafi ló ṣe àtúnṣe abala tí ó tẹ̀lé tiwọn, ó tún apá ibi tí ó kọjú sí ilé rẹ̀ ṣe. Lẹ́yìn wọn, Hatuṣi ọmọ Haṣabineya ṣe àtúnṣe tiwọn. Malikija, ọmọ Harimu, ati Haṣubu, ọmọ Pahati Moabu, ṣe àtúnṣe apá ibòmíràn ati Ilé Ìṣọ́ ìléru. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Ṣalumu ọmọ Haloheṣi, aláṣẹ apá keji agbègbè Jerusalẹmu ṣe àtúnṣe apá ọ̀dọ̀ tirẹ̀, àtòun ati àwọn ọmọbinrin rẹ̀. Hanuni ati àwọn tí ń gbé Sanoa tún Ẹnubodè Àfonífojì ṣe, wọ́n tún un kọ́, wọ́n sì ṣe àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀. Wọ́n ṣe àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, wọ́n sì tún odi rẹ̀ kọ́ ní ìwọ̀n ẹgbẹrun igbọnwọ (mita 450), sí Ẹnubodè Ààtàn. Malikija ọmọ Rekabu, aláṣẹ agbègbè Beti Hakikeremu, ṣe àtúnṣe Ẹnubodè Ààtàn, ó tún un kọ́, ó so àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ ó sì ṣe àwọn ìdábùú rẹ̀. Ṣalumu ọmọ Kolihose, aláṣẹ agbègbè Misipa tún Ẹnubodè Orísun ṣe, ó tún un kọ́, ó bò ó, ó sì ṣe àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ ati ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, ó sì tún mọ odi Adágún Ṣela ti ọgbà ọba títí kan àtẹ̀gùn tí ó wá láti ìlú Dafidi. Lẹ́yìn rẹ̀, Nehemaya ọmọ Asibuki, aláṣẹ ìdajì agbègbè Betisuri ṣe àtúnṣe dé itẹ́ Dafidi, títí dé ibi adágún àtọwọ́dá ati títí dé ilé àwọn akọni. Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn ọmọ Lefi wọnyi ṣe àtúnṣe ọ̀dọ̀ tiwọn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí: Rehumu ọmọ Bani ṣe àtúnṣe apá ọ̀dọ̀ tirẹ̀, lẹ́yìn rẹ̀ ni Haṣabaya, aláṣẹ ìdajì agbègbè Keila ṣe àtúnṣe agbègbè tirẹ̀. Àwọn arakunrin rẹ̀ ṣe àtúnṣe agbègbè tiwọn náà: Bafai ọmọ Henadadi, aláṣẹ ìdajì agbègbè Keila ṣe ti agbègbè rẹ̀. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Eseri ọmọ Jeṣua, aláṣẹ Misipa, náà ṣe àtúnṣe apá kan lára ibi ihamọra ní ibi igun odi. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Baruku, ọmọ Sabai, ṣe àtúnṣe láti apá ibi Igun odi títí dé ẹnu ọ̀nà ilé Eliaṣibu olórí alufaa. Lẹ́yìn rẹ̀, Meremoti, ọmọ Uraya, ọmọ Hakosi, ṣe àtúnṣe apá tiwọn láti ẹnu ọ̀nà ilé Eliaṣibu títí dé òpin ilé Eliaṣibu. Lẹ́yìn rẹ̀, àwọn alufaa, àwọn ará pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọdani ṣe àtúnṣe ọ̀dọ̀ tiwọn. Lẹ́yìn wọn ni Bẹnjamini ati Haṣubu ṣe àtúnṣe apá ibi tí ó kọjú sí ilé wọn. Lẹ́yìn wọn, Asaraya ọmọ Maaseaya, ọmọ Ananaya ṣe àtúnṣe ní ẹ̀gbẹ́ ilé tirẹ̀. Lẹ́yìn rẹ̀, Binui, ọmọ Henadadi ṣe àtúnṣe apá ọ̀dọ̀ tirẹ̀: láti ilé Asaraya títí dé ibi Igun Odi. Palali, ọmọ Usai ṣe àtúnṣe ibi tí ó kọjú sí Igun Odi ati ilé ìṣọ́, láti òkè ilé ọba níbi ọgbà àwọn olùṣọ́. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Pedaaya, ọmọ Paroṣi, ati àwọn iranṣẹ tẹmpili tí wọn ń gbé Ofeli ṣe àtúnṣe tiwọn dé ibi tí ó kọjú sí Ẹnubodè Omi, ní ìhà ìlà oòrùn ati ilé ìṣọ́ tí ó yọgun jáde títí dé ibi odi Ofeli. Lẹ́yìn náà ni àwọn ará Tekoa ṣe àtúnṣe apá ibi tí ó kọjú sí ilé ìṣọ́ tí ó yọgun jáde títí dé Ofeli. Àwọn alufaa ni wọ́n tún Òkè Ẹnubodè Ẹṣin ṣe, olukuluku tún ibi tí ó kọjú sí ilé rẹ̀ ṣe. Lẹ́yìn wọn, Sadoku, ọmọ Imeri, ṣe àtúnṣe ibi tí ó kọjú sí ilé tirẹ̀. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Ṣemaaya, ọmọ Ṣekanaya, olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà ìhà ìlà oòrùn, ṣe àtúnṣe ọ̀dọ̀ tirẹ̀. Lẹ́yìn rẹ̀, Hananaya, ọmọ Ṣelemaya, ati Hanuni, ọmọkunrin kẹfa ti Salafu bí ṣe àtúnṣe apá ibòmíràn. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Meṣulamu, ọmọ Berekaya, ṣe àtúnṣe ibi tí ó kọjú sí yàrá rẹ̀. Lẹ́yìn rẹ̀ Malikija, ọ̀kan ninu àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà, ṣe àtúnṣe títí dé ilé àwọn iranṣẹ tẹmpili ati ilé àwọn oníṣòwò, níbi tí ó kọjú sí Ẹnu Ọ̀nà Mifikadi, ati títí dé yàrá òkè orígun odi. Àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà ati àwọn oníṣòwò sì ṣe àtúnṣe tí ó yẹ ní ààrin yàrá òkè orígun odi ati ti Ẹnu Ọ̀nà Aguntan.

Neh 3:1-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Eliaṣibu olórí àlùfáà àti àwọn àlùfáà arákùnrin rẹ̀ lọ ṣiṣẹ́, wọ́n sì tún Ibodè Àgùntàn mọ. Wọ́n yà á sí mímọ́, wọ́n sì gbé ìlẹ̀kùn dúró sí ibi tí ó yẹ, wọ́n mọ ọ́n títí dé Ilé Ìṣọ́ Ọgọ́rùn-ún, èyí tí wọ́n yà sí mímọ́ títí dé ilé ìṣọ́ gíga Hananeli Àwọn ọkùnrin Jeriko sì mọ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Sakkuri ọmọ Imri sì mọ ní ẹ̀gbẹ́ àwọn ọkùnrin Jeriko. Àwọn ọkùnrin Senaa ni wọ́n mọ Ibodè Ẹja. Wọ́n kún ọ̀pọ̀ ìgbéró rẹ̀, wọ́n sì gbé ìlẹ̀kùn rẹ̀, ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè e rẹ̀ sí ààyè e wọn. Meremoti ọmọ Uriah, ọmọ Hakosi tún èyí tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ẹ wọn mọ. Ẹni tí ó tún wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni Meṣullamu ọmọ Berekiah, ọmọ Meṣesabeli tún èyí ti ó wà ní ẹ̀gbẹ́ wọn mọ. Bákan náà ni ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Sadoku ọmọ Baanah náà tún odi mọ. Èyí tí ó tún wà ní ẹ̀gbẹ́ wọn ni àwọn ọkùnrin Tekoa tún mọ, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́lá kò ṣe àtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà lábẹ́ àwọn olórí wọn. Jehoida ọmọ Pasea àti Meṣullamu ọmọ Besodeiah ni wọ́n tún ẹnu ibodè àtijọ́ ṣe. Wọ́n kún bíìmù rẹ̀, wọ́n ri àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè rẹ̀ sí ààyè wọn. Lẹ́yìn in wọn ni àtúnṣe tún wà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin Gibeoni àti Mispa; Melàtiah ti Gibeoni àti Jadoni ti Meronoti; àwọn ibi tí ó wà lábẹ́ àṣẹ baálẹ̀ agbègbè Eufurate. Usieli ọmọ Harhiah, ọ̀kan lára àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà, túnṣe àtúnṣe èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀; àti Hananiah, ọ̀kan lára àwọn tí ó ń ṣe tùràrí, túnṣe àtúnṣe èyí tí ó tún tẹ̀lé e. Wọ́n mú Jerusalẹmu padà bọ̀ sípò títí dé Odi Gbígbòòrò. Refaiah ọmọ Huri, alákòóso ìdajì agbègbè Jerusalẹmu, tún èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣe. Ní ẹ̀gbẹ́ èyí Jedaiah ọmọ Haramafu tún èyí tí ó wà ní ọ̀ọ́kán ilé rẹ̀ mọ, Hattusi ọmọ Haṣbneiah sì tún tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mọ. Malkiah ọmọ Harimu àti Haṣubu ọmọ Pahati-Moabu tún ẹ̀gbẹ́ kejì ṣe àti Ilé ìṣọ́ Ìléru. Ṣallumu ọmọ Halloheṣi, alákòóso ìdajì agbègbè Jerusalẹmu tún ti ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mọ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀. Ibodè Àfonífojì ni Hanuni àti àwọn ará Sanoa tún mọ. Wọ́n tún un kọ́, wọ́n ri àwọn ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè rẹ̀ sí ààyè rẹ̀. Wọ́n sì tún tún ẹgbẹ̀rún kan ìgbọ̀nwọ́ odi mọ títí dé ẹnu ibodè ààtàn. Ẹnu Ibodè Ààtàn ni Malkiah ọmọ Rekabu, alákòóso agbègbè Beti-Hakeremu tún mọ. Ó tún un mọ, ó sì gbé àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè rẹ̀ sí ààyè wọn. Ẹnu Ibodè Orísun ni Ṣalluni Koli-Hose, alákòóso agbègbè Mispa tún mọ. Ó tún ún mọ, ó kan òrùlé e rẹ̀ yíká, ó gbé àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn idẹ rẹ̀ ró sí ààyè wọn. Ó tún tún odi Adágún Siloamu mọ, ní ẹ̀gbẹ́ Ọgbà ọba, títí dé àwọn àtẹ̀gùn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ láti ìlú Dafidi. Lẹ́yìn in rẹ̀ ni, Nehemiah ọmọ Asbuku, alákòóso ìdajì agbègbè Beti-Suri ṣe àtúnmọ dé ibi ọ̀ọ́kán òdìkejì ibojì Dafidi, títí dé adágún omi àtọwọ́dá àti títí dé ilé àwọn alágbára. Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn ará a Lefi, ní abẹ́ ẹ Rehumu ọmọ Bani. Lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni Haṣabiah, alákòóso ìdajì agbègbè Keila ṣe àtúnṣe fún agbègbè tirẹ̀. Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn Lefi arákùnrin wọn ní abẹ́ àkóso Binnui ṣe àtúnṣe, Bafai ọmọ Henadadi, ìjòyè àwọn ìdajì agbègbè Keila. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Eseri ọmọ Jeṣua, alákòóso Mispa, tún ìbò mìíràn ṣe, láti ibìkan tí ó kojú sí ibi gíga sí ilé-ìhámọ́ra títí dé orígun. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Baruku ọmọ Sakkai fi ìtara tún apá mìíràn ṣe, láti orígun dé ẹnu-ọ̀nà ilé Eliaṣibu olórí àlùfáà. Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Meremoti ọmọ Uriah, ọmọ Hakosi tún apá mìíràn ṣe, láti ẹnu-ọ̀nà ilé Eliaṣibu títí dé òpin rẹ̀. Àtúnṣe tí a tún túnṣe lẹ́yìn rẹ̀ ní àwọn àlùfáà ní àyíká agbègbè túnṣe. Lẹ́yìn wọn ni Benjamini àti Haṣubu tún èyí ti iwájú ilé wọn ṣe; lẹ́yìn wọn ni, Asariah ọmọ Maaseiah ọmọ Ananiah tún ti ẹ̀gbẹ́ ilé rẹ̀ ṣe. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Binnui ọmọ Henadadi tún apá mìíràn ṣe, láti ilé Asariah dé orígun àti kọ̀rọ̀, àti Palali ọmọ Usai tún òdìkejì orígun ṣe àti ilé ìṣọ́ tí ó yọ sóde láti ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ààfin ọba ti òkè lẹ́gbẹ̀ẹ́ agbègbè àwọn olùṣọ́. Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Pedaiah ọmọ Paroṣi àti àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili tí ó ń gbé ní òkè Ofeli ṣe àtúnṣe títí dé ibi ọ̀kánkán òdìkejì ibodè omi sí ìhà ìlà-oòrùn àti ilé ìṣọ́ tí ó yọ sóde. Lẹ́yìn wọn ni àwọn ènìyàn Tekoa tún apá mìíràn ṣe, láti ilé ìṣọ́ ńlá tí ó yọ sóde títí dé ògiri Ofeli. Àwọn àlùfáà ni ó ṣe àtúnṣe òkè ibodè ẹṣin ṣe, ẹnìkọ̀ọ̀kan ní iwájú ilé e rẹ̀. Lẹ́yìn wọn, Sadoku ọmọ Immeri tún ọ̀kánkán òdìkejì ilé rẹ̀ ṣe. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Ṣemaiah ọmọ Ṣekaniah, olùṣọ́ ibodè ìhà ìlà-oòrùn ṣe àtúnṣe. Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Hananiah ọmọ Ṣelemiah, àti Hanuni ọmọ ẹ̀kẹfà Ṣalafi, tún apá ibòmíràn ṣe. Lẹ́yìn wọn ni, Meṣullamu ọmọ Berekiah tún ọ̀kánkán òdìkejì ibùgbé ẹ̀ ṣe. Lẹ́yìn in rẹ̀ ni Malkiah, ọ̀kan nínú àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà ṣe àtúnṣe títí dé ilé àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn oníṣòwò, ní ọ̀kánkán òdìkejì ibodè àyẹ̀wò títí dé yàrá òkè kọ̀rọ̀; àti láàrín yàrá òkè kọ̀rọ̀ àti ibodè àgùntàn ni àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà àti àwọn oníṣòwò túnṣe.