Neh 3

3
Títún Ògiri Jerusalẹmu Mọ
1NIGBANA ni Eliaṣibu olori alufa dide pẹlu awọn alufa arakunrin rẹ̀, nwọn si mọ ẹnu-bode agutan; nwọn sọ ọ di mimọ́, nwọn si gbe ilẹkùn rẹ̀ duro, titi de ile-iṣọ Mea, ni nwọn sọ di mimọ́ titi de ile-iṣọ Hananeeli.
2Lọwọkọwọ rẹ̀ ni awọn ọkunrin Jeriko si mọ: lọwọkọwọ wọn ni Sakkuri ọmọ Imri si mọ.
3Ṣugbọn ẹnu-bode Ẹja ni awọn ọmọ Hasenaa mọ, ẹniti o tẹ́ igi idabu rẹ̀, ti o si gbe ilẹkun rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀, ati itikùn rẹ̀.
4Lọwọkọwọ wọn ni Meremoti ọmọ Urijah, ọmọ Kosi, tun ṣe. Ati lọwọkọwọ wọn ni Meṣullamu, ọmọ Berekiah, ọmọ Meṣesabeli tun ṣe. Ati lọwọkọwọ wọn ni Sadoku, ọmọ Baana tun ṣe.
5Ati lọwọkọwọ wọn ni awọn ará Tekoa tun ṣe, ṣugbọn awọn ọlọla kò fi ọrùn si iṣẹ Oluwa wọn.
6Jehoida, ọmọ Pasea, ati Meṣullamu, ọmọ Besodiah, si tun ẹnu-bode atijọ ṣe, nwọn tẹ̀ igi idabu rẹ̀, nwọn si gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, ati àgadágodo rẹ̀, ati itikùn rẹ̀.
7Lọwọkọwọ wọn ni Melatiah, ará Gibeoni, tun ṣe, ati Jadoni, ara Merono, awọn ọkunrin ti Gibeoni, ati ti Mispa, ti o jẹ ti itẹ bãlẹ̀ apa ihin odò.
8Lọwọkọwọ rẹ̀ ni Ussieli ọmọ Harhiah, alagbẹdẹ wura tun ṣe; ati lọwọkọwọ rẹ̀ ni Hananiah ọmọ alapolu, tun ṣe; nwọn si ti fi Jerusalemu silẹ̀ titi de odi gbigbõro.
9Lọwọkọwọ wọn ni Refaiah, ọmọ Huri ijòye idaji Jerusalemu si tun ṣe.
10Lọwọkọwọ wọn ni Jedaiah, ọmọ Haramafu, si tun ṣe, ani ọkánkan ile rẹ̀. Lọwọkọwọ rẹ̀ ni Hattuṣi ọmọ Haṣabaniah si tun ṣe.
11Malkijah ọmọ Harimu, ati Haṣubu ọmọ Pahati-Moabu, tun apa keji ṣe, ati ile-iṣọ ileru.
12Ati lọwọkọwọ rẹ̀ Ṣallumu ọmọ Haloheṣi, ijòye apa kan Jerusalemu, tun ṣe, on ati awọn ọmọbinrin rẹ̀.
13Hanuni pẹlu awọn ará Sanoa si tun ẹnu-bode afonifoji ṣe; nwọn kọ́ ọ, nwọn si gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀ ati itikùn rẹ̀, ati ẹgbẹrun igbọnwọ odi titi de ẹnu-bode ãtàn.
14Ẹnu-bode ãtàn ni Malkiah ọmọ Rekabu, ijòye apa kan Bet-hakkeremu tun ṣe; o kọ́ ọ, o gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀ ati itìkun rẹ̀.
15Ṣallumu, ọmọ Kol-hose, ijòye apakan Mispa si tun ẹnu-bode orisun ṣe; o kọ́ ọ, o si bò o, o si gbe ilẹkùn rẹ̀ ro, àgadágodo rẹ̀, ati itìkun rẹ̀ ati odi adagun Ṣiloa li ẹ̀ba ọgba ọba, ati titi de atẹ̀gun ti o sọkalẹ lati ile Dafidi lọ.
16Lẹhin rẹ̀ ni Nehemiah, ọmọ Asbuku, ijòye idaji Bet-huri, tun ṣe titi de ibi ọkánkán iboji Dafidi, ati de adagun ti a ṣe, ati titi de ile awọn alagbara.
Àwọn Ọmọ Lefi tí Wọ́n Ṣiṣẹ́ ní Ibi Odi náà
17Lẹhin rẹ̀ ni awọn ọmọ Lefi, Rehumu, ọmọ Bani tun ṣe. Lẹhin rẹ̀ ni Haṣabiah ijòye idaji Keila tun ṣe li apa tirẹ̀.
18Lẹhin rẹ̀ ni awọn arakunrin wọn tun ṣe, Bafai ọmọ Henadadi, ijoye idaji Keila.
19Lọwọkọwọ rẹ̀ ni Eseri ọmọ Jeṣua, ijòye Mispa, tun apa miran ṣe li ọkánkán titọ lọ si ile-ihamọra kọrọ̀ odi.
20Lẹhin rẹ̀ ni Baruku ọmọ Sabbai fi itara tun apa miran ṣe, lati igun ogiri titi de ilẹkùn ile Eliaṣibu, olori alufa.
21Lẹhin rẹ̀ ni Meremoti ọmọ Urijah, ọmọ Kosi tun apa miran ṣe lati ilẹkùn ile Eliaṣibu titi de ipẹkun ile Eliaṣibu.
22Lẹhin rẹ̀ ni awọn alufa si tun ṣe, awọn ọkunrin pẹtẹlẹ [Jordani].
23Lẹhin wọn ni Benjamini ati Haṣubu tun ṣe li ọkánkán ile wọn. Lẹhin wọn ni Asariah ọmọ Maasiah ọmọ Ananiah tun ṣe lẹba ile rẹ̀.
24Lẹhin rẹ̀ ni Binnui, ọmọ Henadadi tun apa miran ṣe, lati ile Asariah titi de igun odi, ani titi de kọrọ̀.
25Palali ọmọ Usai li ọkánkán igun odi, ati ile-iṣọ ti o yọ sode lati ile giga ti ọba wá ti o wà lẹba ile tubu. Lẹhin rẹ̀ ni Padaiah ọmọ Paroṣi.
26Ṣugbọn awọn Netinimu gbe Ofeli, titi de ọkánkán ẹnu-bode omi niha ila-õrùn ati ile iṣọ ti o yọ sode.
Àwọn Mìíràn tí Wọ́n Tún Ṣiṣẹ́ níbi Odi náà
27Lẹhin wọn ni awọn ara Tekoa tun apa miran ṣe, li ọkánkán ile-iṣọ nla ti o yọ sode, titi de odi Ofeli.
28Lati oke ẹnu-bode ẹṣin ni awọn alufa tun apa miran ṣe, olukuluku li ọkánkán ile rẹ̀.
29Lẹhin wọn ni Sadoku, ọmọ Immeri tun ṣe li ọkánkán ile rẹ̀: lẹhin rẹ̀ ni Ṣemaiah ọmọ Ṣekaniah, olùtọju ẹnubode ila-õrùn tun ṣe.
30Lẹhin wọn ni Hananiah ọmọ Selamiah tun ṣe, ati Hanuni ọmọ Salafu kẹfa tun apa miran ṣe. Lẹhin rẹ̀ ni Meṣullamu, ọmọ Berekiah li ọkánkán yàra rẹ̀.
31Lẹhin rẹ̀ ni Malkiah ọmọ alagbẹdẹ wura tun ṣe, titi de ile awọn Netinimu ati ti awọn oniṣòwo, li ọkánkán ẹnu bode Mifkadi ati yàra òke igun-odi.
32Ati larin yàra òke igun-odi titi de ẹnu-bode agutan ni awọn alagbẹdẹ wura ati awọn oniṣòwo tun ṣe.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Neh 3: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa